OSE KEJO
AROKO ASARIYANJIYAN

AKOONU : –
Iha meji ni aroko alarinyanjiyan gbodo ni,iha beeni ati iha beeko.Iha eyi ti a faramo ati eyi ti a ko faramo.Eyi ni wi pe akekoo yoo gbenuso fun egbe kin-in-ni ti o faramo,oun kan naa ni yoo se atako fun eyi ti ko faramo.
    Akekoo gbodo soro lori egbe mejeeji bi o tile je pe yoo fi si ibi kan ju ibi kan lo.Akekoo koko gbodo soro lori egbe ti ko faramo lori awon ohu n ti o dara ti o wa nibe,yoo wa soro lekunrere lori iha ti o faramo gbogbo awon ohun ti o ba so nibi ni yoo fibi ohun ti o wa ninu koko eyi ti ko faramo subu,ibi ni yoo ti fi idi iha ti o yan mule.
    Akekoo gbodo fi idi iha ti o yan mule ninu igunle aroko re.A ko gbodo so itan tabi pa aalo ninu iru aroko bayii.
    ETO INU ARIYANJIYAN
     Gege bi ohun ti mo so saaju,nigba ti akekoo ba fe tako ero elomiran nipa koko kan, ohun ti yoo se ni sise-n-tele niwonyi

  1. Ki o toka si ero elomiran naa ni soki.
  2. Ki o so idi re ti o fi tako ero naa,eyi gbodo je pelu ekun rere alaye.
  3. Akekoo yoo wa gbe ero tire kale ni eseese, ki koko re wa ni ipari ohun ti o ba ko.     

    ILO EDE
Akekoo gbodo sa awon oro inu gbolohun re lo lona ti onkawe/oluko yoo fi maa fokan baalo.
Iru awon gbolohun wonyi dara lopolopo fun ariyanjiyan sise
-Ero awon kan nip e——— sugbon eyi ko ri bee nitori pe
– Ati gbo pe——- bi o tile je pe
-Awon kan gbagbo pe——– sugbon won ti gbagbe pe——-
-Awon elomiran ro wi pe——— sugbon won ti gbagbe pe
    Akekoo gbodo lo akoto ode oni lati gbe ise re kale.
Siwaju si i, owe naa wulo fun ariyanjiyan sise, nigba ti a ba ti lo won lona ti o to ti o si ye.
Apeere ori oro aroko alarinyanjiyan ni : –
Owo legbon,omo laburo.
Iyawo kan dara loode.
Kiko ede abinibi san ju kiko ede okeere lo.
Ise adani mowo wole ju ise akowe lo.
Dokita wulo fun ilu ju agbe lo.
Igba eerun dara ju igba ojo lo.
Ohun ti okunrin le se,obinrin naale se e.
Nje o to ki obinrin abileko maa sise ijoba?
Nje o to ki a maa pa awon adigunjale?

 IGBELEWON
Se ilapa ero fun ori-oro yii
Ise adani mowo wole ju ise osu lo.

 IWE AKATILEWA
Adewoyin S.Y (2006) Imo, Ede, Asa Ati Litireso fun ile Sekondiri Agba S.S. 1. Corpromutt Publihers Nig Ltd Oju iwe 182-188.        
        
ASA
ASA ISINKU NI ILE YORUBA
Awon Yoruba gbagbo pe gbogbo wa ni a da agbada iku,won a ni ‘ma forum yo mi gbogbo wa la jo n lo.’atomode atagba ko si eni ti ko ni ku,gbogbo wa la je gbese iku.Ki Olorun ko fi iku rere pa ni.
    Awon Yoruba gbagbo pe bi eniyan ba ku yoo lo si orun,yala rere tabi orun apaadi.
AWON ONA TI A N GBA SIN ORISIIRISII OKU.
AKOONU : –
Ki Edumare ki o fi iku ire pa gbogbo wa bi a ti n sin oku kookan da lori eni ti o je ati iru iku ti o pa eni bee.Die ninu iru re niwonyii.
Eni ti sango pa.            Awon mogba nii se etutu sisin re.
Eni ti sanponna pa            inu igbo ni won maa n sin-in si awon adahunse n
sii se etutu sisin re.
eni ti o ku sinu odo             eti odo ti o ku si ni won maa n sin –in si,awon
                    alawo ni si n se etutu re.
eni ti o ku toyuntoyun        awon oloro nii se etutu sisin re.
Adete                    awon ogbontarigi adahunse ni i se etutu sisin re,inu
                    Igbo ni won a sin-in si, won a si sun gbogbo nnkan                          Ini re.
Eni ti o pokunso            Awon onimole ni i sin in,idi igi ti o pokunso si naa
                    ni won o sin in si.
Abuke                    Awon babalawo ati adahunse ni i se etutu sinsin re,                    
                    Inu igbo ni won sin in si, ninu ikoko,won a si sin
                    Gbogbo nnkan ini re mo pelu.
Babalawo                 awon agba awo ni i se etutu sisin oku babalawo
pelu eye ti o ga ti won yoo fi se etutu lati yose re
kuro ninu egbe awo.
Ode                     awon ode nii se ayeye oku ode sisin,oro pataki
ti Won ni lati se fun un ni sisipa ode ti a mo si ‘ ikopa ode’ eyi ni etutu ti won maa n se ki awon eran ti ode naa ti pa nigba aye re ma baa hun un,ki o sile je ki awon ode to ku laye maa ri eranko.
Onilu                     awon onilu nii se etutu onilu lati yowo elegbe won
                    ti o ti ku kuro ninu egbe ki awon to ku le maa ri se.
Alagbede                 Awon alagbede nii se oro igbeyin fun oku alagbede
                lati yowo re kuro ninu egbe.Inu ile aro ti alagbede
                naa ti n sise ki o to ku ni a ti maa n saba se etutu
                Ikeyin yii.
Yato si gbogbo awon wonyii,awon Yoruba a maa ro oku paapaa eyi ti o ba je oku oroju ti
won gba pe iku re kii se lasan,awon agba adahunse tabi oloogun ni o maa n ro oku, ki
won to gbe e si koto, riro yii lo maa je ki o se iku pa eni ti o pa a. .
IGBELEWON : –
salaye ona ti a n gba sin awon oku wonyii; – i. eni toku somi,ii. Eni ti sango pa. iii. Adete iv. Eni ti o pokunso.

         LITIRESO
    EWI ALOHUN TO JE MO ASA ISINKU
Ewi alohun-;je ewi ti a jogun lodo awon baba –nla wa,nitori pe awon Yoruba je eya to feran ewi lopolopo,bi won se ni ewi fun asa isinku naa ni won ni ewi atenudenu fun orisiirisii ayeye to ku.
Lara awon ewi atenudenu ti a ya soto fun isinku ni;
    Oku pipe
    Igbala sisin
    Iremoje.
Bakan naa ni won le lo awon ewi atenudenu miiran fun ayeye isinku, ki i se dandan ki o je awon ti a ko soke yii nikan.
Oku pipe
Yoruba ka iku si ohun ibanuje pupo. Nigba ti iku ba de, igbe ekun a gba ile,okiki a gba ode.Awon eniyan yoo bere si pohunrere ekun, won yoo si maa so orisiirisii ohun ti o ba bo si won lenu, lati fi edu okan won han.Iru ekun bayii ti awon agbalagba obinrin maa n sun ti won si maa fi n pe oku bi eni pe ko dide soro ni a n pe ni oku pipe.
Ohun ti o maa suyo ninu ewi tabi arofo oku pipe ni
    – iwa ati ise eni ti o ku.
     – irisi re
– itan igbesi aye re
     – awon aseyori re
     – oriki-orile
     – ise re.
Bi eniyan ba teti si oku pipe yoo mo oruko eni ti o ku,awon obi re,oruko awon omo re ati oruko awon aya re(bi o ba je okunrin) tabi oruko oko re(bi o ba je obinrin).Gbara ti oku ba ti ku ni arofo oku pipe yoo ti bere titi di igba ti won yoo sin in.
Asiko ti enikan ba ku ni a o maa gbo ninu oku pipe bi o se lawo to, bi o se je oninu-un-re to,bi o se ko eniyan mora to abbl.
Eyi ni apeere oku pipe
    A a ri ni lode a a beere
    A a ri ni lode a a beere
Ki n poloro mi ku, abo sun ni?
    Abinbolu Akanji lo gbaa n o rii?
    Baba Foyeke,baba Ejire fi mi sile lo sorun alakeji.
    Iku gboko lowo mi po o.
    Iya nla je mi n o lolugbeja
    Iku pomo Farounbi
    O lo ba baba to bi i lomo
    Akanbi omo olu-oje
    Omo olomi tutu ese oke.
Bi a ba wo apeere oku pipe ti a fun wa yii, a o ri i pe gbogbo awon ohun ti a menuba pata ni o wa nibe.
Iremoje ni ewi atenudenu ti awon ode maa n lo lati dagbere fun ode egbe won ti o ba ku ati lati yo ese re kuro ninu egbe ode ti aye.
    
IGBELEWON
    Daruko awon koko ti o maa n jeyo ninu oku pipe pelu apeere.            

 IWE AKATILEWA
Adewoyin S.Y (2006) Imo, Ede, Asa Ati Litireso fun ile Sekondiri Agba S.S. 1. Corpromutt Publihers Nig Ltd Oju iwe 106-112

 APAPO IGBELEWON

  1. Daruko awon koko ti o maa n jeyo ninu oku pipe pelu apeere.
  2. Ko apeere ewi alohun ti o je mo asa isinku.

 ISE ASETILEWA
1.Leta ——— ni a maa n ko si ore,ara,ebi ati ojulumo.
(a) eni mimo (b) gbefe (d) aigbagbefe
2.Adiresi meloo ni leta si ore wa maa n ni?
(a) kan (b) meji (d) meta.
3———- ni ewi atenudenu ti awon ode maa n lo lati dagbere fun ode egbe won.
(a)oku pipe (b) igbala (d) iremoje.         
4.Okan lara ohun ti o maa n jeyo ninu oku pipe re ni ———
(a)oriki oku (b) iwa re (d) iye ile ti o ko.    
5.ojo——— isinku ni won maa n yo ese obinrin agba kuro ninu ebi.
(a) keta (b) kejidinlogun (d) kejidinlogbon.

 APA KEJI
1.Ko leta si ore re,ki o si salaye fun un nipa ile-iwe re titun ti o wa bayii.
2.Daruko awon ewi atenudenu ti a n lo fun oku pipe.
b.Salaye koko ti o maa n je jade ninu won pelu apeere    

 
 
 
 
 
 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *