OSE KETA
EKA ISE : EDE
ORI ORO : APOLA ORO-ORUKO ATI ISE RE
Apola je apa kan gbolohun,eyi ti o le je eyo oro tabi akojopo oro. Apeere;

  1. olumide ra oko ( eyo oro )
  2. ijoba ipinle Ekiti san owo osu awon osise ( akojopo oro )
  • Apola – oruko : Eyi ni eyo oro oruko kan tabi apapo oro oruko meji tabi ju bee lo ninu gbolohun. Apeere;
  1. Ige ra bata
  2. Igi wo                                                                                                                            
  3. Ade
    omo
    oba se igbeyawo
  4. Olumide Bakari gba ipo kin in ni
  5. Alani
    Aduke
    ile
    oloye se isile abbl

Ise ti Apola oruko n se ninu gbolohun

  1. O n sise Oluwa gbolohun : eyi ni eni ti o se nnkan ninu gbolohun, o le je oro oruko kan soso tabi eyi ti o je apapo oro oruko. Apeere;
  • Kolawole gba oye abobaku
  • Adufe koi le
  • Fijabi ta ile
  1. Apola oro oruko maa n sise abo : eyi ni olufaragba nnkan ti oluwa se ninu gbolohun. O le wa ni aarin tabi ipari gbolohun. Apeere;
  • Baba agba ra oko tuntun
  • Remi mu omi
  • Bolaji pa eye owiwi
  1. Apola oro oruko tun n sise eyan : nigba ti oro oruko meji ba tele ara ninu gbolhun, eyan ni oro oruko keji .eyi le jeyo ni aarin tabi ipari gbolohun. Apeere;
  • Ounje Jumoke ni mo fe je
  • Awa egbe ode ilu niyi
  • Ile oba oyingbo ni mo n lo
  • Okunrin oloro naa ti ku
  • Oluko na Anike Olowonifaari

 IGBELEWON:

  • kin ni apola?
  • Fun apola oro oruko ni oriki
  • Salaye Pataki apola oro oruko ninu gbolohun.

ISE ASETILEWA:
Toka ise ti apola oruko kookan ti a fa ila si nidi n se ninu gbolohunisale yii;

  • Timileyin je oye
  • Jide Animasahun Agbejoro je ipe oluwa.
  • Yemi pa odu oya
  • Okunrin oloro ra oko tuntun
  • Oluko na olumide Arowolo

     
     

EKA ISE : ASA
ORI ORO : IGBAGBO ATI ERO YORUBA NIPA ORISA
Awon orisa ile Yoruba je asoju , alarinna , alagata, alagbawi ati iranse fun Olodumare.
Yoruba Gbagbo wi pe okanlenirinwo (401) ni awon orisa ni ile Yoruba ati pe a le pin won si ona meji Pataki. Awon niyi ;

  • Awon orisa ti Olodumare ran wa si ile aye : awon orisa wonyii kii se eniyan rara, orisa ni Olodumare da won ati orun ni won si ti row a si ile aye. Apeere iru awon orisa bee ni; Ogun , Obatala , Orunmila , Esu ,
  • Awon orisa ti awon eda eniyan so di orisa leyin iku won nitori ise ribiribi ti
    won se nigba ti won wa laye. Apeere eyi ni ; Yemoja , Sango , Oya, Osun, Orisa oko, Moremi abbl.

     

  • Igbagbo ati ero Yoruba nipa Obatala (Orisa-nla)

Yoruba Gbagbo pe obatala ni asaaju gbogbo awon orisa patapata. Won si Gbagbo pe oun ni Olodumare koko seda o si je igbakeji Olodumare ninu ise iseda. Yoruba Gbagbo pe Obatala yii ni o sise iseda mimo oju, imu , eti, ati awon eya ara miiran nigba ti Eleda ba ti seda eniyan ni borogidi tan. Idi niyi ti awon Yoruba fi n pe obatala ni ” Ajala Alamo ti I mo ori ” tabi ” Alamo rere ” . igbagbo won si ni pe ise owo Obatala ni awon abuke, Aro, Afin, Afoju, Amukun-un. Idi niyi ti won fi n pe won ni “Eni Orisa”.
Eewo awon olusin Obatala: emu, ounje elepo,iyo, aja,elede tabi mu omi ikasi(omi ti won ti pon sile ti ki I se oojo)
Ounje obatala : obe eran igbin,obi ati otika( oti oka baba)
Ohun elo Obatala : ileke funfun, sese funfun, bata funfun, aso funfun, igba funfun, abbl. Gbogbo ohun elo Obatala funfun ni.

 

  • Igbagbo ati ero Yoruba nipa sango

Sango ni Yoruba n pe ni “Olufinran”. Won Gbagbo pe o ni oogun,igboya ati agbara lori ojo,ara ati monamona. O si je eniyan lile. Bi o ba n soro, ina maa n jade ni enu re. oruko awon iyawo re ni; oya,Osun ati oba. Sango da ija sile laaarin ijoye ilu meji nigba ti o si ri I wi pe asiri oun fe tu ati pea pa oun ko ka mo ni o fi ori oye sile ti o si binu pokunso.
Ounje Sango : amala, pelu obe ewedu,eran agbo,orogbo ati obi
Ilu Sango : ilu batas
Ohun idamo awon olusin re ; Irun ori didi t’okunrin ati t’obinrin

 

  • Igbagbo ati ero Yoruba nipa Orunmila

Orisa yii je eni ti Olodumare fun ni ogbon ati oye lati fi tun ile aye se. idi niyi ti won fi maa n ki I ni “Akere-finu-sogbon”. bakan naa won a maa pe e ni ” Elerii-ipin” nitori won Gbagbo pe o wa lodo Olodumare nigba ti o n se ipin eda. Awon Yoruba a si maa bere ohun kohun ti won ba fe lowo re nitori ogbon ti Olodumare fun un. Bakan naa, won gbagbo pe “Agbaye- gborun ” ni ,o binu fi ile aye sile osi fi ekuro ‘Ikin merindinlogun” ropo ara re ni ile aye. Ekuro yii ni awon babalawo n lo lati difa titi di oni olonii.
Ohun elo ifa : opon ifa, iyerosun,opele,ikin merindinlogun(16),irukere,awo ifa, abbl
Ohun elo ibo re : eku meji, eja meji,igbin,ewure,adiye,isu,aguntan,obi abbl.

 IGBELEWON:

  • Salaye isori awon orisa ile Yoruba
  • Salaye igbagbo Yoruba nipa orunmila, Obatala ati sango

ISE ASETILEWA:

  • Bawo ni a se le sapejuwe awon orisa ile Yoruba
  • Fi igbagbo Yoruba han pe eniyan ni sango nigba kan ri nigba aye re.

 EKA ISE : LITIRESO
ORI ORO : KIKA IWE LITIRESO APILEKO TI IJOBA YAN(EWI)

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *