OSE KEFA
ORO AROPO AFARAJORUKO
Oriki
- Abuda oro aropo afarajoruko
- Irisi oro aropo afarajoruko.
- AKOONU : –
Oro aropo-afarajoruko ni isesi to frajo ti oro-oruko sugbon o mu eto iye ati eni lara abuda oro aropo oruko.Awon oro aropo afarajoruko ni wonyii; – emi,iwo,oun,awa,eyin, awon.fun apeere.
Emi ko ri Bola.
Ile awa dun.
Abuda oro aropo afarajoruko.
i. Oro aropo afarajoruko ni eto iye ati eni.
Ate oro aropo afarajoruko.
IYE EYO OPO.
Enikin-ni emi awa
Enikeji iwo eyin
Eniketa oun awon.
Fun apeere : – iwo ni won ran
Awa naa n bo.
ii. A le lo oro asopo lati so oro aropo afarajoruko meji papo.apeere.
emi ati iwo.
Awa ati eyin.
iii. Oro aropo afarajoruko le jeyo pelu awon wunren bii da,nko,ko.Fun apeere
iwo n ko?
Oun da?
Eyin ko.
iv. Silebu meji ni oro aropo afarajoruko maa n ni.apeere.
emi – e /mi.
iwo – I /wo.
v. Oro aropo afarajoruko le gba eyan.Apeere
emi naa wa.
Awon gan-an wa.
- A le gbe oro –aropo afarajoruko saaju wunren akiyesi alatenumo ‘ni’ fun apeere
- Eyin ni oga n pe.
- emi ni mo ra iwe naa.
IRISI ORO AROPO AFARAJORUKO.
Ise oluwa ni oro aropo afarajoruko maa n se ninu gbolohun.ap.
Emi naa mu osan.
Oun ni won n bawi.
IGBELEWON
Lo okookan awon oro aropo afajoruko ni gbolohun.
IWE AKATILEWA
Adewoyin S.Y (2006) Imo, Ede, Asa Ati Litireso fun ile Sekondiri Agba S.S. 3 Corpromutt Publihers Nig Ltd Oju iwe 147-150.
ASA
OWO YIYA
- Oriki
- Awon idi ti a fi n ya owo
- Anfaani ati aleebu owo yiya.
AKOONU : –
Owo yiya je wiwa
iranlowo owo lo si odo elomiran ti a mo pe o ni ju wa lo ni akoko isoro.Se bi ko ba nidii obinrin kii je kumolu,bi ko ba nidii eeyan o le deede lo ya owo.Eyi ni awon idi Pataki ti eeyan fi maa n ya owo laye atijo.
- Inawo pajawiri
- Aisan
- Oran dida
- Oku agba.
ANFAANI OWO YIYA.
- Owo yiya maa n bo ni ni asiri lojo isoro.
- Ki I je ki eeyan di eni yepere tabi eni yeye lowo awon eeyan.
ALEEBU.
- Owo yiya kii fi ni lokan bale.
- Ele gegere ori owo ki I je ki eni yawo tete bo ninu gbese.
- O maa n soro lati le ri owo ti a ya san pada.
- Owo yiya miiran le fa fifi nnkan ini tabi omo wa duro
- Awon ona ti a n gba ya owo ni aye atijo.
AKOONU : –
Awon ona ti a n gba ya owo laye atijo ni; –
- Kiko owo ele: – eyi ni ki a ya owo,ki a si gba lati maa san ele lori owo ti a ya.
- Fifi nnkan ini duro tabi dogo: – eyi ni fifi nnkan ini wa duro,o le je ile,ile tabi moto sugbon ti eni ti o ya owo ko ba ri owo san won le gbe nnkan ini re ta dipo owo ti o ya.Iru owo bayii kii ni ele lori.
- Fifi omo kowo tabi sofa : – eyi nip e iwofa yoo maa se abose loko olowo titi yoo fi ri owo ti won ya san.ise ti iwofa n se fun olowo duro gege bi ele lori owo ti o ya.
IPA TI ONIGBOWO N KO.
Onigbowo je alarinna laarin eni to fe ya owo ati eni ti o fe ya eniyan lowo,onigbowo yii ni o maa duro fun eni to feya owo.Sugbon ti eni to ya owo ko ba ri I san onigbowo yii ni won yoo maa wo bi won ba ti n wo o bee ni oun naa yoo maa ni eni ti o duro fun lara.
IGBELEWON
- Ko aleebu merin nibi owo yiya.
- Ko aafaani owo yiya meta sile.
- Salaye ona ti won gba gbese.
LITIRESO
EWI ALOHUN GEGE BI ORISUN IRONU ;
- ESE IFA
- AALO APAGBE
AKOONU
Ese-Ifa
Ewi atenudenu Yoruba kun fun ogbon, ironu ati iwoye tabi akiyesi awon baba-nla wa, okookan awon ewi yii lo si je orisun ironu,agbara, ati imo-ijinle Yoruba.
Ero ati akiyesi Yoruba.
Awon Yoruba gbagbo pe nigba ti eeyan ba n bow a si ile aye lati orun,yoo kunle si iwaju Olodumare lati yan ipin, ipin yii ni ori ti eeyan mu waye, ti o je mo gbogbo ohun ti yoo sele sioluware laye, titi kan ohun ti eniyan yoo da, ojo iku re, ati iku ti yoo ku pelu, eyi ni o mu gbolohun w ape;
‘A kunle, a yanpin
A kunleyan ni adayeba
Ero Yoruba ni pe Orunmila, baba Ifa, wa ni odo Olodumare nigba ti olukuluku n yan ipin tire, nitori naa ni a se pe e ni Elerii ipin. Gbara ti eeyan ba si ti de ile-aye lo ti gbagbe iru ipin ti ti o yan waye.
Lati mo bi ojo iwaju yoo ti ri ati lati wadii nipa ohun kan ti a fe dawole, tabi lati wa ona lati jade ninu isoro kan, odo Ifa ni eeyan yoo lo lati lo se ayewo, ero awon Yoruba ni pe Orunmila lo ranti iru ipin ti onikaluku yan waye, oun lo si le ba ni se atunnse si oro eni.
Idi niyi ti won fi n kii ni
Okitibiri, Apajo –iku-da
Atori-alaisunwon se.
Imo-ijinle Yoruba
Ese-Ifa-; je akojo ogbon ati imo-ijinle Yoruba lati irandiran. Ko si ogbon tabi imo –ijinle nipa ohunkohun ti a n wa ti ko si ninu odu ati ese-ifa. Ko si isorokisoro ti o de ba eda laye tabi ohunkohun ti eda le fe se iwadii re ti apeere re ko si ninu ese-Ifa. Nitori naa, ni o fi je pe nigba ti eeyan ba lo se ayewo lodo babalawo, babalawo yoo difa lati mo odu ati ese Ifa ti oro oluware yan. Babalawo yoo so itan latinu ese Ifa, iru eni ti iru re ti sele si ri ati ohun ti o se si oro naa, yoo si so fun eni naa lati se bee gege.
Afihan agbara Yoruba
Agbara nla ni imo ti a fun Orunmila, baba Ifa, lati ode-orun gege bi Elerii ipin, lati le mo ohun ti o le sele si laye ati lati ba eda wa atunse si oro re.
Afihan agbara yii tun han nipa aroko ti itan inu Ifa pa fun eni to wa se ayewo, nigba ti babalawo ba n so itan eni ti nnkan yii ti sele si ri lati inu ese ifa, eni ti o wa se ayewo gbodo fi ara re si ipo eni ti a n so itan re, ki o si fi okan sip e bi onitoun yanju isoro re ni oun naa yoo yanju isoro toun, yoo si gbiyanju lati se gbogbo ohun ti won ba ni ko se nipa ti ebo riru, yoo si ri ona abayo, oro re yoo si dayo.
IGBELEWON
1. Salaye ayolo isale yii
“A kunle a yanpin
Akunleyan ni adayeba.
APAPO IGBELEWON : –
- salaye ona ti a n gba sin awon oku wonyii; – i. eni toku somi,ii. Eni ti sango pa. iii. Adete,iv. Eni ti o pokunso.
- Ko orisii ewi gege bi orisii itan isedale Yoruba.
- Awon nnkan wo ni a maa n se ayewo re ti a ba n ko aroko?
IWE KIKA.
- Iwe imodotun Yoruba odun kin-in-ni oju iwe 136,142,151.
- Eto iro ati girama Yoruba.0.i 99.
ISE AMURELE.
- ——- je okan lara awon ona ti a n gba ya owo laye atijo. [a] yiya owo ele [b] yiya owo ni banki [d] yiya owo ninu apo egbe.
- Iwofa yoo maa se ——— loko olowo [a] ise [b] abose [d] agbase.
- Eyin ni won n pe. Oro aropo afarajoruko inu gbolohun yii ni ———
(a) won (b) pe (d) eyin.
- eyo ni (a) emi (b) awon (d) eyin.
- Awa je (a) emi (b) awon (d) eyin.
APA KEJI
1. Kin ni owo yiya?
b. Daruko idi ti a fi n ya owo.
2.Salaye abuda oro aropo afarajoruko merin pelu apeere.
Ko koko ohun ti ewi apileko ti o ka dale lori.