OSE KESAN-AN

 EYA AWE GBOLOHUN
Gege bi a se so saaju pe awe gbolohun pin si meji: olori awe gbolohun ati awe gbolohun afarahe.
1 OLORI AWE GBOLOHUN Olori awe gbolohun ni gbolohun to le da duro pelu itumo.Fun apeere.
    Bola jeun ni ori tabili
    Sade ra aso ti ko ni iho lara
    Ojo gbodo jeun ki o to lo oogun re. Gbogbo awon ti a fala si nidi yii ni a pe ni olori awe gbolohun. Sade ra aso, Bola jeun, Ojo gbodo jeun; awon wonyi ni itumo ju ni ori tabili,ti ko ni iho lara,ki o to lo oogun.
2.    AWE GBOLOHUN AFARAHE
Eyi ni apa keji odidi gbolohun ti ko le da duro funra re,o fi ara he olori awe gbolohun ni Apeere: –
Ode wa mu oti yo ni oru ana
    Gbogbo ilu gbo pe oba ti waja
     Mo ti lo ki ore mi to de

 IGBELEWON

  1. Iyato wo lo wa laarin olori awe gbolohun ati awe gbolohun afarahe?
  2. Fa ila si idi awe gbolohun afarahe ninu awon gbolohun wonyi:

a    Inu mi dun pe n ko subu
b    Bade n korin bi eye
d    Oga so pe ki a tete de
e    Oga olopaa de ni oru ana

 ORISII EYA AWE GBOLOHUN AFARAHE ASAPONLE
(a)    Awe Gbolohun Afarahe Asaponle Alafiwe: gbolohun yii maa n se afiwe nnkan meji wunren “bi” tabi “bi” ni atoka re
        Ade nkorin bi eye se nkorin
        Omo naa kigbe bi eni ti agbon ta
(b)     Awe Gbolohun Afarahe Asaponle Alasiko: eyi maa n toka asiko ti nnkan sele ninu gbolohun tabi igba. Apeere: –
        Baba maa wa nigba ti o ba de
        Mo ri tade ni ale ana
        Bo se n bo lati ile lo ti raa dani
(d)    Awe Gbolohun Afarahe Asaponle Onibi:- A maa n fi eleyi toka ibi ti isele inu gbolohun ti waye. Apeere:
        Mo ba ore mi nibi ti o ti n mu oti
        Tomi pade oko re ni ile ijo ti o lo.
        Oluko gba mi ni ori
(e)     Awe Gbolohun Afarahe Asaponle Onidii Abajo:- eyi ni a fi maa nsalaye okunfa isele kan ninu gbolohun. Apeere
        Mo n jiya nitori ki n le joro
        Baba tete jii ko le sin ore re de idiko
        Akeko naa tera mose ko le gbebun
(e)     Awe Gbolohun Afarahe Asaponle Onikan: – eyi maa n so ohun ti iba sele bi nnkan miran ba sele saaju ninu gbolohun Apeere: –
        Nba tele yin lo, kani mo tete ji
        Kani mojisola wa ni, oju iba tii
        N ba ra moto kani mo lowo
(f)    Awe Gbolohun Afarahe Asaponle Oniba:– irufe gbolohun yii maa n so iru ona ti nnkan gba sele ninu gbolohun. Apeere:- Ojo naa ro bi eni pe ile yoo ru
    Ounje yii dun bi eni pe ki n ma siwo
    Oluko na akekoo naa ni ana daju bole
IGBELEWON
1.    KI ni a n pe ni awe gbolohun?
2.    Iyato wo lo wa laarin olori awe gbolohun ati awe gbolohun afarahe?
3.    Ona meloo ni ale pin gbolohun afarahe pin si, daruko won.
4.    Ona meloo ni awe gbolohun afarahe asaponle pin si, daruko won.

 IWE AKATIELWA
1.    S.Y Adewonyi (2004) New Simplied Yoruba L1 Copromutt Publisher Book Three Oju Iwe 43 – 44
2.    Oyebanji Mustapha (2002) Eko Ede Yoruba Titun University Press Plc Iwe Keji Oju Iwe 11, 12
3.    Egbe Akomolede ati Asa Yoruba (2003) Eko Ede ati Asa Yoruba Iwe Keta Oju Iwe 22- 23

 IGBAGBO AWON YORUBA NIPA ASEYIN WAYE ATI AWON ABANI EDA.

  • Itumo aseyinwaye (iye leyin iku)
  • Ohun to mu Yoruba gbagbo pe ajinde n be leyin iku

AKOONU
Awon Yoruba ni igbagbo ninu iye leyin iku, won gbagbo pe bi eni won ba fi owo rori ku, o le pada wa ya lodo omo re ki won si tun bi. Eyi ni o mu won maa so oruko bii Babawale, Babajide, Iyabode, Yejide. Bakan naa won gbagbo pe eni ti o ba ku ni rewerewe ko le lo si orun taara, kaka bee yoo maa rin kaakiri ni, o si tun le lo si ile ibomiran lati maa gbe, iru awon bee ni a mo si akudaaya. Bakan naa nitori igbagbo ti won ni ninu iye leyin iku ni won se maa n sin owo, ounje ati awon nnkan miiran mo oku laye atijo pe ti oba je ile ibomiran, a le ri owo ati ounje lo lohun-un.
Igbagbo awon baba-nla wa nipa abiku tun fi igbagbo ninu iye, leyin iku han, eyi ni o mu ki won maa so omo won loruko bii Malomo, Okoya, Kokumo, Kosoko abbl.
Igbagbo awon baba wa tun han nipa abobaku, ni aye atijo ti oba ba ku, ti won ba maa sin-in pelu Abobaku ni, awon wonyi logbodo ku pelu oba, won gbagbo pe ti oba ba ji si ile ibomiran, ko le ri awon eru ti a maa ran nise.

 IKINI
Awon Yoruba ni igbagbo ninu iye leyin iku. Eyi si han ninu ikini won lakoko ti oku ba ku . Won a ni iya a ya o. Baba a somo o.

 Igbelewon:
Pelu apeere salaye Igbagbo awon Yoruba ni pa aseyinwaye ati abani-eda.

 EKA EDE
EDE YORUBA ATI AWON EKA RE
Ki ni ede Yoruba? Okan lara awon ede pataki ti a n so ni orile-ede Naijiria ni ede Yoruba. O je ede ti o gbajugbaja. Ti o si bi opolopo omo. Awon omo ti o bi yii ni eka ede ti o wa ni abe isori ede Yoruba. Ede yii ni a le ka kun ede ajumolo ni aarin awon Yoruba. Ohun ni ede ti a fi maa n se ipade, Ko omo ni ile iwe, ko iwe iroyin, polowo oja, ti a si tun n lo o lati yannanna ohun ti o ba ruju laarin ara wa. Idi niyi ti a fi ka kun ede ajumolo.
    Ipinle mesan ni ede Yoruba je ede abinibi fun ni orile-ede Naijiria. Awon ipinle bii: Eko, Ogun, Oyo, Osun, Ondo, Ekiti, Kuwara, Kogi ati Edo. Nitori idi eyi koseese ki iyato diedie ma wa lati awujo kan de ekeji. Koda iyato yii le farahan de ibi pe a fere le ri eka ede wonyi gege bi ojulowo otooto. Die lara awon eka ede Yoruba ni Ife, Owo, Remo, Awori, Egba, Ijebu, Oyo, Onko, Igbomina, Akoko, Ekiti, Ijesa, Ketu, Gbede, Eko abbl.
    Okookan awon eka ede wonyi ni o tun ni eka won. Fun awon apeere awon ilu ti o n so Ijebu ni Epe, Ikorodu, Ijebu Ode, Remo, Ikenne.
    Awon ilu ti o n so Onko ni: Ayetoro ati Saki.
    Awon ilu ti o n so Ibarapa ni: Lanlate, Eruwa, Igboora, Tapa, Igangan.
O soro lati so ni pato, iye eka ede to wa ninu ede Yoruba, nitori pe bi ilu se n paala laarin ara won, ni iyato die n ba eka ede won. Sugbon nitori pe agboye wa laarin awon ilu ti won jo paala, a ko ni tete fura si iyato awon eka ede ti won n so. Fun apeere, awon ara Saki gbo Iganna, Iganna gbo ti Iganna. Igboora gbo ti Igangan. Ayetoro gbo ede Igboora ni agboye Egba gbo ede Ayetoro. Remo gbo ede Egba. Ijebu gbo Remo bee ni awon Ijebu Waterside gbo ede awon Ilaje. Sugbon ti ara Saki ba n takuroso pelu ara Ilaje ese odo, o se e se ki agboye ma wa. Won tile lero pe ede otooto ni awon n so.
    O ye ki a mo pe ko si eka ede to je erusin fun eka ede miiran, sugbon o se e se ki won gbajumo ju ara won lo. Ise kan naa ni gbogbo eka ede jo n so fun ibanisoro ati ibagbepo ojoojumo ni awujo kookan.
EDE YORUBA AJUMOLO
    Yoruba ajumolo ni ede Yoruba ti a n so ti ki i se okan naa pelu eyikeyi awon eka ede ti a ti so saaju. Awon miiran a tie maa pe e ni ojulowo ede Yoruba sugbon a ko fee se eleyi. Bi a ba pe Yoruba ajumolo ni ojulowo ede Yoruba a je pe a gba pe gbaro-gudu ni eka ede Yoruba to ku. Eleyii ko dara to.
ORIKI FUN EDE ABINIBI
Ede abinibi ni ede ti a bi omo sinu re, ti omo naa dagba sinu re ti o si gbonju ba ni awujo ti o ba ara re. Ede abinibi ni ede ti omo maa n gbonju ba ni ayika re nigba ti o koko bere oro siso. Eyi maa n wa lowo agbegbe ti omo bee ba ara re. Omo ti obi re je Hausa ti won gbe ni ile Yoruba. Ede abinibi omo naa yoo je Yoruba.

 ORISUN EDE YORUBA
    Ede Yoruba je okan lara awon ede ti a n so ni orile ede Naijiria. Looto ni a ri ibi ti won ti n so ede Yoruba ni apa iwo oorun Afrika ati ni ile alawo funfun sugbon o soro lati so pato ibi ti oruko naa ti san wa. Opolopo ojogbon ni o ti so nnkan nipa re.
    Awoniyi (1978) gbagbo wi pe oruko ti awon ajoji kan ronu lati fun awon eya ti o n so ede yii ni ‘aku’ awon miiran tun gbagbo pe awon Hausa ni o pile orukon ti awon eya yii n je loni nitori awon Hausa yii ni o koko n pe okunrin ti won ni ‘Yaribawa” ti won si n pe obinrin ni ‘Yarabanci”. Atotonu miiran ni wi pe lara ede ti won n pe ni ”Kwa” ni ede Yoruba ti jade wa.
Awon ipinle meje ti o n so ede Yoruba yii julo ni orile ede Naijiria ni Eko, Ogun, Oyo, Osun, Ekiti, Ondo ati Kwara. Bakan naa ni awon apa ibi kan ni ipinle Kogi ati Edo. Ni apa iwo oorun Afrika ni ile olominira Benin, Togo, Ghana, Cote d’Ivore, ni won ti n so ede Yoruba. Ni apa iha Guusu Amerika bi (Cuba, Brazil) Haiti Trinidad ni a tun ri awon ti o n so ede yii bakan naa.
ORIKI FUN EKA EDE
    Orisii oriki ni awon ojogbon ti fun eka ede. Eka ede ni ede ti awon eya kan tabi adugbo kan n so ni ile Yoruba. A tun le so wi pe eka ede ni ona ti iro tabi oro kan gba yato si ekeji ile Yoruba. A tun le so pe eka ede ni okan lara ede ajumolo ti awon eya kan ti okun ede Yoruba so papo.
    Iro ki i se bakan naa ni gbogbo ede bee si ni iro ohun yato si omiran. Eyi tumo si wi pe ki oro ni itumo kan naa ki pipe won si yato si ara won.
Fun apeere: ninu ede ajumolo:    
Inu mi dun nigba ti mo ri o.
Ijesa:    Inu mii dun, nigbi mo ri o.
Ondo:     I no mo don, nigi mo ri o.
Egba:    Igba i mo ri o, inu mi dun.
Ijebu:    Inu mii dun, Ki mi ri e.
    Eka ede ni ona ibanisoro ti awon ara adugbo kan fowo si fun ibasepo owo, oro aje,esin,oselu, eto eko abbl. Ti o yato si ti awon ara adugbo miiran ni agbegbe kan naa. A tun le so pe eka ede ni ibanisoro ti awon owo tabi egbe kan n lo ti o yato si ti awon miiran.

 IPINSOWOOWO AWON EKA EDE
    Ipinle Eko:
Awori: awon ilu won n so niwon yii: Egan Oke, Egan Eyin, Osa, Oto, Ikanikin, Obadoore, Idoluwo, Iseri, Ikeja, Musin, Isagira, Etegun, Ojota.
    EKA EDE IJEBU
Ikorodu ati agbegbe re, Epe, Ibeju, Imota, Odo Iragunse, Ilara, akodo abbl.
IPINLE OYO
    Awon ilu ti won n so ede Oyo ni wonyi: Oyo, Ibadan, Fiditi, Jobele, Akinmoorin, Ajaawa, Ogbomoso, Ogbomoso abbl.
EKA EDE ONKO
Awon ilu ti n so ede Onko ni wonyi: Igbeti, Igboho, Saki, Ago Amodu, Aba, Iseyin, Sepenteri Kisi, Tede, Ago Awaye, Out, Okeho, Iganna, Igboora, Owo, Irawo ati Iwere abbl.
IPINLE OSUN
    A ni awon eka ede yii ni ilu won:
EDE IJESA
    Awon ilu ti won n so ede Ijesa ni: Ilesa, Ibokun, Osu, Ipetu Ijesa, Ikeji, Arakeji, Ijebu Ijesa, Idominasi, Imesi Ile, Erinmo, Erin, Iperindo.
EDE OSUN
Awon ti won n so ede Osun ni: Ede, Osogbo, Ogbaagba, Ifon, Ifon Osun, Erin Osin, Iragbiji, Erinpa, Ikirun, Otan abbl.
EKA EDE OYO
Awon eya ti won n so ede Oyo ni Osun ni Ila Orangun Oke Ila.
IPINLE OGUN

  1. EKA EDE EGBA: Abeokuta ati agbegbe re, Waasinmi, Owode, Papa abbl.
  2. EKA EDE YEWA: Ayetoro, Ilaro, Ajilete, Oke-Odan, Igbogila, Imeko, Ijofin, Ibooro, Saala, Ifonyin abbl.
  3. EKA EDE AWORI: Agbara, Igbesa, Ota, Atan, Ijoko.
  4. EKA EDE IJEBU: Ijebu Ode, Ijebu Igbo, Ago Iwoye, Ikene, Isara, Ososa, Ijesa, Ijebu, Ijebu Ife, Abigi, Jobore, Ijebu, Ilese, Ijebu-Musin abbl
  5. EKA EDE OHORI: Ijoun, Tata, Igan Alade, Igan-Okoto abbl.

    EKA EDE ONDO

    1. AKURE: Iju, Ita-Igbolu, Ijare, Oba Ile, Igbatoro, Uso, Ilaramokin, Oda
    2. EDE OWO: Owo, Ipele, Iyere, Isuada Emure, Ipeme, Ikaro, Ifon, Okeluse, Imoru, Ute, abbl
    3. EDE ONDO: Ondo, Ile-Oluji, Idanre, Odigbo, Ore, Ondo Igbedo, Bagbe, Laje, Laamu, Erinla abbl.
    4. EDE IKALE: Iju-odo, Igbotako
    5. EKA EDE ILAJE: Igbokoda, Ugbonla, Ilu-titun, Ode-aye, Okitipupa, Ode Irele, Araromi abbl.

IGBELEWON

  1. ki ni ede ajumolo?
  2. Ki ni eka ede?
  3. Ko iyato merin laarin ede ajumolo ati eka ede.

     

APAPO IGBELEWON
1.    KI ni a n pe ni awe gbolohun?
2.    Iyato wo lo wa laarin olori awe gbolohun ati awe gbolohun afarahe?
3.    Ona meloo ni ale pin gbolohun afarahe pin si, daruko won.
4.    Ona meloo ni awe gbolohun afarahe asaponle pin si, daruko won.
5.    ki ni ede ajumolo?

  1. Ki ni eka ede?
  2. Ko iyato merin laarin ede ajumolo ati eka ede.

 ZT%NY@W) IX!

  1. Ki ni oro ise?
  2. Ko abuda oro ise mefa sile pelu apeeremeji meji.

     

ISE ASETILEWA

  1. ”Mo ri e ni oru ana ni oru ana” je awe gbolohun afarahe ……… (a) asaponle(b) asapejuwe (d) asodoruko (e) alasiko
  2. Iwe ti mo ra ti faya ‘ti mo ra’ je awe gbolohun aafarahe …… (a) asaponle (b) asapejuwe (d) asodoruko (e) alasiko
  3. Apeere awe gbolohun afarahe asodoruko ni (a) yo bi ojo (b) nba wa ka ni e wi fun mi (d) pe mo de dun mo won (e) Ile ti mo ko ga
  4. Nba wa ka ni e wi fun mi ”ka ni e wi fun mi;; je apeere awe gbolohum afarahe… (a) asodoruko (b) onikani (d) asapejuwe (e) alasiko
  5. Olori awe gbolohun ni wonyi AYAFI (a) Ode pa etu (b) Ojo ro (d) ni abule oja (e) Bola ra aso.

APA KEJI

  1. ki ni eka ede?
  2. Ki ni ede ajumolo?
  3. Ko iyato meji laarin olori awe gbolohun ati awe gbolohun afarahe.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *