OSE KOKANLA ATI IKEJILA
EKA ISE : EDE
ORI ORO : ATUNYEWO ISE LORI ISEDA ORO
ORUKO
Oro oruko ni awon oro ti o le da duro ni ipo oluwa, abo tabi eyan ninu gbolohun.
Isodoruko ni ona ti a n gba seda oro ti ayorisi oro bee yoo je oro tuntun.
Orisi ona ti a le gba seda oro oruko
- Nipa lilo afomo ibere(prefix)
- Nipa lilo afomo aarin (infix)
- Nipa sise apetunpe (reduplication)
Apeere iseda oro oruko nipa lilo afomo ibere , afomo aarin ati apetunpe.
- Nipa lilo afomo ibere (prefix) : eyi ni kikan afomo ibere po mo oro ise tabi oro oruko. Apeere,
- a + lo = alo
- a + de = ada
- i +jo = ijo
- ai + lo =ailo
- ai + san = aisan abbl
- Nipa lilo afomo aarin (infix) : Eyi maa n jeyo laaarin oro oruko meji. Apeere;
- ore + si + ore = oresore
- igba + de + igba = igbadigba
- iso + ku + iso = isokuso
- emi + ri +emi = emiremi
- iran + de + Iran = irandiran
- igba +ku +igba = igbakigba
- A le seda oro oruko nipa lilo apetunpe apola oro ise (Reduplication of verbs) : apeere;
- Gbomo + gbomo = gbomogbomo
- Jagun + jagun = jagunjagun
- A le seda oro oruko nipa lilo apetunpe oro oruko (Reduplication of noun). Apeere;
- Ale + ale = Alaale
- Omo + omo = Omoomo
- A le seda oro oruko nipa lilo apetunpe
elebe (partial reduplication): Eyi ni ki a fi faweli ‘I’ ti o je mofiimu olohun oke po mo konsonanti akoko ti o bere oro ise, ki a tun fi odidi oro ise ipinle bee kun-un. Apeere;
- Je – j + i = Jije
- Fe – f + I = Fife
- Ra – r + i = Rira
IGBELEWON:
- Fun oro oruko loriki
- kin ni iseda oro oruko?
- Salaye pelu apeere awon ona ti a n gba seda oro oruko ni ile Yoruba
ISE ASETILEWA:
Bawo ni a se seda awon oro oruko wonyi;
- Onidajo
- Igboya
- Ogboogba
- Jobijobi
- Bamgboye
- Pejapeja
- Fife
OSE KOKANLA ATI IKEJILA
EKA ISE: ASA
ORI ORO: ATUNYEWO ASA IKINI
Asa ikini je okan lara iwa omoluwabi; o je iwa ti a gbodo ba lowo omo ti a bi ti o gba eko rere.
Ikini oniruuru ni ile Yoruba
Akoko Ikini Idahun
- Ni owuro E kaaaro/se alaafia ni a ji? A dupe
- Ni osan E kaasan O o
- Ni irole E kurole O o
- Ni ale E kale O o
- Akoko ojo E ku ojo O o
- Akoko oye E ku oye O o
- Awon alaboyun Asokale anfaani O o
- Awon o n tayo Mo kota mo kope Ota n je, ope
Ko gbodo fohun
- Agbe Aroko bodunde Ase
- Onidiri Ojugbooro E ku ewa Iyemoja a gbe o
Tabi ooya aya o
- Iya olomo tuntun E ku owo lomi oo
IGBELEWON:
- Fun asa ikini loriki
- N je loooto ni awon Yoruba n fi iwa omoluabi han nipa asa ikini?
ISE ASETILEWA:
Bawo ni a se n ki awon wonyi ni ile Yoruba:
- Akope
- Ontaja
- alaboyun