OSE KEWAA
ORI-ORO-;ISORI ORO-ORUKO
AKOONU
– oriki
– orisiirisii oro oruko.
– ise ti oro oruko n se ninu gbolohun.
– lilo oro oruko ninu gbolohun.
Oro –oruko ni awon oro ti won le da duro nipo oluwa,abo tabi eyan ninu gbolohun.AP.
    Baba ko ebe.
    Tolu fo aso.
    Mama se isu ewura.
EYA ORO ORUKO.

  1. ORUKO ENIYAN : -Oro oruko le je oruko eniyan,eyi ni oruko ti o n toka si ohun ti o je eniyan.Ap

    -Rotimi
            – Dele
            -Ahmed
            – Dokita
            – Iyalaje…abbl
    2. ORO-ORUKO ALAISEEYAN: -Eyi ni oruko to n toka si awon nnkan ti kii se eniyan AP.okuta,iwe, ewure,omi,iyanrin,bata abbl.
    3.    Oro-oruko le je ohun elemi : – Eyi je oruko nnkan ti won ni emi bii eniyan tabi eranko.apaja,eniyan,esin,maalu,alangba,okunrin.abbl.
    4.     Oro-oruko le je ohun alailemii: – Eyi ni awon nkan ti ko ni emi.ap iwe,ile,bata,ewe,igi,abbl.
    5.     Oro-oruko le je ohun aridimu : – Eyi ni awon ohun ti a le fi oju ri tabi fi owo kan.apewa,eja,isu,tabili,sokoto,aga,ewedu,abbl.
    6.     Oro-oruko le je oruko ibikan :- Eyi ni awon oro oruko ti a le fi ibo se ibeere won.Ap ibo lo n lo? Osodi,Meka,Soosi.
    7.     Oro-oruko le je ohun afoyemo : – Eyi ni awon ohun ti a ko le fojuri sugbon ti a le mo nip aero opolo.Ap ogbon,ilera,ero,ife,alaafia,igbadun,wahala,imo.
    8.     Oro-oruko le je aseeka : – Eyi ni o n toka si ohun ti a le ka Ap. Ile,ilu,eniyan,iwe,tatapupu.
    9.     Oro-oruko le je alaiseeka : – Eyi ni o n tokasi awon ohun ti koseeka Ap Iyanrin,epo,omi,afefe,gaari,irun.
    10.     Oro-oruko le je oruko igba : – Eyi ni oro ti a le lo lati toka si igba ti nnkan sele han.Ap Aaro,ana,odun,irole,oni,ola,ijeta.
    ISE TI ORO-ORUKO N SE NINU GBOLOHUN.
    Ona meta Pataki ni a le gba lo oro-oruko ninu gbolohun,o le sise:
    i.Oluwa,
    ii. abo
    iii. eyan.
    OLUWA;ni eni tabi ohun ti o se nnkan ninu gbolohun.ap Baba ko ebe.
    Bola fo aso.
    ABO;ni eni tabi ohun ti a se nnkan si,ap
    Mama se obe
    Bolu ko leta.
    EYAN;ni o maa n se afikun itunmo fun oro-orukoap
    Mama se obe eja yiyan.

     
     
     Bola se isu ewura.
    Ona miran ti a tun le gba da oro oruko mo ni pe
    Oro-oruko maa n gba oro aropo bii eyan,ap
    ‘oro yin ni a sese so tan yii.’
    ‘ile re ni mo n lo.’
    Oro-oruko le se e lo fun sise akiyesi alatenumo ti a ba gbe saaju wunren ‘ni’ap
    ‘iwe ni mo ra.’
    Rira ni mo ra iwe yii.

     ASA
    IPOLOWO OJA
    AKOONU
    Ipolowo oja-;je ona ti a n gba lati ke gbajare oja ti a n ta si etigbo awon eniyan lati le ba won ra a.
    Ona meji ni a n gba se ipolowo oja,awon naa ni
    i.ipolowo oja abinibi
    ii. ipolowo oja ode-oni.
    Ipolowo oja abinibi-;je ona ti a n gba polowo oja ni aye atijo,awon naa ni;ipate,ikiri.
    Ipolowo oja ode-oni-; je ona ti a n gba polowo oja ni ode-oni,lati le je ki oja ti a n ta ya,apeere ipolowo oja ti ode-oni ni; ipolowo lori telifisan,redio,iwe iroyin,fidio ati inu magasinni.
        IWULO/PATAKI IPOLOWO OJA
    Gege bi a se mo pe ipolowo ni agunmu owo,opolopo anfaani ni o wa ninu ipolowo oja ti anfaani re ko si se e fi owo ro seyin.
    i. Ipolowo oja maa n je ki oja ta.
    ii. O maa n je ki awon eeyan mo nipa oja titun to sese n jade.
    iii. O maa n je ki ohun ti a fe ra wa ni arowoto wa.
    .iv.O maa n je ki awon eeyan mo ibi ti won ti le ri oja ti won fe ra.
    ORISII OJA TI A N POLOWO
    ONA TI A N GBA SE IPOLOWO
    O fere je pe gbogbo oja ti a ni ni a maa n polowo,eyi ni die lara awon oja ti a maa n polowo.
    OJA                    IPOLOWO
    Efo                     E refo e sebe.
    Gaari                 gaari,olooyo,ayangbe gaari o
    Ata                     E rata e sebe o
    Iresi                 ofe niresi eran lowo
    Epo                     E repo e sebe.
    Iru                     E raru e sebe.
    Orisii ogbon ni awon oloja maa n da lati polowo oja won,ki awon eeyan le ba won ra a,ara awon ogbon naa ni

    1. Itowo-;Eyi ni pe won a fun onibara ni die ninu oja ti won n ta pe ki o to o wo bi o se ri lenu ap gaari.
    2. Isiwo-; Eyi ni pe won a ti ni kekere kan ninu oja yen ti won a maa fi han onibara lati wo o bi o se ri ap eko.
    3. Awin-; Awon oloja maa n ta oja awin fun awon onibarawon lati fi fa oju won mora.

    Orisiirisii ede aponle ni awon oloja maa n lo lati fa oju awon onibara won mora,fun apeere “e woju obe e muyan.
    Igbelewon

    1. Daruko awon oja ti a maa n polowo.
    2. se ipolowo merin ninu won.
    3. Daruko isori oro-oruko marun-un pelu apeere metameta fun ikookan..

    Iwe Akatilewa
    Iwe imodotun Yoruba fun olodun kin-in-ni o.i 93, 98.
    ISE ASETILEWA
    1.———- ni agunmu owo
    (a) itowo (b) ipolowo (d) ikiri
    2. ——- je okan lara ogbon ti awon oloja maa n lolati ta oja won.
    (a) ipate (b) itowo (d) eebu.
    3.Okan lara ona ti a n gba se ipolowo oja lode oni ni
    (a) ikiri (b) itowo (d) redio
    4. Mama se eja tutu. Eyan ti o wa ninu gbolohun yii ni
    (a)mama (b) eja (d) tutu.
    5. Orisii ise ——- ni oro-oruko maa n se ninu gbolohun.
    (a) kan (b) meji (d) meta.
    APA KEJI
    1,Kin ni ipolowo oja?
    b.Daruko orisii oja marun-un ti a maa n polowo,ki o si polowo won.
    2. Salaye ise ti oro-oruko n se ninu gbolohun,pelu apeere metameta fun ikookan.
        

     
     
     

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *