OSE KEFA
EKA ISE: EDE
ORI ORO: ISEDA ORO ORUKO NIPA LILO APETUNPE
- A le seda oro oruko nipa lilo apetunpe apola oro ise (Reduplication of verbs) : apeere;
- Gbomo + gbomo = gbomogbomo
- Jagun + jagun = jagunjagun
- Daran + daran = darandaran
- Peja + peja = pejapeja
- A le seda oro oruko nipa lilo apetunpe oro oruko (Reduplication of noun). Apeere;
- Ale + ale = Alaale
- Agba + agba = Agbaagba
- Omo + omo = Omoomo
- A le seda oro oruko nipa lilo apetunpe elebe (partial reduplication) : Eyi ni ki a fi faweli ‘I’ ti o je mofiimu olohun oke po mo konsonanti akoko ti o bere oro ise, ki a tun fi odidi oro ise ipinle bee kun-un. Apeere;
- Je – j + i = Jije
- Fe – f + I = Fife
- Ra – r + i = Rira
- Ta – t + i = Tita
IGBELEWON:
- Fun isodoruko ni oriki
- Seda oro oruko marun-un nipa lilo apetunpe
ISE ASETILEWA:
- Seda oro oruko mewaa nipa lilo apetunpe
EKA ISE : ASA
ORI ORO: IGBAGBO YORUBA NIPA IYE LEYIN IKU
Yoruba Gbagbo pe “Awaye iku kan ko si, orun nikan ni aare-mabo”. Ohun ti eyi tunmo si nip e gbogbo eda ni o ti dagbada iku, ko si eni ti ko ni ku; olowo n ku, talaka n ku, oba ilu n ku, ijoye n ku, omode n ku, agbalagba n ku.
Yoruba Gbagbo pupo ninu iye leyin iku idi niyi ti eniyan ba ku ni ile Yoruba, dandan ni ki won se awon etutu kan bii; oku wiwe,, fifa irun ori oku okunrin, didi irun ori oku obinrin, wiwo aso ti o dara fun oku, fifi lofinda olooorun kun oku lara. Oniruuru ohun tie nu n je ni won yoo sin pelu oku ki o leri nnkan je ninu irin ajo re.
Ni kukuru, awon Yoruba Gbagbo pe gbogbo ohun ti awon n se ni oku n ri ati pe gbogbo oro ti awon n so ni o n teti si pelu.
IGBAGBO YORUBA NIPA IYE LEYIN IKU BI O SE JEYO NINU ASA YORUBA – AKUDAAYA, ISOMOLORUKO ATI ISINKU.
- AKUDAAYA: Awon akudaaya ni Yoruba Gbagbo pe won ku ki ojo won to pe, ti won ki I le lo si oorun taara.
Yoruba Gbagbo pea won ti o ku lai pe ojo yoo maa lo gbe ni ilu miiran ti a ko ti I mo won ri ati pe bi won ba ri enikeni ti won mo nigba aye won ki won to ku, won yoo fi iru ilu naa sile lo ilu miiran. Pupo awon ti won fi ojo olojo lo yii ni awon eniyan ti se alabapade ni ilu miiran gege bi I eri.
- ISOMOLORUKO : oniruuru oruko amutorunwa ni ile Yoruba ti fi iye leyin iku han. Bi baba agba ni idile oko ba papoda ti okan lara awon iyawo omo re ba bimo ni iru akoko bee ti omo naa si je okunrin, igbagbo Yoruba nipe baba agba ti o ku yii ni o tun pada wa saye ninu ebi won. Iru awon omo bee ni a n so ni ; babatunde, Babajide, Babarinde, abbl. Bi o ba si je iya agba ni idile oko ni o papoda igbagbo Yoruba nip e iya agba ti o ku ni o tun pada wa.
Won a so iru omobinrin bee ni; Iyabode, Iyejide, Yewand, Yetunde abbl.Bi irisi awon omo yii ba siba ti awon baba agba ati iya agba mu won a ma ape won ni “Baba agba ati Iya agba.
- ISINKU: Yoruba Gbagbo pe irin ajo ni oku n rin lo si orun ati pe gbogbo oro ti awon ba n so si iru oku bee ni o n gbo. Orisirisi dukia bii; aso, owo, ileke, oti, ounje lorisirisi ni awon Yoruba maa n ko sinu posi oku lati le ri nnkan lo ninu irin ajo naa. Itoju oku bii; fifa irun ori oku okunrin, didi irun ori oku obinrin, fifi lofinda olooorun didun kun oku lara ni awon Yoruba maa n se nitori won Gbagbo pe iye n be leyin iku. Ba kan naa, won kii je ki ounje tan ninu ile won nitori igbagbo won nipe oku si le pada wa ile lati wa wo awon omo re ki o si le ri ounje je nigba ti o ba wa.
IGBELEWON:
- N je Yoruba Gbagbo pe iye wa leyin iku?
- Salaye igbagbo Yoruba nipa iye leyin iku bi o se jeyo ninu; asa isomoloruko,asa isinku ati akudaaya.
ISE ASETILEWA:
- N je Yoruba gbagbo pe iye wa leyin iku? Ko oruko Yoruba marun-un ti o fi eyi han.
EKA ISE: LITIRESO
ORI ORO: EWI ALOHUN TI A FI ORO INU WON DA WON MO
Ewi alohun ni awon ewi ti a jogun lati enu awon baba nla wa.
O je okan lara litireso ti awon baba nla wa maa n lo lati iwase.
Agbara ti o ya ni lenu ati imo ijinle n be lowo awon Yoruba , idi niyi ti a fi n pe won lolopolo pipe ati alarojinle eda.
Apeere awon ewi alohun ti o fi idi otito mule pea won Yoruba je alarojinle ati olopolo pipe niyi;
OFO
Ofo fe oro ti a n so tabi fo jade ti a fi n segbe leyin oogon tabi ti a n pe lati mu ero okan wa se.
Lara awon oro ti a fi le da ofo mo niyi ;
- Oruko awon emi airi ti a n pe
- Awitunwi awon oro ninu ofo
Apeere ofo awure;
” Itun lo ni ke e fohun rere tun mi se
Ifa lo ni ke e e fohun rere fa mi
Abeere lo ni ke e fohun rere beere mi
Tigi tope ni i saanu afomo
Omo araye e maa saanu emi lagbaja
Omo lagbaja loni o ”
Itumo ofo yii ni pe, nibi ki bi ti o ba n de ki awon eniyan maa fi ohun rere le e lowo
Apeere miiran;
” A-toju-maaro loruko aa peku
A-tagbon-muje loruko aa paarun
A-pantete-ori-rin-lojuto loruko aa pasasi
Adia femi omo iya aje
Won ni ki n maa lo ko sewu
A-toju-maaro ti iku n je ko ni jeku pami
A-tagbon-muje tarun n je ko ni jarun gbemi de
A-pantete-ori-rin ko ni je kasasi mu mi
O di to ! ”
AYAJO
Omo iya ofo ni ayajo sugbon inu ese ifa ni oun ti maa n je jade. Oro enu lasan ni ko nilo oogun rara.
Apeere ayajo ti a fi n da inu rerun duro;
” O-dorita-meta pete isale
O-dorita-meta pero orun oyela
Eyin le yo Olugbon asiri
Ti Oduduwa pa enu re mo
A-ka-woroko-ori-idodo
A-na-le-ori-iwo
Ojo lo de lo mu aganna alaganna gun
Kuro ninu aganna
Ki o wa ibomiiran lo”
OGEDE:
Ohun enu bii ti ayajo ni ogede sugbon ohun enu ti o ni agbara ju ohun enu lo ni. Enikeni ti o ba fe pe ogede gbodo ni ohun ti yoo koko se tabi je gege bii ero ki o to le pe e rara bee ni o gbodo ni ohun ti yoo sare je tabi to la ti o ba tip e e tan ki inira ma ba de ba a. eni ti yoo gbo ogede naa gbodo lo ero tabi ki eni ti yoo pe ogede ti se ohun ti ko ni je ki o se onitoun ba kan.
IGBELEWON:
- Kin ni ewi alohun?
- Salaye awon ewi alohun ti o je orisun ironu, agbara ati imo ijinle awon Yoruba.
ISE ASETILEWA:
- N je ori oro to jo mo ofo ati ayajo wa ninu bibeli bi?