OSE KEJE
GBOLOHUN ONIPONNA
ITUPALE GBOLOHUN ONIPONNA.
- Oriki
- Ibi ti o ti n jeyo.
- Apeere/itupale oro-oniponna ninu gbolohun.
AKOONU : –
Gbolohun oniponna-; ni gbolohun ti o ni ju itumo kan lo.gbolohun oniponna le je eyo oro tabi apola kan ni o maa ni ponna.
Itupale eyo oro oniponna ninu gbolohun.
Ayo ko le da mi. o tumo si pe
. Ayo ko le da mi [ se eda mi ].
Ayo ko le segun mi.
Isu rira ni Badejo gbin.Tumo si-
isu ti o ti ra[baje] ni Badejo gbin.
Isu ti o ra ni oja ni o gbin.
Ogun ile ni Ariyibi gbonju ba.tumo si pe-;
ile ogun ni Ariyiibi gbonju ba[20],o tun le tumo si
ogun ile ti oloogbe fi sile ni Ariyibi gbonju ba.
Itupale apola oniponna ninu gbolohun.
Gbolohun Itumo
Ayo wu mi Mo feran Ayo
Mo fe idunnu
Omo Akin Omo ti Akin bi.
Akinkanju omo.
Omo-ise Akin.
Iya aje naa ti de Iya ti o bi iya aje.
Iya ti o je aje gan-an ti de.
Akanlo-ede oniponna
Mo buta Mo jeun
Ki a fi owo bu ata si inu nnkan
Oba waja Oba ilu ku.
Oba ilu wo inu orule ile lo.
IGBELEWON
Se itupale fun awon gbolohun isale yii
Eran afoju naa ti jade
- Owo sinkun tite omo ole ifo.
- Ode aperin da iyepe lu abami eda naa ni oju ese.
- Baba ru agbe emu merin lo si oja.
IWE ITOKASI:
Adewoyin S.Y (2014) IMO, EDE, ASA ATI LITIRESO YORUBA fun ile eko girama agba S.S.1 Corpromutt Publisher Nig Ltd. O.I 226-230.
ASA
ONA TI A N GBA GBA GBESE NI AYE ATIJO
AKOONU: –
Eyi ni orisiirisii ona ti awon Yoruba n gba lati gba owo ti ajegbese je pada lowo re leyin ti akoko to da ti koja.Awon ona naa niwonyii
- sisingbese
- didogo ti ajegbese ati fifooro emi re titi yoo fi ri owo ti o ya san.
- Riran elemun-un
- Gbigbe edan lo sile ajegbese
- Ifibiya.
SISINGBESE : – Eyi nipe olowo ti ajegbese je lowo yoo funra re to onigbese lo tabi ran elomiran si I lati ran-an leti pee to ni ki o wa.
IDOGOTI : – Eyi ni diduro ti ajegbese ati fifooro emi re titi ti yoo fi ri owo san.Bi o fe jeun,won a gbe ounje niwaju re,bi o fe to tabi yagbe yoo telee lo sibe bayii ni won yoo se maa yo o lenu titi ti yoo fi wa owo won san.
RIRAN ELEMU-UN : – Ti gbese ti ajegbese je ba ti pe ti o si je eyi ti a n ta ewure tabi agbo le ka,olowo yoo seto ki gende kunrin kan ki o ba oun mu ohun osin ni agboole ajegbese tita ni ohun osin naa yoo da lati fi ri owo ropo gbese ti ajegbese je sugbon ki I se dandan ki o je ohun osin.
Elemu-un ni a n pe gende kunrin ti olowo ran nise yii.
GBIGBE EDAN LO SILE AJEGBESE: – Laye atijo eru jeje ni awon egbe ogboni je fun awon ara ilu nitori naa ti olowo ba loo fi ejo ajegbese to taku sun awon ogboni,awon ogboni yoo fi edan[amin ase ogboni]ran onise si ajegbese naa,itunmo eyi nip e ki ajegbese naa o maa bo wa si ile ogboni won a da si oro gbese naa,won a si pase fun ajegbese naa ki o san owo yii eru won nii mu ajegbese wa ona kiakia lati san gbese.
IFIBIYA : – Olowo yoo ra oja lowo ajegbese tabi lowo ebi re ti o to iye owo ti o je e, yoo si so fun eni ti o ra oja naa lowo re pe ki o lo gba owo lowo ajegbese oun.
IGBELEWON : –
- Kin ni gbolohun oniponna?
- Daruko awon ona ti a n gba lati gba gbese ni aye atijo.
APAPO IGBELEWON : –
- (a) Kin ni gbolohun oniponna?
(b) ko apeere gbolohun oniponna marun-un sile
2. Daruko awon ona ti a n gba lati gba gbese ni aye atijo
LITIRESO
EWI ALOHUN GEGE BI ORISUN AGBARA ATI IMO IJINLE YORUBA
– OFO
– OGEDE
– ITAN RIRO
AKOONU
Ewi alohun je orisun fun ofo ati ogede nitori pe ohun enu ni a fi gbe awon ewi yii jade.
Oro ni ofo,apa kan oogun si ni.oun si ni eniyan fi n mu ohun gbogbo ni ayika re wa ni ikawo re,yala ohun to lemii tabi eyi ti ko ni.
Ofo je mo pipe awon oro enu bi a se n pe e latayebaye laiyi pada ati pipe awon oro naa ni aimoye igba.Ofo ni awon miiran maa n pe ni ogede,bi ofo se wa fun ire naa ni o wa fun ise ibi.
Yoruba gbagbo pe ohun gbogbo to wa ninu aye yii lo ni agbara tire bi o tile je pe agbara inu okan ju ti ikeji,Iru ero yii lo fa pipa orisii ewe,egbo,eepo igi ati awon nnkan miiran po se oogun fun anfaani eniyan.
Agbara oro ti a fa yo ninu oruko ti a fun ohun-elo oogun kookan ni o wa ninu ihun ofo ti a pe si oogun naa.
Bakan naa ni gbolohun maye maa n wa ninu ofo pipe.
Ero awon Yoruba ni pe gbogbo ohun to wa laye lo ni oruko asiri,ti eniyan le mo ,to le fi pe ohun naa lati sise ti eniyan fe.Bakan naa ni pe ti eeyan ba mo orirun tabi iseda nnkan, eeyan le lo won fun anfaani tire.
Gbogbo eleyii lo si maa n je ki oogun o je kiakia.okan ninu agbara Yoruba niyi,ninu ofo oke yii ni a ti fa oro-ise yo lara oruko ti a fun ewe tabi ohun elo ti a papo se oogun naa.
Ap
Eni ba dari so apa,apa a pa a
Eni ba dari so Iroko,iroko a ko o
Eni ba dari so Oruru
Se ni won-on ru u bo oko.
Eni ba dari so emi lagbja,omo lagbaja
Ojiji lada ba igi eba ona
Ojiji ni ka gbo kuu re,ko dero orun.
Ninu ohun-elo ti won lo fun oogun yii ni eepo igi apa,eepo igi iroko,eepo igi oruru ati eeku ada,ati awon ohun elo miiran.Oluranlowo ni ofo je fun oogun,o maa n ba oogun sise ni.
IWE KIKA
Eko Ede Yoruba Titun. Iwe keji oju iwe 39-43.
APAPO IGBELEWON
- Iyato meloo ni o wa laarin ofo ati ogede? Se alaye kikun.
- Pelu alaye kikun bawo ni itan riro se je orisun agbara Yoruba.
- Ko ona merin ti a n gba gba gbeses?
ISE AMURELE
1. Nibo ni won maa n sin oku oba si laye atijo?
(a) aafin (b) koso (d) Bara
2.______ ni won fi maa n tufo oku oba?
(a) ekun (b) fere okinkin ati ilu koso (d) orin
3. Bi won ba n lo sin oku oba ona meloo ni awon ijoye ti maa duro?
(a) mokanla (b) mejila (d) mewaa.
4.______ je orirun fun ofo ati ogede
(a)oro (b) orin (d)ewi alohun.
5._______ ni oruko oloye ti oye re je mo isinku oba
(a)Abobaku (b)Asetutu oba (d)Ona onse-awo.
Apa keji
1.Salaye lekun-un rere bi a se n sin oku oba.
2.Pelu apeere salaye ohun ti ofo tabi ogede je.