OSE KEJI
ORI-ORO-;SILEBU EDE YORUBA
        Oriki.
        Ihun silebu.

AKOONU:- Silebu ni ege oro ti o kere julo ti eemi le gbe jade leekan soso
Iye ohun ti o ba wa ninu oro ni iya silebu ti oro naa yoo ni.
Fun Apeere
Wa-je oro onisilebu kan nitori pe ami ohun kan ni o wa lori re.
    I / we = 2
    Ba / ta = 2
Ihun silebu:-
    Ona meta Pataki ni ihun silebu pin si awon naa ni:-

  1. Ihun faweli kansoso
  2. Ihun to je konsonanti ati faweeli.
  3. Ihun to je konsonanti aranmupe-asesilebu.

 
  i.    IHUN FAWEELI KAN SOSO
Eyi ni ihun to je faweeli kan soso ‘f’ ni a maa n lo fun ihun yii..fun apeere
    I / we
    A /a / lo

 ii. IHUN TO JE APAPO KONSONANTI ATI FAWEELI:-
Eyi ni ihun ti o je konsonanti ati faweeli,faweeli yii le je aranmupe tabi airanmupe. ‘KF’ni a n lo fun ihun yii.fun apeere
    Je
    Kf
    
Wa        gbin
Kf         kf

 Ra        sun
Kf        kf

 iii.IHUN TO JE KONSONANTI ARANMUPE ASESILEBU:-
Eyi ni ihun silebu ti konsonanti aranmupe ‘n’ ati ‘m’ maa n dun gege bi silebu.
‘N’ ni a maa n lo fun ihun yii.
Fun apeere
Gba /n /gba =3
Ke / n /gbe =3
A / la / n / gba =4
Bi /m / bo.
Kf-N-kf

 
 Oro olopo silebu-;eyi ni oro ti o ni ju silebu kan lo,o le je silebu meji,meta tabi ju bee lo.
ap
Oro        ipin ihun            iye
Ade        a-de f-kf            meji
Sugbon        su-gbon     kf-kf             meji
Nnkan n-n-kan f-f-kf             meta
Opolopo o-po-lo-po f-kf-kf-kf            merin
Ogunmodede o-gun-mo-de-de f-kf-kf-kf-kf marun-un
Alapandede a-la-pa-n-de-de f-kf-kf-N- kf-kf         mefa

 IGBELEWON

  1. kin ni silebu?

b. Daruko ihun silebu, ki o si salaye won pelu apeere.

 IWE ITOKASI:
Adewoyin S.Y (2014) IMO, EDE, ASA ATI LITIRESO YORUBA fun ile eko girama agba S.S.2 Corpromutt Publisher Nig Ltd. O.I 53-57

 ISE ABINIBI
Eni ise ni oogun ise
Eni ise n se ko ma b’Osun
Oran ko kan t’Osun
I baa b’Orisa
O dijo to sise aje ko to jeun.
Owuro lojo, ise ni a fii se ni Otuu’Fe. Kaakiri ile Yoruba ni won ti n fi owuro sise. Won gbagbo wi pe ise loogun ise. Eredi ti won fi ise won ni okunkundun ni yii. Se eni mu ise je ko sai ni ise je. Eni ni ko feran ise ni won n pe ni ole. Won a maa ni ole afajo. Ojo odun de ni oro n dun ole tori gbogbo egbe re ni o raso sugbon oun ko le ra. Lara ise abinibi ile yoruba ni: ise agbe ‘eyi to wopo ju laarin ise abinibi’ ode, awako oju omi, babalawo ……..

 ORISII ISE AGBE
Agbe olokonla
Agbe alaroje

 ORISII OKO
Oko akuro
Oko etile
Oko egan
Oko odan

 OHUN ELO ISE AGBE
Oko, Ada, apere, …………..

 IGBELEWON
Salaye ogbin ati ikore agbado.

 IWE ITOKASI:
Adewoyin S.Y (2014) IMO, EDE, ASA ATI LITIRESO YORUBA fun ile eko girama agba S.S.2 Corpromutt Publisher Nig Ltd. O.I 136-150.
ATUPALE IWE ASAYAN

 Atupale iwe asayan ti ijoba yan.

 Salaye eda itan marun-un ninu iwe apileko

 ISE ASETILEWA

  1. ohun ti o kere ju ti eemi le gbe jade leekan soso ni (A) akoto (B) oro (C) faweli (D) silebu.
  2. Silebu meloo ni o wa ninu ”olopaa’ (A) meji (B) meta (C) merin (D) mejo
  3. Ninu ‘iwe’ odo silebu ni (A) i (B) w (C) e (D) ko si odo silebu nibe.
  4. Ibi ti awon agbe maa n gbin nnkan si ni (A) oko (B) ile (C) oko (D) papa
  5. Awon agbe maa n lo ……. lati ka koko (A) oko (B) ibon (C) obe (D) ada.

APA KEJI

  1. Salaye odo silebu ati apaala silebu pelu apeere mejimeji.
  2. Fun awon wonyi ni apeere mejimeji: KFKF, KFKFKF, KFNKF, FKF, FKFKF
  3. Salaye lori ohun ogbin kan.

     

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *