OSE KEJO
ORO ATI GOLOHUN ONIPONNA
    
Gbolohun oniponna-; ni gbolohun ti o ni ju itumo kan lo.gbolohun oniponna le je eyo oro tabi apola kan ni o maa ni ponna.
Itupale eyo oro oniponna ninu gbolohun.
    Ayo ko le da mi. o tumo si pe
. Ayo ko le da mi [ se eda mi ].
Ayo ko le segun mi.
Isu rira ni Badejo gbin.Tumo si-
isu ti o ti ra[baje] ni Badejo gbin.
Isu ti o ra ni oja ni o gbin.
Ogun ile ni Ariyibi gbonju ba.tumo si pe-;
ile ogun ni Ariyiibi gbonju ba[20],o tun le tumo si
ogun ile ti oloogbe fi sile ni Ariyibi gbonju ba.
Itupale apola oniponna ninu gbolohun.

 Gbolohun                Itumo
Ayo wu mi             Mo feran Ayo
                 Mo fe idunnu
Omo Akin             Omo ti Akin bi.
                 Akinkanju omo.
                 Omo-ise Akin.
Iya aje naa ti de         Iya ti o bi iya aje.
                 Iya ti o je aje gan-an ti de.
Akanlo-Ede Oniponna
Mo buta             Mo jeun
                 Ki a fi owo bu ata si inu nnkan
Oba waja             Oba ilu ku.
                 Oba ilu wo inu orule ile lo.            
Se itupale fun awon gbolohun isale yii            
Eran afoju naa ti jade

 

  • Owo sinkun tite omo ole ifo.
  • Ode aperin da iyepe lu abami eda naa ni oju ese.
  • Baba ru agbe emu merin lo si oja.

     

ORO ONIPONNA
Odi        (i) eni ti ko le soro.    (ii) ogiri ti a mo yi ilu ka.     (ii) odidi padi eyin.
Tinu        (i) oruko eniyan    (ii) nnkan ti o wa ninu.
Nu        (i) ki eniyan pa nnkan re (ii) fun ni ni ounje je     (ii) ki nnkan sonu.

 IGBELEWON
Ko itumo mejimeji fun awon gbolohun/oro yii:

  1. Iya aditi se ogede.
  2. Olu keran.
  3. Ayo ni yoo pa omo naa.
  4. A o ni polowo.
  5. Olu le omo afin lo.

     

IWE ITOKASI
Adewoyin S.Y (2006) Imo, Ede, Asa ati Litireso Ile Eko Sekondiri Agba. (S.S.S.3) Copromutt Publishers 226-229.

 
 
 
 
 
 EEWO
Eewo je ohun ti a ko gbodo se rara, awon Yoruba si gbagbo pe ti a ba se awon nnkan wonyi tabi ti a ba dejaa nnkan buruku le sele.
Eewo ni ohun ti a agba ni ile Yoruba pe eniyan ko gbodo se, bi eniyan ba si dejaa yoo jiya re. A da eewo sile lati le ko awon omode ni iwa imototo, omoluwabi, ibowofagba ati igbe laruge asa wa.
A le pin eewo ile Yoruba si awon isori wonyi:-

  • Eewo ikilo / ikonilogbon
  • Eewo iderubani
  • Eewo ti o je mo eri okan tabi ikora eni ni ijanu
  • Eewo idile
  • Eewo ilu
  • Eewo esin
  • Eewo fun ibagbepo eda

Eewo ikilo: Eyi ni eewo ti a gbe kale lati fi kilo tabi lati fi ko ni logbon. Apeere:
–    Aboyun ko gbodo rin ni osan tabi ni oru ganjo
–    A ko gbodo fi igi owo dana
–    Omode ko gbodo fi owo gbe ojo
Eewo Iderubani: Ni a maa n lo tabi deruba omode. Apeere:
    –    Omode ko gbodo to si aarin aaro ki iya re ma baa ku
–    Omode ko gbodo jokoo si eti odo
–    Omode ko gbodo jokoo si enu ona nigba ti ojo ba n ro
–    A ko gbodo soro nigba ti a ba n jeun.
Eewo ti o je mo eri okan

  • Ode ko gbodo ba iyawo egbe re se nnkan papo
  • Babalawo ko gbodo gba iyawo babalawo lati dekun iwa odale

Eewo esin

  • Obatala ko gbodo mu emu ope
  • Onisango ko gbodo mu siga, je sese
  • A kii fi adi ko esu. Eni ti o ba dejaa yoo ri ija orisa re

Eewo Idile/orile: Eyi ni eewo ti o je mo idile kookan. Apeere

  • Iran onikoyi ko gbodo je eran okete ati eran oore

 Eewo Aisan

  • Eni ti warapa ba n se ko gbodo duro si ibi ti ariwo ba tip o.
  • Eni aromolegun ba n se ko gbodo fo egungun eran ki ara riro re ma baa po sii

Eewo fun Ibagbepo
A kii toju elese mesan-an kaa ki ija ma baa sele.

 
 
 IGBELEWON

  1. Ki ni eewo :

Obatala
Sango
Esu

  1. Ki ni gbolohun oniponna? Fi apeere meta gbe e lese.

     

LITIRESO
Kika iwe apileko ti ijoba yan.

 APAPO IGBELEWON

  1. Ko itumo mejimeji fun awon gbolohun/oro yii:
  2. Iya aditi se ogede.
  3. Olu keran.
  4. Ayo ni yoo pa omo naa.
  5. A o ni polowo.
  6. Olu le omo afin lo.
  7. KO idile merin sile ki o si ko eewo idile kookan.
  8. Ki ni gbolohun oniponna? Fi apeere meta gbe e lese.

 ZT%NY@W) IX!

  1. Ni ilana tabili, ko iyato laarin oro-oruko ati oro aropo oruko mefa sile.

     

ISE ASETILEWA

  1. Oro ….. je oro ti o ba ni ju itumo kan lo. A. aranmo B. atokun C. ise D. oniponna
  2. ” a o je isu lale” oro-pon-na inu iso yii ni A. a B. o C. jesu D. lale.
  3. ”Omo akin” gege bi iso pon-na ni itumo A. eyo kan B. meji C. meta D. merin.
  4. ”Olu jata” tumo sip e Olu …… A. jata B. jeun C. daran D. binu.
  5. Awon idile ti won ki i je eran okete ni A. Eso Ikoyi B. Aresa C. Iremogun D. Onigbeeti.

APA KEJI

  1. Ko itumo awon:
    1. Omo naa ko wulo
    2. Mo pa iro
    3. Eti mi ti kun
    4. Iya aje.
  2. Ko eewo imototo marun-un sile.

     
     
     
     
     

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *