OSE KESAN-AN
Ori-oro-; Aroko oniroyin
Akoonu:
Aroko oniroyin:- je mo iroyin sise tabi itan isle ti o ti koja seyin ti o si se oju eni ti a n royin re ni sise-n-tele ninu aroko oniroyin fun elomiran ti ko si nibe. A rii wi pe o fi ara pe aroko asapejuwe.
Ki a to le se iroyin yori, a gbodo je eni ti o ni ife si gbigbo tabi kika iwe itan kekere.
Eyi ni apeere ori-or, to je mo aroko oniroyin.
Iroyin ipade maje – o – baje kan ti mo lo.
Ayeye odun eyo ni ilu eko
Ojo buruku, esu gbomi mu.
Ipolongo eto idibo ti o koja
Bi mo se lo isinmi mi ti o koja
Isomoloruko kan ti won se ni odede wa laipe yii.
Igbelewon.
Ko aroko lori
Isomoloruko kan ti won se ni adugbo wa laipe yi.
ASA
ORI-ORO-;orisiirisii oruko ti a le so omo ni ile Yoruba
Akoonu
Oruko se Pataki ni ile Yoruba, awon Yoruba kii sii deede fun omo ni oruko, awon oruko Yoruba maa n ni itumo. Idi niyi ti awon agba fi maa n se akiyesi ipo ti omo ba gba waye, Ipo ti ebi wa, esin idile baba ki won to fun omo ni oruko, Yoruba ni ile laawo ki a to so omo ni oruko.
Eyi ni orisii oruko ti a ni ni ile Yoruba.
- Oruko amutorunwa
- ii. Oruko abiku
iii. Oruko Inagije
iv. Oruko abiso
Oruko amutorunwa:- ni oruko ti a fun omo nipa sise akiyesi ona ara ti o gba wa si aye tabi isesi re nigba ti a bii.
Ap
Oruko amutorunwa:-
Ige Omo ti o mu ese waye
Aina Omobinrin ti o gbe ibi korun.
Ojo Omokunrin ti o gbe ibi korun.
Oke Omo ti o di ara re sinu apo ibi wa si aye epo tutu ni won maa
n ta si ara apo naa, ki o to le tu.
Oke Omo ti o maa n daku ti won ba n fun ni ounje ni idubule.
Dada Omo ti irun ori re ta koko.
Ilori Omo ti iya re ko se nnkan osu ti o fi loyun
Oni Omo ti won bi sile to n kigbe laisinmi
Babarinsa Omo ti baba re ku ni kete ti won bii.
Abiona
Oruko abiku: Oruko ti a fun omo ti o maa n ku, ti a sit un pada wa saye.
Won maa n fun won ni oruko bii ebe tabi epe ki won le duro.ap
Oruko Itumo
Durojaye – Ki o duro ni ile aye je igbadun
Rotimi – Duro ti mi, ma se fi mi sile.
Malomo – Duro si aye, ma pada si orun mo
Kosoko – Ko si oko ti a o fi sin oku re mo
Kasimaawoo – Ki a si maa wo boya yoo tun ku tabi ye.
Bamitale – Duro ti mi di ojo ale
Aja – Iwo ko ye ni eni ti a le fun ni oruko eniyan mo afi aja.Oruko Inagije:- oruko atowoda ti a fi eniyan tabi ti eeyan fun ara re lati fi se aponle tabi apejuwe irisi tabi iwa re ap.
Eyinafe: Eni tie yin re funfun ti o si gbafe.
Ajisafe: Eni to feran afe ni owuro ti gbogbo eeyan ba n sise
Peleyeju: Eni to ko ila pele, ti ila oju naa si ye e gan-an.
Oginni: Eni ti o maa n roar n tele ginniginni.Oruko abiso: eyi ni awon oruko ti o n tokasi ipo idile tabi obi omo saaju tabi asiko ti a bii.
Apeere oruko to n tokasi ipo tabi esin idile.Ipo Oruko abiso
Oba – A Adebisi, Adegorite, Adegoroye, Adesoji, Adegbite, Adeyefa.Eleegun Ojewunmi, Ojeniyi, Eegunjo bi
Jagunjagun Akintola, Akinkunmi, Akindele
Onisona Onajide, Olonade
Elesin Ifa Fayemi, Faleye, Awobiyi, Awotunde
Onisango Sangobunmi, Sangodele
Orisa Oko/Idobatala Efunjoke, Opakunle, Soyinka.
Orisa Ogun Ogunyemi, Ogunbiyi, Odetola.
Oruko to n tokasi ipo obi saaju tabi ni akoko ti won bii.
Oruko Itumo
Ekundayo Ibanuje ati ekun ti o wa ninu ebi di ayo.Olabode Ola to ti lo ninu ebi tun ti pada de.
Tokunbo Omo ti won bi si Ilu oyinbo tabi ile okeere ti won gbe wa ile.
Igbelewon
1. Kin ni Oruko?
b. Daruko orisii oruko ti o wa.
IWE AKATILEWA
Imo,Ede ASA Ati Litireso.Adewoyin S.Y o.i 298-301.
ISE ASETILEWA
1.Ojo ——- ni won maa n fun omokunrin ni oruko laye atijo
2.Omo ti a bi ti o mu ese waye ni
(a)Amu-ese-wa (b) Ige (d) Dada
3.——- ni o n bi iku ati arun danu
(a) obi (b) ata (d) abikudanu/
4. Efunyela je oruko ti o je mo orisa ———–
(a) Esu (b) Orisa oko (d) Ogun
5. Omo ti o maa n daku ti won ba n ro o ni ounje ni ibule ni ———
(a) Oke (b) Oke (d) Abiona.
APA KEJI- Daruko orisii oruko marun-un,pelu apeere merinmerin fun ikookan.
Ko aroko lori odun keresimesi ti o koja.