OSE KEWAA
EKA ISE : EDE
ORI ORO: IHUN APOLA
APONLE ATI ISE TO N SE NINU GBOLOHUN
Apola aponle ni oro aponle kan soso tabi apapo oro aponle pelu isori oro miiran ti o n sise gege bi epon fun oro ise ninu gbolohun.
Apeere;
- Mo je iyan tan
- Omo naa dudu fafa
- O lo pelu ibinu abbl,
Akiyesi : apola aponle le je akanpo wunren oro atokun pelu oro oruko.
Orisi apola aponle meji ni o wa;
- Apola-ajemopon-on-le asaaju ise : apeere oro epon fun oro ise ti a le ri labe isori yii ni ; n , ti , yoo , maa , ko , jaja , kuku , tile , tetye , papa , moomo , abbl. Apeere;
- mo n lo
- se o papa je ounje naa?
- Mo tile maa papa gba owo naa
- Apola ajemapon-on-le agbeyin ise: gege bi I oruko re , eyin oro ise ni o ti n jeyo ninu gbolohun lati fi kun itumo oro ise.
Apola ajemapon-on-le yii pin si isori. Awon niyi;
- Apola ajemapon-on-le alafiwe : apola yii maa n so bi oro ise se ri nipa sise afiwe isele kan pelu omiiran. Apeere;
- Tope n korin bi I eye
- Adebiyi dudu bi I koro isin
- Olumiide n sare bi I ehoro abbl
- Apola ajemapon-on-le – alasiko : O je apola afi akoko han. Apeere ;
- Ounje yoo po ni odun yii
- Alani Arowolo n se igbeyawo ni ola
- Mo fe ri o ni otunla
- Apola ajemapon-on-le – onibi : Eyi n toka si ibi ti isele kan ti waye. Apeere ;
- Mo ri ayomide ni ilu Oyo
- Gaari po ni agbegbe ijebu
- Anike se ayeye ojo ibi re ni ilu oba
- Apola ajemapon-on-le –onidii : Apola yii n so idi abajo ti isele kan fi waye. Apeere;
- A n sise nitori owo
- Iya n jiya pupo nitori omo. Abbl
- Apola ajemapon-on-le oniba : Eyi n so bi nnkan se sele. Apeere;
- Won gba wa lalejo towotese
- Omo naa sun worowo
- Alaga se alaye oro naa ni sise-n-tele
- Apola ajemapon-on-le onikani : Eyi n toka ohun ti iba sele ka ni ohun kan saaju re. Apeere ;
- Okete iba jeyan kani ile re gba odo
- Yemi iba jiya ka ni o kuna ninu eto eko
IGBELEWON:
- So itunmo oro aponle
- Salaye isori apola-aponle meta pelu apeere meji meji
ISE ASETILEWA:
- Ko apeere soki lori isori oro apola-aponle meji.
EKA ISE : ASA
ORI ORO : OWE ILE YORUBA
- Owe ni afo ti o kun fun imo ijinle, ogbon ati iriri awon agba.
- Owe lesin oro , oro lesin owe, bi oro ba sonu, owe ni a fi n wa.
- Awon agba n lo owe lati yanju oro to takoko.
Orisi owe Yoruba
- Owe fun ibawi : apeere;
- Agba ki I wa loja ki ori omo
tuntun wo
Itumo : Awon agba je olutona iwa rere fun awon omode ni awujo.
- A n gba oromodie lowo iku, o ni won o je ki ohun lo ori aatan lo je.
Itumo : a maa n pa owe yii fun eni ti o n rin irin ti abayorisi lewu ti o si fi gbigbo se alai-gbo, o n te ife
inu ara re lorun.
- Owe ikilo :
- Aguntan to ba ba aja rin
yoo je igbe
Itumo : ti awon agba ba se akiyesi pe eni kan n ba eniyan buburu kegbe po,won yoo fi owe yii kilo fun iru eni bee lati year ki o ma aba parun tabi ko irufe iwa buburu naa.
- Ise ni oogun ise
Itumo : eni ba fe se aseyori yala lenu ikose tabi ninu eto eko a tepa mose daadaa ( a mura si ise )
- Owe fun imoran :
- Agba to ba je ajeeweyin ni
yoo ru igba
re dele koko
Itumo : agba to ba hawo ko ni ri omode tabi eniyan kankan ran-an lowo lati gba eru tabi jise fun-un.
- Bi ara ile eni ba n je kokoro arinya, bi a ko ba so fun un, here-huru re ko ni je ki a sun loru.
Itumo : bi ara ile eni ba n huwa ibaje ti a ko ba so fun un, nigba ti wahala tabi ijiya re ba de yoo ta ba ni ( eniyan yoo ni ipin tabi je ninu iya bee )
- Owe fun alaye :
- Agba to n sare ninu oja, bi nnkan o le , a je pe
o n le nnkan.
Itumo : Agba tabi eniyan to n sise karakara mo idi ti oun fi n se e loju mejeeji
- A ni ka je ekuru ko tan labo, n se ni a tun n gbon owo re sinu awo tan-n-gan-ran
Itumo : awon agba maa n pa owe yii bi wahala tabi ede aiyede kan ba sele ti won si n gbiyanju lati yanju re, ti won tun wa se akiyesi pe awon kan fe hu u sita ( awon kan ko fe ki o tan )
- Owe fun isiri :
- Bi ori ba pe nile a dire
Itumo : bi iya ba n je eniyan de bi pe o fe si oro so tabi so ireti nu, awon agba a maa lo owe yii lati tu u ninu pe ojo ola yoo dara.
- Pipe ni yoo pe , akololo yoo pe baba
Itumo : ko si ipenija ti eniyan le maa la koja, o le dabi eni pe ko sona abayo sugbon ni ikeyin ireti n be
Iwulo owe ni ile Yoruba
- O n je ki a fi ododo oro gun eniyan lara ( ba eniyan wi ) lai binu
- Wo n lo o lati gbe oro to wuwo fun eniyan lati so kale ni ona ti ko fi ni binu.
- Owe n gbe ogo ede yo
- A n lo owe lati fi kilo iwa ibaje
- A n lo o lati fi gba eniyan ni iyanju
- Awon agba n lo owe lati fi yanju aawo abbl.
IGBELEWON:
- Fun owe ni oriki
- Ko orisi owe pelu apeere
- Ki ni Pataki owe ni awujo Yoruba.
ISE ASETILEWA:
Ko owe ikilo marun-un pelu itumo okookanEKA ISE : LITIRESO
ORI ORO: KIKA IWE LITIRESO TI IJOBA YAN