OSE KESAN-AN
    AKAYE 1
Bi a ti se mo pe asa je ihuwasi, isesi ati ibasepo awon eniyan ni agbegbe kan. Ara asa ni ounje ti a n je, aso ti a n wo, ikini, igbeyawo, isomoloruko ati iteriba fun agbalagba.
Asa ijo jijo eyi ti o maa n suyo ninu tilu-tifon yala nibi ayeye isile, igbeyawo ati ikomojade tabi ni idi orisa Sango, Obatala, Orunmila ati bee bee lo se pataki. O ni bi a ti n tase agere si awon orisiirisii ilu ati orin ile Yoruba, bi a ti n repa-rese ti a si n gbe genge owo ijo si ilu bata yato gedegbe si bi a ti n gbepa-gbese si ilu dundu nidii Ogun. Eyi lo fa a ti a fi n so pe Onisango to jo ti ko tapa ta abuku ara re.
Awon eegun alarinjo ni won maa n fi orin, ijo ati idan pipa da awon omo kaaro-oo-jiire lara ya laye atijo sugbon olaju ati imo ero ni aye ode-oni ti so o di ere ori-itage, ori ero asoromagbesi ati ti amohun-maworan. (NECO 2002)

  1. Ohun ti a ko ka kun asa gege bi a ti se ka a ninu ayoka yii ni (A) aso wiwo (B) igbeyawo (C) ihuwasi (D) imo ero (E) ounje jije.
  2. Ijo jijo maa n suyo nibi (A) ayeye (B) ikini (C) imo ero (D) iteriba (E) olaju
  3. Awon ti o n da omo kaaro-oo-jiire lara ya ni (A) Eegun alarinjo (B) Obatala (C) Ogun bibo (D) Orunmila (E) Sango
  4. ”so o di ere ori-itage …. ” ”o” n toka si (A) asa Yoruba (B) Obatala (C) orin, ijo ati idan pipa (D) Orunmila (E) Sango bibo.
  5. Akole ti o ba ayoka yii mu ju ni (A) ijo jijo (B) ikomojade (C) oosa bibo (D) igbepe-igbese (E) tilu-tifon.

    AKAYE 2

Ajike ati Bola se igbeyawo ni nnkan bi odun mefa seyin. Bola je omo odun ogbon nigba ti o laya, o fi odun meji ju iyawo re lo. Laarin odun mefa yii, Bola ti di oga agba ni ile itaja kan ni Eko. Won n sanwo daradara fun un nibe, bee ni awon to n raja naa si maa n fun un lebun. O maa n gbebun lowo awon onibara kookan, o si maa n ko ebun opolopo to ba tan-mo-on pe iru ebun bee yoo mu ki oun se ojusaju lenu ise oun. Lara awon to maa n ba raja ni Dele ati Ayoka. Ilu ni won, ero won si ni pe oko-kan-kun-koboodu. O to odun meta ti okookan won ti kuro nile oko.
Bola sakiyesi pe Dele ati Ayoka ko se e dara de afi bi oluwa re ba fe kan abuku. O maa n se won daradara sugbon ki i gba ebun lowo won. Awon naa se akiyesi iwa Bola yii nitori won mo pe o maa n gba ebun lowo awon kan. Won pinnu lati fa oju re mora sugbon bi eyi ko ba se e se, won yoo wa ona atisakoba fun-un. Lodi si iru ajosepo bee, Dele dibon pe oun ko mo nipa oro to n lo. O fi ebun ran Tadese, eni ti Bola tele nibi ise sugbon Bola fi towotowo ko ebun naa.
Bola fi ete onibara re to iyawo re leti, won si pinnu po lati fi adura ati isera bi ogun esu wo. Loooto, onise awon araabi je. Gbogbo eru ibi ise to wa labe akoso Bola ni awon kan ko loru ojo kan. Awon onise ibi pa ode kan, won si sa awon marun-un yooku yannayanna. Won fi isele yii to awon olopaa leti, iwadii si bere ni kiakia. Bola ati awon omo ise re di ero atimole lagoo olopaa. Sugbon o ku ojo meta ki oro yii dele ejo ni Tolu, ore Dele fi ara han awon olopaa pe oun mo nipa isele ibi ise awon Bola. Oun le so bi isu se ku ati bi obe se be e. Laipe, owo te Dele, Ayoka ati awon isongbe re, Ooto leke ran Tolu ni ewon odun mefa, o si dajo iku fun awon yooku, Bola naa si gba ominira.

  1. ki ni Olorun fi ta Bola lore? (a) owo (b) iyawo (c) omo (d) igbega.
  2. Bola n sise ni …… (a) ile itaja (b) ago olopaa (c) kootu (d) soosi.
  3. Omo odun meloo ni Ajike nigba ti o loko? (a) mejilelogbon (b) ogbon (c) merinlelogbon (d) merindinlogoji.
  4. Ta ni oga Bola? (a) Dele (b) Tolu (c) Tadese (d) Ootoleke.
  5. Bola ko ebun awon onibara re nitori pe (a) owo osu re po (b) o fe yera fun abuku (c) ko f eta oja fun won (d) ko fe ni won lara.
  6. ‘onitohun’ toka si (a) Ayoka (b) Dele (c) Bola (d) Tadese.
  7. Leta ti Ayoka ko fi han gege bi (a) oninuuru (b) osonu (c) alapepe (d) apaniyan.
  8. ‘O’ ti a fala si nidii n toka si (a) Tadese (b) Dele (c) Bola (d) ayoka.
  9. ……. ni Ootoleke (a) olopaa (b) ontaja (c) ode (d) adajo.
  10. Ewo ni ooto? (a) Ajike je oga dele (b) Bola je onibara ayoka ati Dele (c) Bola gba awe ati adura (d) awon ode pa ole.

 ASA
ASA ISINKU NI ILE YORUBA
    -ISINKU OBA ATI ABAMI EDA.
AKOONU
Bi a ti n sin oku oba yato patapata si bi a ti n sin oku eniyan lasan.Awon oba alade po ni ile Yoruba,bi a si ti n sinku oba ni ilu kan yato si ti ikeji, ati pe ipo oba kan yato si ara won. Isinku Alaafin ni a o fi se apeere.
Ilu ati ibon yiyin ni a fi n tufo oba ati arugbo,won ki i tete tufo oku oba, ki awon omo to fi to awon oloye leti ni won yoo to palemo gbogbo ohun ti o ba je ohun ini ti oba ni won yoo ti palemo.
    Leyin eyi ni awon omo oba yoo lo so fun awon ijoye pe ara baba awon ko ya, nitori pe won ko ni ase lati so fun won pe oba waja.Nigba ti awon ijoye ba de aafin ni won yoo to mo pe oba ti gbe emi mi, a ki i so pe oba ku, nitori pe oba ki i ku,oba wo aja-ile.A tun le so pe erin wo,opo ye tabi ile baje.
    Gbara ti oba ba ku,ni awon ijoye ati awon agbaagba ti ise tabi ipo oye won ba je mo isinku oba, yoo ti bere etutu ati oro –isinku oba nitori pe aki i sinku oba gege bi a ti i sinku eniyan lasan.Oku gbogbo ilu ni oku oba,ni Oyo ilu koso ati fere Okinkin ti a fi eyin gbe.
    Ni Bara ni won maa n sin oku Alaafin si ni aye atijo,lale si ni won maa n se eto oku naa,opolopo etutu ni won o ti se.
Ona-Onse Awo ni oloye ti ipo oye re jemo isinku oba Alaafin.Oloye yii ni yoo ge ori oba to waja,inu yara kan to wa laafin, ti a n pe ni ile ori ni yoo gbe ori oba si fun ilo oba ti yoo tun je tele e.
    Bi won ba fe lo sin oku oba to ku ni Bara, won a fon fere Okinkin,a o si lu ilu koso lati so fun awon ara ilu pe oba n re ile igbeyin lati lo sun.
Ibi mokanla ni awon oloye to gbe oba yoo ti duro ki won to de Bara nitori pe ibe jinna die si aarin ilu.Nibi kookan ti won ba ti duro si ni won yoo ti fi eeyan kan ati agbo kan rubo.
    Koto ti a o sin oku Alaafin si maa n fe pupo,yoo gun daadaa,bee ni yoo si jin gidi nitori opolopo nnkan ti a o sin pelu re,aso dudu ati aso funfun ni a fi n sinku oba Alaafin.
Bi won se n sinku oba ni pe won a te oku oba si aarin koto ti a gbe,leyin eyi won a pa obinrin mejo,won a te merin si igberi re ati merin si igbase re .won a tun pa awon giripa okunrin merin,won o te meji si egbe re otun ati osi,leyin eyi ni won yoo wa ko oku awon mokanla ti a fi rubo loju ona,ki a to de Bara sinu koto nla naa.
Awon metalelogun ti a sin pelu oba ni won gbagbo pe yoo maa se iranse fun oba lona orun ati ni orun nibi ti o n lo.
Igbagbo won ni pe ipo ti oba wa laye ni yoo wa ni orun,nitori naa oba ni lati ni opolopo obinrin ati iranse.leyin gbogbo re ni won yoo pa eni ti o gbe ina lowo ti a fi se gbogbo eto isinku yii,won yoo gbe oku re pelu awon iranse ti o wa ninu koto.
    Awon iyawo,omo,ore,ati ebi yoo wa bere si ko ebun,ounje ti won ko way ii ni won lero pe yoo wulo fun oba lona irin-ajo ti o n lo.leyin gbogbo eyi ni won yoo wa ro eepe bo gbogbo ohun ti o wa ninu koto.
    Ayipada ti de ba bi a ti n sin oku oba laye ode-oni,won ko fi eniyan se etutu mo ni ilu oyo esin ati maluu ni won n lo bayii.

 LITIRESO
KIKA IWE TI IJOBA YAN.
IWE KIKA-;
Eto Iro Ati Girama Fun Ile-Iwe Sekondiri Agba. Folarin Olatubosun.o.i 75.
ISE ASETILEWA
AKAYE KIN-IN-NI
Ka awon ayoka wonyi, ki o si dahun awon ibeere ti o tele won.
    Igba oye je igba ti awon eniyan koriira ni ile Yoruba, nitori ni asiko yii ni otutu maa n mu gidi gan-an ati dide lori ibusun maa n soro ati kowo bo omi tutu je ise beeni iwe wiwe ko rorun, opolopo awon eniyan lo n pe de ibi ise won, gbogbo awon oloja tita ki i de ibi ise loju ojo.
    Ategun oye maa n se akoba fun igi oko nitori gbogbo itanna igi eleso ni o n gbon danu, nipa bee, igi eleso ko ni le so to bee, omi inu odo a gbe kiakia, beeni opolopo kanga ko si ni sun omi, omi a wa di owon gogo. Bakan naa, eran igbe ki i pop o loja nitori awon ode ki i ri eran pa ninu igbo, bee gege ni eso igi kii saba pon lasiko yii. Imura awon miiran maa n buru jojo bee si ni awon miiran kii we lasiko yii, won yoo wo dandogo si isale buba, won yoo wa dabi oba awon igare, ti iru won ba yo lokankan ko si iyato laarin won ati inaki.
    Bi awon eniyan se korira igba oye to yii, sibe aisan Kankan ko wopo, oorun asun gbadun ni eniyan maa n sun, oju ogbe maa n san kiakia ati wi pe awon efon maa n dinku. Bi awon aleebu igba oye yii se po to sibe igba oye si dara ju igba ooru lo nitori iku maa n wopo nigba ooru.
Dahun awon ibeere wonyi:

  1. Ki ni idi re ti alayoka yii fi faramo igba oye ju igba ooru lo? (A) atiwe maa n soro (B) awon eniyan maa n mura bi oba iganre (C) awon eniyan maa n pe de ibi ise (D) iku maa n dinku (E) omi odo maa n gbe.
  2. Gbogbo nnkan wonyi ni isoro igba oye lara awon eniyan ayafi isoro. (A) airoorun sun (B) atidide lori ibusun (C) atifowo kan omi (D) iwe wiwe (E) pipe de ibi ise.
  3. Ki ni idi ti igi eleso ki i fi so tobee lasiko oye? Lasiko oye (A) awon itanna ti o tan yoo (B) igi eleso kii tanna (C) igi eleso maa n gbe danu (D) itanna igi eleso ti o maa n po (E) itanna igi eleso ti o maa n re danu.
  4. Ewo ni ko si lara anfaani oye ninu akaye yii? (A) aisankaisan ko wopo (B) eso igi ki i saba pon (C) efon n dinku (D) oju ogbe n san kiakia (E) oorun asungbadun.
  5. Ewo ni ki i se aleebu igba oye ninu awon wonyi? (A) awon oloja tita maa n pe de pe de oja (B) eran igbe kii po loja (C) imura awon eniyan kii dara to (D) kanga maa n lomi ninu (E) oorun asungbadun maa n wa.

    AKAYE KEJI
    Ka awon ayoka yii, ki o si dahun awon ibeere ti o tele won.
    Leyin osu merin ti awon igara olosa ko iwe ranse si adugbo Karonwi ni won mu ileri won se. Idaamu ti ko legbe ni won ko ba awon ara adugbo paapaa julo Ayinla oko Mosunmola, okunrin bi obinrin lati igba ti won ti gba leta yii. Se ti eti ko ba gbo yinkin, inu ki i baje ipade adugbo ti won maa n se ni osu meji-meji ti di osoose latari ati jiroro lori aabo awon ara adugbo naa.

         Afemoju ojo eti ni nnkan bii aago kan aajin ni awon elekeri wo adugbo Karonwi pelu oniruuru ohun ija ati oogun ti won so mo ara won. Logan ni awon ode ti bere si ni fon feere foo, faa lati ji awon ara adugbo. Awon onile ati ayalegbe gbogbo gbe iku ta, won ya sita bi eesu pelu ibon , ada, ofa, igi, obe-ere, ati kumo. Se anikan rin nii je omo ejo niya. Bi awon ole yii se ri opo ero ni won bere si ni yin ibon. Oro wa di ”eni to fe ku pade eni ti yoo pa a” iro ibon yii ko da awon ara adugbo duro rara, se ti a ba sun ewure kan ogiri o le bu ni je. Leekan naa ni awon olosa yii poora sinu ile alapa kan ti won sa wo.

         Ara awon eniyan yii ko gba a, won si ina bo inu ile alapa yii. Aja dudu meta ni won ri ti o sa jade ninu ina yii won si ri okan ninu won sa ladaa. Bi won ti sa ladaa ni o yipada di eniyan. Oro di pen-n-tuka. Ayinla ni o saaju awon ti o koko ba ese won soro. Sugbon awon agba taku pe ojo ti a ba ri ibi ni ibi n wole. Won ba a woya ija, won si dana sun oku re ni ita gbangba. Awon to je ode aperin le awon meji yooku wo inu igbo, nibe ni won si yanju won si.
    Dahun awon ibeere wonyi:

  6. Toka si gbolohun ti o je ooto nipa akaye yii. (A) awon adigunjale pa die lara awon ara Karonwi (B) Monisola ni iyawo Ayinla. (C) awon ayalegbe ko da si oro awon ara adugbo (D) awon ode aperin ni o ba aja dudu wo iya ija (E) kii se gbogbo eniyan ni o lagbara lati doju ko awon ole yii.
  7. Kin ni awon adigunjale se nigba ti won ri i pe ibon won ko deru ba awon ara Karonwi? Won (A) bere sii pofo (B) poora (C) sa pada (D) sa won ladaa (E) yo igi si won.
  8. Oro ti o le dipo ”ba ese won soro” ti afa ila si ni idi ni (A) ja (B) korin (C) palemo (D) ranti (E) salo.
  9. Ewo ninu awon wonyi ni ko si lara ohun ija awon ara adugbo? (A) ada, igi, ofa (B) ada, ofa, ibon (C) igi, kumo,, obe-ere (D) kumo, ofa, ada (E) obe-ere, ida, ofa.
  10. Akole wo ni o ba akaye yii mu julo? (A) aitete mole, ole mu oloko (B) awon ode adugbo Karonwi (C) awon olosa fese fe (D) leta adigunjale (E) ojo gbogbo ni ti ole, ojo kan ni ti olohun.

Apa keji
1.salaye isinku oba

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *