OSE KEFA
ARANMO
Aranmo ni agbara ti iro kan ni lori miiran eyi ti o le f ape ki iro mejeeji yipada di iru kan naa tabi ki won fi abuda jo ara. Apeere:
Ara ile —-à araale
Omo ise —à omoose.
Oni owo –à olowo.
Iro Afaramo: iro afaranmo ni iro ti o ni agbara lati yi abuda iro tabi die lara abuda iro miiran pada si tire. Apeere:
Owo ile —-à owoole.
Ise ilu —–à iseelu.
Iro Agbaranmo: iro agbaranmo ni iro ti o yi pada gba abuda iro miiran. Apeere.
Ile iwe —-à ileewe
Ara ile —-à araale.
ORISII ARANMO
- ARANMO IWAJU
Iro Afaranmo Iro Agbaranmo Aranmo Iwaju
Ile ise ileese
Ku irole kuurole
- ARANMO EYIN
Iro Agbaranmo Iro Afaranmo Aranmo Eyin
Ara orun aroorun
Ku ale kale
- ARANMO ALAIFORO
Ojo iku ojooku
Ile ise ileese
Ara orun aroorun.
- ARANMMO AFORO
Oni epo -àelepo
Oni owo -àolowo
Oni eran -àeleran.
- ARANNMO KIKUN
Agbo + ile -àagboole
Oku + igbe -àokuugbe
Ile + ise -àileese.
IGBELEWON
Sakaye awon wonyi ki o si fi apeere mejimeji gbe alaye re lese: Aranmo: i. Iwaju, ii. Eyin. iii. Aforo . iv. alaiforo. v. kikun. vi. iro agbaranmo ati iro vii. afaranmo.
IWE ITOKASI
Adewoyin S.Y (2006) Imo, Ede, Asa ati Litireso Ile Eko Sekondiri Agba. (S.S.S.3)
Copromutt Publishers Oju Iwe 119-124.
ETO IDAJO LODE ONI
Yoruba bo won ni ibi ti ko si ofin ese ko si nibe. Itapa si ofin ni o n je oran dida. Aye ki ba ti ma roju bi ki i ba se ofin ti o de eniyan. Gbogbo ofin ni o n sise alaafia, idaabobo fun gbogbo eniyan. Ti eniyan ba tapa si ofin tan, ohun ti o kan ni idajo.
Ejo Dida/ Eto Idajo ki i se ohun ajeji nile Yoruba, o ti wa laarin awon agba aye atijio.
Awon ti o maa n se idajo ni aye atijo ni baba, iya, olori ebi aale ati Oba. Oba je olori eni ti o n se idajo. Ohun ti o ba so ni abe n ge. Sugbon ki o to di wi pe o soro ni gbogbo awon oloye yoo ti se idajo ki oba to pase.
Ni ode-oni, awon adajo ni won maa n da ejo. Ko si eni ti won ko le da ni ejo.
Awon agbejoro naa wa ninu eto idajo lode-oni. Awon mejeeji ni won maa n se iwadii finnifinni ki won to da eniyan lejo ki won ma lo gbe ebi fun alare. Ile ejo ni won ti maa n da ejo. Orisiirisii ile ejo ni o w anile Yoruba awon naa ni:
Ile ejo ibile.
Ile ejo giga.
Ile ejo Kotemilorun.
Ile Ejo ti o ga julo.
IPA TI OLOPAA ATI WODA N KO NINU IDAJO ODE ONI
Awon olopaa ati awon woda je agbofinro. Awon ni won maa je ki ofin ti ijoba se di mimuse. Won maa n ri wi pe gbogbo eniyan ni o gbodo tele ofin. Bakan naa won tun maa n se idanileko ati isininiye lori ofin ti ijoba ba gba jade lati le ki awon eniyan mo pe ofin wa anfaani ara ilu. Won leto lati fa odaran (iyen eni ti ko rufin ti ko tele ofin) lo si ile ejo ki adajo si so ijiya ti o to fun eni naa.
ISE AGBEJORO NINU IDAJO
Agbejoro maa n je akosemose. Awon ni won maa n se iwadii finnifinni lori oran. Ti won ba mu odaran pe o rufin ni ile ejo, awon agbejoro ni won maa n gbenu odaran soro. Won gbodo se iwadii ti o to lori ejo ti won n sise le lori.
ETO YIYANJU AAWO LORI REDIO ATI TELIFISAN
Opolopo eto ni o wopo lode oni ti o maa n da lori yiyanju aawo laarin awon eniyan. Eyi je ohun igbalode ti ko sele ni aye atijo. Opolopo igba ti awon awon ba jaye familete ki ntuto, awon kan n fi owo ola gbaniloju ti iru eni ti won n fi owo ola gba loju yi ko ni eni Kankan ni iru awon eniyan yii maa n ke gbejeri lo si ori redio tabi telifisan lati ri iran lowo. Ki a ma paro iru awon eniyan bayi maa n ri iran-lowo daadaa.
IGBELEWON
- Salaye lori: i. Agbejoro ati adajo ii. Ile ejo kotemilorun iii. Ile ejo ibile.
IWE ITOKASI
LITIRESO
KIKA IWE APILEKO TI IJOBA YAN.
APAPO IGBELEWON
- Sakaye awon wonyi ki o si fi apeere mejimeji gbe alaye re lese: Aranmo: i. Iwaju, ii. Eyin. iii. Aforo . iv. alaiforo. v. kikun. vi. iro agbaranmo ati iro vii. afaranmo.
Salaye lori: i. Agbejoro ati adajo ii. Ile ejo kotemilorun iii. Ile ejo ibile.
ZT%NY@W) IX!
- Ki ni oro aropo oruko?
- Ko apeere oro aropo oruko mejo sile.
- Ko apeere oro oruko opo mesan-an sile.
- Ko apeere oro oruko eyo mesan-an sile.
ISE ASETILEWA
- Aranmo ni …………..A.iro ti o yi pada di iro B. Iro ti o yi pada di iro miira C. agbara ti iro kan ni lati yi abuda iro miiran di ara re. D. iro ti o maa n parade.
- Iro agbaranmo ninu ” ara oko” ni ….. A. a. B. o. C. k. D. r.
- Iro ti yi abuda iro miiran pada di ara re ni ……… A. afaranmo B. agbaranmo C. aranmo iwaju D. aranmo eyin.
- Ewo ninu awon wonyi ni aranmo aforo? A. araale B. kale C. akaa D. eleran.
- Awon ti maa n da eniyan lejo ni ……….. A. olopaa B. woda C. adajo D. agbejoro.
APA KEJI
- Ko apeere mejimeji fun aranmo: i. Iwaju ii. Eyin iii. Aforo iv. kikun.
- Salaye lori: i. Eto idajo aye atijo ii. Eto idajo ode oni iii. Ile ejo ti o ga julo.