SECOND TERM E-NOTE
SUBJECT; YORUBA. CLASS-; SS1
ILANA ISE OSOOSE FUN SAA KEJI
Ose kinni- Ede-Atunyewo awon isori oro
- oro aropo oruko
- oro aropo afarajoruko
- oro atokun
- oro asopo
- oro-ise
Asa- Oge sise
Litireso-Itupale asayan iwe litireso
Ose keji Ede- Awon isori gbolohun gege bi ihun won.
Asa- Oge sise
Aso wiwo laarin okunrin ati obinrin
Awon ayipada ti o de ba aso wiwo aye atijo ati ode-oni.
Litireso- Itupale asayan iwe litireso.
Ose keta Ede- Awon isori gbolohun gege bi ise won.
Asa- Asa ila kiko
– pataki ati iwulo ila.
Litireso- Itupale asayan iwe litireso.
Ose kerin Ede- Aroko Asapejuwe;ilana kiko aroko
– Awon ori-oro to je mo aroko asapejuwe.
Asa- Asa Igbeyawo Ni Ile Yoruba.
- Awon igbese igbeyawo abinibi
- Awon ohun elo idana.
Litireso – Itupale asayan iwe litireso.
Ose karun-un Ede- Aayan Ogbufo; ilana sise aayan ogbufo.
Asa – Orisii igbeyawo ti o wa
- igbeyawo nisu loka
gbigbe ese le iyawo
ana sise ni ile Yoruba.
Litireso- Itupale asayan iwe litireso.
Ose kefa Ede – Aayan Ogbufo; sise ogbufo ayoka ede Geesi si ede Yoruba.
Asa – Igbeyawo ode-oni-soosi, Yigi,Kootu.
- iyato ati ijora ti o wa ninu igbeyawo ode-oni ati atijo.
Litireso- itan olorogeere gege bi orisun itan isedale ati asa Yoruba
-itan isedale Yoruba
– itan awon eya Yoruba
ose keje- Ede- Onka Yoruba;onkaye lati ori ookan titi de Egbaa (1- 2000)
Asa- Oyun nini,itoju oyun,ibimo.
Igbagbo Yorubanipa agan,omo bibi ati abiku
Aajo lati tete ni oyun.
Eewo ati Oro idile.
Litireso – Itan oloro geere gege bi orisun itan ati asa Yoruba; Asa bi Yoruba se n sin oku sinu ile.
Ose kejo- Ede- Atunyewo eko lori eka ede Yoruba; Ijesa, Ekiti,Oyo.abbl.
- iwulo Yoruba Ajumolo
Fifi eka ede we Yoruba ajumolo
Asa- Isomoloruko Ni Ile Yoruba
- Pataki siso omo loruko
- Ohun elo ati isomoloruko.
Litireso-Itupale asayan iwe litireso.
Ose kesan-an
EDE-Aroko asotan/ oniroyin.
Orisii ori-oro ti o je mo aroko oniroyin
Asa- Orisii oruko ti a le so omo - oruko amutorunwa
- abiso abbl
Litireso alohun oloro wuuru; Aalo orisirisi- apamo, apagbe,
iwulo aalo
awon ona ede ti o wa ninu aalo.
Ose kewaa- Ede- Isori oro-oruko
Oriki
Orisii
Ise ti oro-oruko n se ninu gbolohun.
Asa- Ipolowo oja; Iwulo ati pataki ipolowo oja.
Orisiirisii ona ipolowo oja ti abinibi-ikiri, ipate,ipolowo pelu ohun enu.
Litireso – Ewi alohun gege bi orisun itan isedale ati asa Yoruba; oriki orile,ijala abbl
Ose kokanla- Agbeyewo ise saa keji lapapo..
Ose kejila- Idanwo saa keji.
OSE KINNI
ORI-ORO-;ATUNYEWO AWON ISORI ORO
-Oro-oruko
ORO AROPO ORUKO.
- Oriki
- Abuda oro aropo oruko
- Ate oro aropo oruko
- Irisi oro aropo oruko.
AKOONU
Oro aropo oruko ni a maa n lo dipo oro-oruko ninu apola oruko.apeere
‘Bolu je akara.
‘O je e.’
‘ewure je agbado Bola’
‘ewure je agbado re.
Abuda oro aropo oruko.
1. Oro aropo oruko ni eto to n toka si iye bi eyo tabi opo.apeere
O lo [ eyo ni o ]
Won wa [ opo ni won]
- oro aropo oruko ni eto to n toka si eni.apeere.
enikinni /eyi ni eni ti o n soro.
Enikeji / eyi ni eni ti a n soro sii.
Eniketa / eyi ni eni tabi ohun ti a n soro re.
Mo ko leta.
O ko leta
O ko leta.
3. Oro aropo oruko ni eto ipin si ipo.
IYE Eyo opo
Enikin-in-ni mo a
Enikeji o e
Eniketa o won.4. A ko le fi oro-asopo so oro aropo oruko meji papo.apeere
mo ati o
wa ati won.5. A ko le lo oro aropo oruko pelu da ati nko,ni,ko.apeere
mo n ko?
E da?
O ko?
6. A ko le lo eyan pelu oro aropo oruko.apeere
mo naa
e gan-an
IRISI ORO AROPO – ORUKO.
Ona meta Pataki ni a le gba lo oro aropo oruko ninu gbolohun.
- O le sise oluwa
- Abo
- Eyan ninu gbolohun.
Ipo oluwa; – oro aropo oruko maa n sise oluwa ninu gbolohun,
IYE EYO OPO.
Enikin-ni mo a
Enikeji o e
Eniketa o won
Apeere;- mo n jo
O n jo
Won n jo
E n jo
A n jo.
Ipo abo : – oro aropo oruko maa n sise abo bakan naa ninu gbolohun.Iye Eyo Opo.
Enikin-in mi wa
Enikeji o/e yin
Eniketa faweli won
Oro-ise gunBaba na mi.
Bolu n pe o/e
Oluko pe e.
Oba ri wa.
Ipo eyan : -oro aropo oruko maa n ni ipo eyan ninu gbolohun.IYE EYO OPO.
Enikin-ni mi wa
Enikeji re/e yin
Eniketa re/e won.
Apeere; –
Aja mi
Aja re
Aja re
Ile wa
Aso yin
Aja won.
IGBELEWON.
- Kin ni oro aropo oruko?
- salaye awon oro aropo oruko pelu apeere.
ORO AROPO AFARAJORUKO.
- Oriki
- Abuda oro aropo afarajoruko
- Irisi oro aropo afarajoruko.
- AKOONU : –
Oro aropo-afarajoruko ni isesi to farajo ti oro-oruko sugbon o mu eto iye ati eni lara abuda oro aropo oruko.Awon oro aropo afarajoruko ni wonyii; – emi,iwo,oun,awa,eyin,awon.fun apeere.
Emi ko ri Bola.
Ile awa dun.
Abuda oro aropo afarajoruko.
i. Oro aropo afarajoruko ni eto iye ati eni.
Ate oro aropo afarajoruko.IYE EYO OPO.
Enikin-ni emi awa
Enikeji iwo eyin
Eniketa oun awon.
Fun apeere : – iwo ni won ran
Awa naa n bo.
ii. A le lo oro asopo lati so oro aropo afarajoruko meji papo.apeere.
emi ati iwo.
Awa ati eyin.
iii. Oro aropo afarajoruko le jeyo pelu awon wunren bii da,nko,ko.Fun apeere
iwo n ko?
Oun da?
Eyin ko.
iv. Silebu meji ni oro aropo afarajoruko maa n ni.apeere.
emi – e /mi.
iwo – I /wo.
v. Oro aropo afarajoruko le gba eyan.Apeere
emi naa wa.
Awon gan-an wa.
- A le gbe oro –aropo afarajoruko saaju wunren akiyesi alatenumo ‘ni’ fun apeere
- Eyin ni oga n pe.
- emi ni mo ra iwe naa.
IRISI ORO AROPO AFARAJORUKO.
Ise oluwa ni oro aropo afarajoruko maa n se ninu gbolohun.ap.
Emi naa mu osan.
Oun ni won n bawi.
LITIRESO.
Kika iwe litireso.ORO APONLE
AKOONU
Oro-aponle je oro ti o maa n pon oro-ise ninu gbolohun, o ma n se afikun itumo fun apola-ise, ti yoo si je ki itumo re si tubo ye ni yekeyeke.Tobi jeun die
Bolu n rin kanmokanmo boNinu apola-ise ni oro-aponle ti maa n jeyo ninu gbolohun
Oro-ise ni oro-aponle maa n pon ninu gbolohun oro-aponle maa n se afikun ituom fun oro-ise.
Tade dide fuu
Igi naa ga fiofioIrufe oro-aponle inu ede Yoruba orisii meji ni oro-aponle, awon naa ni:-
Awon oro-aponle aiseda
Awon oro-aponle aseda
Oro aponle aiseda ni oro-aponle ti a ko seda, iru oro yii kii ni ju silebu kan tabi meji lo. A won ni fio, kia, gan-an loganO lo logan
Ile naa ga fio2. Oro-aponle aseda:- ni oro-aponle ti a seda lati ara oro-aponle, nipa sise apetunpe oro-aponle ponbele
Kia + Kia = Kiakia
Wadu + Wadu = waduwadu
Pele + pele = peleple
Jan + jan = Janjan
Kele + kele = kelekeleTobi n laagun yoboyobo
Mo n laagun yobo
Aso naa funfun gboo
Obe naa ti tan yanyan
Osupa mole rokosoORO-ISE
- Oriki
- Iwulo oro ise
- Ona ti a le gba lati da oro ise mo.
- Isori oro ise.
AKOONU : –
Oro-ise ni oro ti o ba le duro bii koko fonran ninu gbolohunoro-ise ni oro ti o n toka si ohun ti oluwa se ninu gbolohun laisi oro ise ninu gbolohun ko le ni itunmo nitori ohun ni o je opomulero fun gbolohun.Ap.
Baba ra bata.
Olu fo aso.
Bi a ba yo oro-ise kuro ninu awon gbolohun wonyii ko le ni itunmo.
ONA TI A FI LE DA ORO-ISE MO.
- Oro-ise ni o maa n jeyo leyin oluwa.ap ‘mo je eba.’ ‘won gba owo’.
- oro ti o ba le tele erun oro-ise ‘n’ gbodo je oro-ise.ap ‘Ade n ko iwe’ ‘ mama n se obe.’
- oro ti o ba jeyo leyin yoo,maa,fi ati ti gbodo je oro-ise.Ap ‘Akekoo yoo se idanwo’ ‘oluko maa wa.’ ‘baba ti de’.
- oro ti o ba tele atoka iyisodi ‘ko/o gbodo je oro-ise.Ap ‘ Bayo ko ra aso.’ ‘ oluko ko je eba’.
ISORI ORO ISE.
Orisiirisii isori ni awon onimo girama pin oro ise si ninu ede Yoruba. - Oro –ise Agbabo : – ni oro-ise ti a maa n lo abo pelu re ninu ede Yoruba.ap ‘Tolu sun’ Tope kuru.’ ‘ ojo ro’.
- Oro ise asebeere : – meji naa ni o wa ninu ede Yoruba,awon naa ni da ati nko.fun apeere ‘ mama da’ ‘Bisi nko’.
- Oro ise asokunfa : – Eyi ni oro –ise ti o maa n se okunfa isele,awon oro-ise asokunfa ni;so,mu,se,ko,fi,da. Apeere Bola da erin pa mi. Bade fi iya je Sola. O se iku pa aja re.
- Oro-ise Elela: – Eyi ni oro-ise ti a le fi oro-oruko ti o duro fun abo bo laarin ninu gbolohun.apeere bawi,reje,pada,danu. ‘ mama ba omo wi’ ‘ Bola re mi je’ ‘ Baba da isu nu.
- Oro ise akanmoruko : – Eyi ni a seda lati ara apapo oro-ise ati oro-oruko.Apeere ‘Tope muti yo [mu oti] ‘mama gunyan je [gun iyan] ‘ Abiola lawo pupo [la owo].
- Oro-ise Asapejuwe : – ni oro-ise ti a maa n lo lati so irisi nnkan.Apeere ‘Bisi pupa foo’ ‘Eyin Tolu funfun’ ‘ Tope ga’.
- Oro ise Asoluwadabo : – ni oro-ise ti oluwa ati abo le gbapo ara won.Eyi nip e a le si oluwa ati abo ni ipo pada laisi iyato ninu gbolohun naa.Apeere- ‘ Ojo n se were,were n se Ojo’ ‘ mo ti ju’ ‘oju ti mi’ ‘ mo jaya,aya mi ja’.
- Oro-ise Alapepada: – ni oro ise ti a maa n se apetunpe fun ninu gbolohun.Apeere ‘ iwo ni o ku mi ku’ ‘ E row a ro ire’ ‘Aye ko feni foro’ ‘ ma da mi da wahala’.
- Oro-ise Asinpo : – ni oro-ise ti o maa n je meji tabi meta ninu gbolohun pelu oluwa kan.iye oro ise ti o wa ninu gbolohun yii ni iye gbolohun ti a le ri fayo.fun apeere, ‘Ola sun isu ta.-Ola sun isu. – Ola ta isu. ‘Tope ji eran je’. – Tope je eran. – Tope ji eran.
Bolu sare lo gbe aga wa.
- Bolu sare
- Bolu lo
- Bolu gbe aga
- Bolu wa.
Ori – oro: Isori oro: Oro-asopoi. Oriki
ii. Orisii wunren oro-asopo
iii. Ise ti won n se ninu gbolohunAKOONU
Oro-asopo ni awon wunren ti a n lo lati so awon oro tabi gbolohun bii meji tabi ju bee lo po di gbolohun kan.Apeere
- Ade feran iresi
- Tomi feran iresi
- Ade ati Tomi feran iresi
- Ile re tobi
- Iyara re kere
Ile re tobi sugbon iyara re kere. Awon wunren oro-asopo inu ede Yoruba ni ati pelu, oun afi sugbon nigba ti, ayafi, abi, amo, bee ni, yala, tabi anbosi bosi abbl
Ise ti won n se ninu gbolohun ise oro-asopo ni fun siso oro tabi gbolohun papo.
1. ‘ati’, pelu ati oun ni a fi n so
(a) oro-oruko, meji po ninu oroapeere:
Tolu ati Oye lo si ilu oba
Tunde Pelu Toyin lo si Ikorodu
Ola oun Bayo jo n kawe(b) A le fi so oro-aropo afarajoruko meji po ninu iso
apeeere
Iwo ati oun ni oloro
Awon pelu eyin kii se egbe(d) A le fi ‘ati’, pelu so oro-oruko ati oro aropo afarajoruko po
apeere:
Iwo ati Deinde ni mo ri
Emi pelu Rotimi n ka iwe iroyin(e) Sugbon, tabi, amo. A n lo awon oro wonyi lati so gbolohun meji po ti abayori re yoo je gbolohun olopo oro ise alakanpo.
Apeere:
Bola pe mi sugbon n ko dahun.
Mama ni owo amo won o ra aso.Isori oro:- Oro-atokun
Wunren oro-atokun
- Ise ti won n se ninu gbolohun
- Ibi ti won ti n jeyo
AKOONU
Oro – atokun ni oro ti a n lo lati so iha ti oro-oruko meji kosi ara won. Awon wunren atokun inu ede Yoruba ni: si, ti, ni. Oro-atokun maa n jeyo saaju oro-oruko ninu gbolohun.Apeere:
Ade ti Ikeja lo si Oyingbo ni ana
Ise ti oro-atokun maa n seNinu ihun gbolohun, oro-atokun maa n toka
I. Ibi ti eniyan tabi nnkan n lo. Oro atoka re ni – si
Apeere:
Mo lo si Ibadan
Oduduwa tedo si Ile Ife
II O maa n fi ibi ti eeyan tabi nnkan ti n bo han. ‘ti’ ni wunren reApeere:
Dele ti Akure de lanaa
Eru ti ori aja ja luleIII. Oro_atokun maa n se afihan ibi ti eeyan tabi nnkan wa. ‘ni’ ni atoka re.
Apeere:
Talabi wa ni Ikeja
Olu wa ni Eko
Mama wa ni ile Hausa
ORO APEJUWE
Oro-apejuwe-; ni oro ti o maa n yan oro-oruko ninu gbolohun.A n lo oro-apejuwe lati se alaye yekeyeke ohun ti a n soro ba ninu iso.
Ap.
Omo pupa ni Bunmi.
Esin funfun ni baba ra.
Oti lile ko dara.
Iwa rere ni eso eniyan.
Iro konsonanti lo maa n bere oro apejuwe.
ap
Omo kekere ni mo je.
Inu apola oruko ni oro –apejuwe maa n wa.
ap
Irin rederede ko ye omoluabi.Orisii oro-apejuwe
Oro-apejuwe ipile-;eyi ni awon oro bii rere,kekere,nla.
Oro-apejuwe iseda-; eyi ni awon wunren oro-apejuwe ti a seda nipa sise apetunpe elebe.
Ap
Mu -mimu
ro -riro
bo -bibo
oro apejuwe ti a seda nipa apetunpe
ap
nla- ile nlanla ni won fun wa.
Igbelewon
Tokasi oro apejuwe ti o wa ninu gbolohun yii
Sile mefamefa ni oluko fun wa.
Omo giga ni Bola.
Oruko rere san ju wura oun fadaka lo.
Igbelewon
1. Kin ni oge sise?
- Daruko awon ona ti a n gba se oge ni aye atijo.
kin ni oro-ise?
Salaye isori oro-oruko meta pelu apeere metameta fun ikookan.
IWE AKATILEWA
Imo, ede, asa ati litireso fun ile-eko sekondiri agba i.o. 163
– Eko ede Yoruba titun i. o.105
-ISE ASETILEWA1. ___________oro-aponle maa n pon ninu gbolohun
(a) Oro-Oruko (b) Oro ise (d) Eyan2. Inu ____________ni a ti maa n ba oro-aponle pade
(a) Apola-aponle (b) apola-oruko (d) Apola ise3. ‘lau je je apeere oro-aponle ______________
(a) aseda (b) alaiseda (d)
4. . Atoka oro asopo ti a le fi so gbolohun meta po di eyo kan ni
(a) ati (b) yala…..tabi (d) amo5. Iwo oun Deinde kii segbe. Oro asopo inu iso yii ni
(a) iwo (b) oun (d) segbe
Apa keji - Salaye awon isori oro wonyi pelu apeere metameta fun ikookan
- oro-ise
- oro-atokun
- oro-asopo