OSE KESAN-AN
EKA ISE: EDE
ORI ORO: AWE GBOLOHUN EDE YORUBA
Gbolohun onibo ni gbolohun ti a fi gbolohun miiran bo inu re.
Awe gbolohun Ede Yoruba ni gbolohun onibo. A pin gbolohun yii si ona meji, awon niyi;
- Olori awe gbolohun
- Awe gbolohun afibo/afarahe
- Olori awe gbolohun : eyi ni awon gbolohun ti o le duro bii odindin gbolohun,o le da duro ki o ni itumo ti o peye. Apeere;
- Ile naa dun-un wo
- Omo naa yoo dake
- Awon ole poora
- Ebi alayo abbl.
- Awe gbolohun afibo : gbolohun yii je eyi ti ko le da duro ki o ni itumo ti o peye. Apeere;
- ……………….. bi o ba de
- …………………pe o gbo
- ………………..ti mob a dolowo
- ………………..ki n to lo.
Ninu apeere oke yii, awe gbolohun afibo ko ni itumo, oro abo ni ti o ni lo olori gbolohun fun itumo kikun. Bi apeere;
- Wa ri mi (olori awe gbolohun) bi o ba de ( awe gbolohun afarahe)
- O ya mi lenu ( olori awe gbolohun ) pe o gbo ( awe gbolohun afarahe )
- Ma ra oko fun baba mi (olori awe gbolohun ) ti mo ba dolowo ( awe gbolohun afarahe )
- Ma a ri o (olori awe gbolohun) ki n to lo ( awe gbolohun afarahe ) abbl.
IGBELEWON:
- Fun gbolohun onibo ni oriki
- Ko ona meji ti a le pin gbolohun onibo si ki o si salaye pelu apeere
ISE ASETILEWA:
- Pelu apeere ti o dangajia salaye ona meji ti a pin gbolohun ede Yoruba si
EKA ISE : ASA
ORI ORO : ASA ISINKU NI ILE YORUBA
Isinku ni eye ikeyin ti a se fun oku logan ti o ku titi di akoko ti a fi sin-in
Yoruba Gbagbo pe “eni sinku lo pale oku mo, eni sukun, ariwo lasan lo pa ”
Igbese isinku ni ile Yoruba
- Itufo : eyi ni kikede iku oloogbe fun awon ebi ,ana ati gbogbo eniyan. Ilu liu, ariwo, ekun sisun, ibon yinyin ni a fi n tufo oku.
- Ile oku gbigbe : awon ana tabi omo okunrin ile oku ni yoo gbe ile iwon ese mefa lati sin oku
- Oku wiwe : won ni lati fa irun ori oku ti o ba je okunrin, won a si di irun ori oku ti o ba je obinrin. Gbogbo eekanna owo ati ese oku ni won yoo ge leyin naa ni won yoo fi ose ati kanin-kain pelu omi to loworo we e. leyin eyi ni won yoo wo aso to dara fun oku.
- Oku tite : inu yara tabi odede ti won se losoo ni won n te oku si ni ori ibusun pelu aso funfun ati lofinda olooorun bee ni won yoo fi owu di iho imu ati eti re mejeeji. Ni asiko yii, awon obinrin ile yoo maa ki I ni mesa-an mewaa.
- Alejo sise : Awon omo ati ebi oku yoo peae jije ati mimu fun awon okunrin ile, awon ana ti o gbele oku ati gbogbo alejo patapata.
- Isinku : eyi ni ayeye “fifi erupe fun erupe”. Won yoo gbe oku sinu posi pelu oniruuru nnkan bii; owo,ounje,ileke,aso,bata, opa itile ati nnkan meremere miiran lati lo ni iri ajo naa nitori Yoruba Gbagbo pe iye wa leyin iku ati pe irin ajo ni oku n rin lo si orun. Ni geere ti won ba ti gbe oku sinu koto, awon omo oloku ati ebi re yoo bu eeru si oku naa lara.
IGBELEWON:
- Kin ni Yoruba n pe ni isinku?
- Salaye igbese isinku ni ile yoruba
ISE ASETILEWA:
- Salaye lekun-un rere isinku oba ni ile Yoruba.
EKA ISE : LITIRESO
ORI ORO : KIKA IWE EWI TI IJOBA YAN