OSE KEJI
EKA ISE : EDE
ORI ORO : LETA KIKO
Leta kiko je ona ti a n gba gbe ero okan wa kale ni ori pepa ranse si elomiiran.
ISORI LETA
- Leta gbefe
- Leta aigbefe
LETA GBEFE
Leta gbefe ni leta ti a maa n ko si eni ti o sunmo wa; o le je molebi, ore, tabi alajose.
Leta gbefe fi aaye gba eniyan lati fi ero inu re han elomiiran. O le je baba, iya , egbo, aburo, ore ati ojulumo eni gbogbo.
Igbese kiko leta gbefe
- Adiresi akoleta : Apa otun ni oke tente ni adireesi akoleta maa n wa. Nonba ojule, opopona tabi apoti ile ifiwe ranse si (p.o. Box) , oruko ilu ati ipinle eni ti a n ko leta si ni yoo wa ninu adireesi yii.
- Deeti : ojo, osu, ati odun ti akoleta n kowe re yoo wa ninu adireesi yii.
- Ikini ibere : apa osin ni ibere ila ti o tele deeti ni a n ko eyi si pelu ami idanuduro die ni ipari re.
- Koko leta : eredi ti akoleta fi n ko leta re ni yoo so di mimo ninu ipin afo yii.
- Ipari/ikadi leta : owo otun ni akoleta yoo sun owo si ni ori pepa, oruko akoleta nikan ni yoo han ni opin leta yii pelu ami idanuduro die
Ori oro to je mo leta gbefe:
- Ko Leta si baba re lati bere owo ile iwe saa keta ninu eto eko re ki awon alase ile iwe ma aba le o jade lenu ise.
- Ko leta si ore re ti o wa ni ilu oba lati ran an leti ayeye ojo ibi re ti o n bo ninu osu kewaa odun yii
- Ko leta si egbon re obinrin lati ki I fun ipalemo eto igbeyawo re to n bo lona ninu osu kefa, ojo kerinla odun ti a wa ninu re yii abbl
IGBELEWON:
- Kin ni leta kiko?
- Daruko ona meji ti a le pin leta kiko ede Yoruba si
- Salaye awon ona ti a n gba lati ko leta gbefe
ISE ASETILEWA:
Ko leta si ore re kan ti o wa ni ilu odi keji lati wa si ayeye igbeyawo egbon re obinrin ti o n bo ni ojo karun-un osu keje odun ti a wa ninu re yii.
EKA ISE : ASA
ORI ORO : IGBAGBO YORUBA NIPA OLODUMARE
Aimokan-mokan lo mu ki awon oyinbo alawo funfun maa so pe Yoruba ko mo Olorun ati pe won ko tile gba pe Olorun wa, ohun ti a le fi owo re soya ni pe ki awon elesin kiritieni ati musulumi to mu esin ajeji won de aarin awon Yoruba ni won ti gbagbo pe eni kan n be to n je Olodumare ati pe oniruuru oruko ni won n pe Olodumare yii lati fi igbagbo won mule pe O n be.
Ba kan naa, Yoruba pe Olodumare wa nibi gbogbo;idi niyi ti won fi maa m so pe “Amookun-jale bi oba aye ko ri o,torun n wo o ”
ONIRUURU ORUKO TI YORUBA N PE OLODUMARE
- Alaaanu ati oloore : eni to maa n se aanu fun gbogbo eniyan bakan naa ni o kun fun oore(o maa n soore kiri ni)
- Okan soso ajanaku to n migb kiji kiji : ajanaku je eranko to rinle to si tobi ju ninu igbo. O je oba fun awon eranko.Yoruba fi Olodumare we eranko yii lati f titobi re ati pe nibi kibi ti Olodumare ba wa gbogbo eniyan maa n ni imolara pe o wa nibe.bakan naa won gbagbo pe ko si ohun ti ko le e se
- Olu-orun, Olugbala : eni to ni orun, eni ti o n gba ni ninu isoro
- Eledaa Adedaa : oun ni o da gbogbo eda patapata. Olodumare je eni to n se eda nnkan yala eniyan , eranko tabi ohun ailai-lemi gbogbo
- Onidajo ododo : ko ki I segbe leyin enikeni.olotito ni, ki I gbe ebi fun alare bee ni ki I gbe are fun elebi
- Oba awon oba :olodumare je oba fun gbogbo awon Oba aye
- Olupese : oun lo n pese fun gbogbo eda laye.bakan naa, o n pese fun eye oju orun ati gbogbo eda miiran
Ni kukuru, awon Yoruba Gbagbo pe Olodumare wa ati pe o ni gbogbo nnkan lodu-lodu ni ikawo re,ko si eni ti a le fi we rara.
IGBELEWON:
- Salaye igbagbo Yoruba nipa Olodumare
- Daruko oniruuru oruko ti Yoruba n pe Olodumare
- So itunmo okookan irufe oruko bee
ISE ASETILEWA:
- N je looto nipe awon Yoruba ti ni igbagbo nipa Olodumare? Salaye oruko maru-un ti o fi igbagbo Yoruba mule nipa Olodumare
EKA ISE: LITIRESO
ORI ORO: EWI ALOHUN TI A FI ORO INU WON DA WON MO
Litireso ni akojopo ijinle oro ni ede kan tabi omiiran ti a fi ohun enu gbe jade tabi ti a se akosile re
Isori litireso
- Litireso alohun(atenudenu)
- Litireso apileko(alakosile)
- Litireso alohun : litireso alohun ni awon ewi Yoruba ti a jogun lati enu awon baba nla wa
O je ewi ti awon babanla wa ti n lo lati igba iwase ki awon oyinbo alawo funfun to mu esin ajeji ati ogbon mo-on-ko- mo-on-ka wo ile wa
Awon esin ibile Yoruba ni wonyi;
- Oya-pipe
- Sango-pipe
- Esu-pipe
- Orin arungbe
- Iyere- ifa
- Ijala abbl
Bi a se le da awon esin ibile wonyi mo
- Oya-pipe : akoko odun oya ni won maa pe oya. Awon olusin re ni a n pe ni ” iya oya” .oro inu ewi won maa n da lori ife oko
Ounje fun irubo: amala ati obe ilasapelu ewure
Eewo orisa : agbo tabi irun ori re ko gbodo de ojubo oya
- Esu-pipe : Esu je iranse ati olopa okunkun fun Olodumare. Awon olubo re ni a n pe ni “Eleesu” akoko odun esu ni awon olusin re maa n pe, awon obinrin ni o wopo ninu awon aworo re
Ounje fun irubo : epo , ebo
Eewo esu : adi ati obi
- Orin Arungbe : a tun le pe e ni orin oro. Awon oloro ni won maa n ko orin yii ni akoko odun re. won maa n fi orin naa bu oniwa ibaje lati le dekun iwa ibaje ati lati fi tu asiri ohun ikoko awon onise ibi ti won ro pe eniyan ko mo
Ounje fun irubo : efo ekuya, asaro, obuko, adiye, iyan ati obe egusi.
Eewo oro : a) obinrin ko gbodo ri oro
b) A ki I ri ajeku oro
IGBELEWON:
- Kin ni litireso?
- Ona meloo ni a pin litireso Yoruba si?
- Fun litireso alohun loriki
- Daruko esin ibile meta ni ile Yoruba ati bi a se le da won mo
ISE ASETILEWA:
- Awon wo ni olusin ijala ati sango?salaye salaye won ni soki