OSE KEJE
Oro – Agbaso
Akoonu
Oro agbaso naa ni a mo si afo agbaran.
Oro agbaso:- je siso oro ti a gbo lenu oloro fun elomiran. Iru oro tabi iroyin bee gbodo je eyi to ti koja. Oro agbaso le je ohun ti enikan so nipa wa tabi elomiran. O si le je iroyin ohun to sele nibi kan. Awon wunren atoka oro agbaso ni so, wi, ni, ki, pase, wi pe, salaye, so fun abbl
Tunde ni oun ko ni wa si ipade
Sola beere boya a ti jeun
Bi a ba n se agbaso, ayipada maa n de ba oro aropo oruko tabi oro aropo afarajoruko, ti eni to n soro ba lo oro aropo-oruko tabi oro aropo-afarajoruko enikinni ninu oro re – oro aropo –oruko tabi afarajoruko eniketa ni eni to n se agbaso yoo lo. Apeere:
Mo ri owo he.
Agbaso-     O ni oun ri owo he.
A ko mo won ri
Won ni awon ko mo won ri
Mo fo aso
O ni oun fo aso
Atunse maa n sele si oro-oruko
ap
Afo asafo: Eyi ni ki o ra.
O pase pe iyen ni ki o ra.

 IGBELEWON

  1. Se agbaran awon afo asafo wonyi:
    1. Oye: Seun, se o ti jeun?
    2. Obasa: Banjo, bawo ni o se rin lanna?
    3. Folake: Suberu fe gbe ise fun mi.
  2. Se afo asafo awon afo agbaran wonyi:
    1. Tunde ni oun fe mo idi ti n ko fi wa.
    2. Basiru so pe omo naa ki i wa deede.

IWE ITOKASI
Adewoyin S.Y (2006) Imo, Ede, Asa ati Litireso Ile Eko Sekondiri Agba. (S.S.S.3)
Copromutt Publishers Oju Iwe 231-233.

 AROKO PIPA
Aroko je ona ti awon baba-nla wa fi n ba ara won soro laye atijo. Ami ni won fi maa n ranse si eni ti ko si ni tosi. A le fi aroko aye atijo we leta kiko lode oni.

 ORISII AROKO AYE ATIJO
Aale: ni ami ti a maa n le lori eru tabi eso. A maa n fi ni kilo fun eniyan pe nnkan ti a ta mo ti ni oluwa ki enikeni ma di ibe.
Aaga: aaga ni ami ti a ta mo ara igi meji ti a ri mole lati fi kilo fun eniyan lati sa fun ewu.
Itufu: ni awon nnkan ti o le mu ina wa, ti a gbe seyinkule eniyan lati fi kilo fun iru eni bee pe ki o jawo kuro ninu iwa ika. Bi bee ko won n bow a jo ile re.
Asewelewe: jija ewe tutu sile ni ikorita bi ami ni lati fi so fun awon ti won dijo n lo si ibi kan pea won ti koja siwaju.

 AMI IPAROKO NI AYE ATIJO
AMI        ITUMO

  1. Owo-eyo        eni naa ti di eni itanu.
  2. Ikarahun igbin    ife nini. Okan re n fa mi.
  3. Iye            wa kiakia. Ija ti pari. O ti fo lo bi eye.
  4. Iye ayekooto    sora lati so otito.
  5. Aidan        wa san gbese re ni kiakia.
  6. Ajoku owu    iku tabi ewu wa nitosi.
  7. Awo Ehoro    sa jinna rere. Ewu wa nitosi.
  8. Awo oju ilu    oro ti kuro ni asiri. Gbogbo aye ti mo.
  9. Awe Obi        oro ti yanju.
  10. Esun Isu        dawo ohun ti fe se yen duro.
  11. Esuru        oro naa ko gbudo su o.
  12. Kain-kain, osun    iyawo ti bi omo tuntun
  13. Obi         gbo tie.

IGBELEWON
Ki ni itumo awon nnkan woyin ti a ba fi ranse si ni:

  1. ooya
    1. eja
    2. akan
    3. obi

 IWE ITOKASI
Adewoyin S.Y (2006) Imo, Ede, Asa ati Litireso Ile Eko Sekondiri Agba. (S.S.S.3) Copromutt Publishers 76-82.
LITIRESO

 
 ZT%NY@W) IX!

  1. Ki ni oro aropo oruko eni kin-in-ni mesan-an sile.
    1. Ko apeere oro oruko eni keji sile.
  2. Ko apeere oro oruko eni keta mesan-an sile.

 ISE ASETILEWA

  1. ”Yemi: mo ti yo bamubamu”. Afo agbaran gbolohun yii ni A. o ti yo bamubamu B. mo ti yo bamubamu C. oun ti yo bambamu D. o ti yo bamubamu.
  2. ” mo n lo” afo agbaran gbolohun yii je A. o n lo B. o ni mo lo C. o ni oun lo D. o ti n lo.
  3. Tinu so pe oun feran iresi pelu eja tutu. Ki ni afo asafo gbolohun yii? A. mo feran iresi eleja tutu B. o ni mo feran iresi ati eja tutu C. o ni oun feran iresi ati eja tutu D. o feran iresi pelu eja tutu.
  4. Yemi ni awon ti pon omi. Ki ni afo asafo gbolohun yii? A. e ti ponmi sile B. a ti ponmi sile C. emi ti ponmi sile D. Yemi ni a ti ponmi sile.
  5. Ti won ba fi obi ranse si eniyan itumo re ni A. ki iku o bi lori eniyan B. ki eniyan maa tete bo C. ife ti pari D. ki eniyan gbo tie.

    APA KEJI

  6. Ki ni afo asafo?
  7. Ki ni afo agbaran?
  8. Se alaye: kain-kain, esuru, awo oju ilu.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *