OSE KEJE
EKA ISE: EDE
ORI ORO: LETA AIGBEFE
Leta kiko je ona ti a n gba gbe ero okan wa kale ni ori pepa ranse si elomiiran.
Leta aigbefe nil eta ti a n ko si awon eniyan ti o wa ni ipo giga kan tabi ipo ase.
Awon wonyi le je oga ile iwe, olootu iwe iroyin, Giwa ile ise oba, Alaga igbimo eto ijoba , akowe agba ile ise, abbl.
Igbese kiko leta aigbefe
- Adireesi : Adireesi meji nil eta yii maa n ni,adireesi akoleta ni apa otun loke tente ati adireesi agbaleta ni apa osin iwe ni ibere ila ti o tele adireesi akoleta.
- Ikini ibeere : eyi ni lati fi mo eni ti a n ko leta si bii; “oloootu ile ise iwe iroyin”
- Ori oro : eyi ni ori oro lete ti a n ko.
- Koko leta : Alaye lekun rere lori ohun ti lete naa dale lori leseese ni ipin afo kookan. Leta aigbefe ko fi aaye gba efe tabi awada sise,eredi ti akoleta fi n ko leta re ni yoo so di mimo fun agbaleta.
- Ikini ipari : fifi ifara eni jin si eni ti a n ko leta si tabi si ise eni ni a oo so di mimo (tiyin ni tooto ) ni ipin afo yii,leyin eyi ni ifamisi oruko akoleta ati oruko re ni kikun (full name) yoo wa ni abe re.
- Apo iwe : odi keji apo iwe nibi ti goomu wa ni adireesi akoleta yoo wa,sitanbu yoo wa ni oju apo iwe ni apa otun loke tente, adireesi agbaleta yoo wa ni isale sitanbu yii.
Ori oro to je mo aroko aigbefe
- Ko leta si oloootu ile ise iwe irioyin ‘AIT’ lati fi edun okan re han ijoba nipa ini lara ti o de ba ara ilu nipa owon gogo epo robi ni ipinle re.
- Ko leta si Alaga ibile re lati mo riri ise takuntakun ti won n se lowolowo ni opopona marose ijoba ni Abule-egba ni ipinle eko.
- Ko leta si oga ile eko re lati fi imoriri re han nipa atunse ti o de ba ayika ile iwe re ni saa yii.
- Ko leta si olootu iwe iroyin Akede Oodua lati wa wo ere boolu oloree-soore ni ile iwe re ni ojo isegun, ose to n bo.
IGBELEWON:
- Kin ni leta aigbefe?
- Ko awon igbese ti a ni lati tele bi a ba n ko leta aigbefe
- Ko ori oro to jo mo leta aigbefe meta
ISE ASETILEWA:
- Ko leta si oloootu ile ise iwe irioyin ‘AIT’ lati fi edun okan re han ijoba nipa ini lara ti o de ba ara ilu nipa owon gogo epo robi ni ipinle re.
EKA ISE: LITIRESO
ORI ORO: AWON OHUN MIMO NINU
ESIN IBILE
Esin ibile ni awon esin abalaye ti a jogun lati owo awon baba-nla-wa.
Yoruba Gbagbo pe Olodumare je mimo bee ni awon orisa re, Ile awon orisa ile Yoruba je mimo, awon ohun elo won bakan naa si je mimo.
Awon elo awon orisa ile Yoruba niyi ;
- Ere orisa
- Aso ala orisa
- Ikoko omi orisa funfun
- Sese efun
- Igba funfun
- Igi orisa funfun
- Ebo orisa funfun
- Agbada ati ada orisa funfun
- Ileke funfun abbl.
Siwaju si I, mimo ni awon orisa ile Yoruba wonyi; Obatala, Orisa oko, Osun, Olokun, Obalufon abbl. Mimo ni awon eni orisa bii; abuke, afin, arara, aro, iya olorisa abbl, nitori pe Yoruba Gbagbo pe Obatala ni o seda won bee.
Mimo ni ‘omi ajifowuro’ pon nitori owuro kutukutu ni awon aworo Obatala n jip on omi naa fun iwosan ati fun mimu awon olusin re. Won Gbagbo ninu omi yii pe o dara fun alaboyun lati bi were, o dara fun iwure, o dara fun iwosan loniruuru.
Ojubo orisa je ibi owo, eewo ni fun aworo obinrin ti o n se nnkan osu lati de ibi ojubo orisa. Inu igbo kijikiji leyin odi ilu, inu ile, orita meta ni ojubo orisa maa n saba wa. Mariwo tabi aso funfun ni awon aworo orisa yoo ta si oju ona ojubo bee ni won yoo kun ara ogiri ni efun gege bii ami ohun mimo.
IGBELEWON:
- Fun esin ibile loriki
- Salaye awon ona tie sin ibile n gba fi ohun mimo han
- Daruko ami idamo awon elesin ibile meta ti o je mimo
- Daruko ibi meta ti awon elesin ibile n lo gege bi I ojubo.
ISE ASETILEWA:
- Daruko ohun idamo obatala merin ti o je mimo.