SIGMA TERM ILAANA ISE NI SAA KINNI FUN JSS3
YORUBA LANGUAGE
| OSE | AKORI EKO |
| 1 | EDE – Ihun orisirisi awe gbolohun po lati di odidi gbolohun ASA – Awon asa to suyo lati inu awon ewi alohun LITIRESO – Kika iwe literaso apileko ti ijoba yan |
| 2 | EDE – Atunyewo leta kiko (aigbefe) ASA – Awon oriisa ati eewo to suyo ninu litireso alohun ti a n fi oro inu won daa mo LITIRESO – Ifaara lori litireso alohun |
| 3 | EDE – Iyato ti o wa laarin apola ati awe gbolohun Yoruba ASA – Itan isedale agbala aye LITIRESO – Kika iwe litireso apileke ti ijoba yan |
| 4 | EDE – Aroka alalaye ASA – Owe ile Yoruba LITIRESO – Oriki orile elerin, olokun, esin, onikoyi, olofa abbl. |
| 5 | EDE – Gbolohun Onibo ASA – Awon akanlo oro inu ede ati awujo Yoruba LITIRESO – Kika iwe apileko ti ijoba yan |
| 6 | EDE – Akaye oloro wuuru / geere ASA – Awon orisa to suyo ninu litireso LITIRESO – Kika iwe litireso ti ijoba yan |
| 7 | EDE – Akaye II (Ewi) ASA – Awon imole / orisa to suyo ninu litireso LITIRESO – Kika iwe litireso ti ijoba yan |
| 8 | EDE – Atunyewo awon oro eyan ASA – Igbese igbeyawo ni ile Yoruba LITIRESO – Kika iwe litireso ti ijoba yan |
| 9. | EDE – Atunyewo awon oro aponle ASA – Ikomojade ni ile Yoruba LITIRESO – Kika iwe apileko ti ijoba yan |
| 10 | Atunyewo ise lori ise saa yii lori ede, asa ati litireso |
| 11 | Idanwo ipari saa keji |
| 12 | Ifi – owo si iwe idanwo |
OSE KINNI
AKORI EKO: IHUN ORISIIRISII AWE GBOLOHUN PO DI ODIDI GBOLOHUN
Kin – in – ni awe gbolohun?
Awe gbolohun ni ipede to ni oluwa ati ohun ti oluwa se
Bi apeere:
Ayinke mu omi
Adepoju ti jeun
Kasali je eba
Awe gbolohun le je ipede ti ko ni ju apola oro oruko ati apola kookoo lo. Apeere:
Mo gba ebun naa
Awon ni won wa
Ade ti sun lanaa
Mo gba ebun naa
apola apola oro – ise
oro-oruko (verb phrase)
(Noun phrase)
Awe gbolohun le da duro ki o ni itumo. Apeere:
Isola ati Ajani ra aso
Omi ero naa mo
Awe gbolohun miiran le da duro ki maa ni itumo (awe gbolohun afarahe)
Ti a ba ko ile
Iba ke si mi
Yala o wa tabi ko wa
Awe gbolohun le da duro bi odidi gbolohun, iru awe gbolohun bee ni a maa pe ni olori awe gbolohun. Apeere:
Won gba
Ade mo
Iya omo ni
Itesiwaju ise lori awe gbolohun Abeke gbon
Opolopo awon gbolohun abode ni o le se ise awe gbolohun. Sugbon kii se gbogbo awe gbolohun lo le da duro bii gbolohun. Awon gbolohun isale wonyi le se ise awe gbolohun.
Akanmu mu emu
Apinke se iresi
Ode pa igala
Orisii awe gbolohun (Types of clause)
1. Olori awe gbolohun (main clause): Eyi maa n da duro, o si maa n ni itumo ati paapaa o maa n sise odidi gbolohun. O ti ihun jo gbolohun abode tabi gbolohun eleyo oro-ise. Bi apeere:
Awon omode feran iresi
Aja Ogundeji ku
Ise dara
2. Awe gbolohun afarahe (subordinate clause): Inu ihun gbolohun olopo oro-ise tabi gbolohun onibo ni a ti maa n ri awe gbolohun afarahe. Ninu gbolohun olopo oro – ise. Ipa kan yoo je gbolohun kikun nigba ti awon iyoku yoo je awe gbolohun afarahe ti ko ni itumo.
Orisii awe gbolohun afarahe
i. Awe gbolohun afarahe asapejuwe: ti ni atoka ibeere awe gbolohun yii. Awe gbolohun yii maa n tele oro oruko tabi apola oruko, o maa n je ki a mo nipa apejuwe nkan. Bi apeere
Apinke ti o sun ti dide
Aso Ankara ti mo ra dara
Omoge ti mo n soro re niyi
ii. Awe gbolohun afarahe asodoruko: ‘Pe’ ni o maa n bere awe gbolohun yii, o le sise oluwa ati abo, o si maa n sise iso – doruko ninu ihun gbolohun. Apeere:
Pe Olu ku ti mo gbo igbe ni mo fi ta
Pe oju ka awon ole naa mo dun mo mi
Oda mi loju pe omo naa ko le jale
iii. Awe gbolohun afarahe asaponle: Awon oro atoka fun awe gbolohun yii n ‘nigba’, ‘ti’, ‘nitori ti’ abbl. Awon oro – ise ti won maa n tele gbolohun ni won maa n pon. Bi apeere:
Aja naa ku nigba ti oko ko lu u
Emi yoo lo nisinsinyii ti mo gbo pe won de
Ole naa ku nigba ti olopaa kolu won
Obrinrin naa ku nitori ko ri owo le iwosan san
Iyato ti o wa laarin apola ati awe gbolohun (Differences between phrase and clause)
| APOLA (PHRASE) | AWE GBOLOHUN (CLAUSE) |
| 1. Apola kii ni oro – ise (ayafi ninu apola ise) Bi apeere: Iya Joke Aburo Badejo Ni Ibadan | Awe gbolohun gbodo ni oro – ise ninu. Bi apeere: Ki o to sun Ti mo ra Maa jo |
| 2. Apola ko le da duro ki o fun wan i itunmo kikun. Bi apeere: Ni abule odu Papa asafa Aja ode Rin kemokemo | Olori awe gbolohun le da duro ki o fun wan i itumo kikun. Bi apeere: Mo ti de Fijobi kan ilekun Aso Ankara dara |
| 3. Apola ko le daduro bi odidi gbolohun kikun. Bi apeere: Iwo ati emi Ni Osogbo Ti ile bo | Olori awe gbolohun le da duro bii gbolohun kikun ti o ni itumo. Bi apeere: Obinrin yii burewa Egungun ko korin Adeojo kii ja |
OSE KEJI
AKORI EKO: ATUNYENWO LETA AIGBEFE (INFORMAL LETTER)
IGBESE LETA AIGBEFE
i. Adiresi: Adiresi akoleta (The writer’s address)
Adiresi agbaleta (Receiver’s address)
ii. Deeti (the day’s date)
iii. Ikini ibeere (salutation)
iv. Akole leta (the tittle / heading)
v. Koko leta (main content)
vi. Ikadii / ipari leta (conclusion)
Leta aigbagbefe / aigbefe (Formal letter)
Eyi ni leta ti a maa n ko si awon eniyan ti won wa ni ipo kan ni ibi ise adani tabi si ajo ilu. Leta bayii kii se enikan pato, eni ti o je oga ni akoko naa ni yoo kaa. Idi niyi ti a kii fi ko oruko eniyan Kankan sii.
Ninu leta aigbagbefe, ko si aaye fun iroyin tabi efe rara. Apeere iru leta yii ni a n ko si Ajele, Olofuu iwe iroyin, enwa ile – ise, oba, Alaga igbimo, Alaga ijoba ibile, oga ile – iwe ati akowe agba ibi ise ijoba apapo bii: oga agba ajo idanwo WAEC, NECO ati JAMB.
Igbese Leta aigbagbefe
a. Adiresi: Adiresi meji nil eta aigbafe maa n ni
i. Adiresi akoleta: eyi yoo wa ni owo otun oke iwe, deeti ojo ti a koi we yoo tele ni isale.
ii. Adiresi agbaleta: Eyi yoo wan i owo osi ni ila ti o tele deeti. Apeere:
Federal Government College,
Ilorin,
Kwara State.
2nd February, 2015.
Olotuu,
Iwe Iroyin Alaroye
34, Agbabiaka Street,
Lagos.
b. Ikini Ibeere: Apa osi ni ila ta tele adiresi agbaleta ni akoleta yoo ko ikini akoko si leta n la ni o gbodo fi bere yoo si fi ami koma kadii re. apeere:
Olotuu,
Oga ile – iwe,
Akowe agba, abbl
d. Akole leta aigbefe: Ila ti o tele ila ikini ni akoleta yoo ko akole leta re si ni aarin iwe yoo si fara sidii re ti o ba ti leta kekere ko o tabi ki o ko o nil eta nla lai fala si nidii. Apeere:
Ayeye Ojo Omiran Orile – Ede Naijiria.
e. Ara leta: Aaye ko si fun iforo jewoo tabi awada ninu leta yii, ohun ti a ba fe so ni pato ni a gbodo gbe kale. Ti o ba si je esi iwe ti akoleta ko gba tele tabi ko ni a gbodo fihan.
e. Ikadii/ipari: owo otun ni isale iwe ni akoleta yoo ko igunle leta re si, oruko meji (iyen ni oruko akoleta ati obi re) ni o gbodo ko pelu ami idanuduro ni ipari. Apeere:
Emi ni,
Biodun Agbabiaka.
(signature)
Ise Asetilewa
Ko leta si oluko agba ni ile – iwe re lati gba aaye fun ose kan nitori ailera re.
AWON ORISA ILE YORUBA ATI AWON EEWO WON
Eniyan ni awon orisa wonyii ni igba aye won (ifa, ogun, esu, sango, oya, osun abbl). Sugbon nitori akitiyan ati ise akoni won nigba ti won wa laye ni awon Yoruba se so won di orisa akunlebo. Paapaa julo, iru iku ti won ku ati ise won leyin iku won so won di eniyan oto laarin awon omo adari ti n irun.
1. Ifa tabi Orunmila: Orunmila ni awon Yoruba pe ni Agbonmiregun, ayanmo tabi kadara eniyan ko seyin re, ko si ohunkohun ti eniyan le se laye ti ko ni mo nipa re. orisa yii je okan gboogi ninu awon ibe ti awon Yoruba ka si lopolopo, ifa dide (pelu ikin tabi opole) ni o maa n so ayanmo tabi ese – n – taye omo. Litireso atenudenu ti a maa n lo ti a ba n da ifa tabi se odun ifa ni a n pe ni iyere ifa, amaa n sun uyere ifa lati fi yin tabi ki ifa ni.
Ounje Ifa niwonyii:
- Adie
- Ewure
- Eyele
- Igbin
- Eja
- Epo pupa abbl.
Eewo Ifa
Awon olusin re ko gbogbo je iu titun saaju odun ijesu.
2. Ogun:Agbe ni ogun nigba aye re, o si je akikanju nigba ti o wa laye. Ni aye ode – oni gbogbo awon ohun elo tabi irinse ti o ba je mo irin ni won maa n boo gun. Ijala ni ewi ti ab maa ri sun nibi odun ogun tabi ni ibi isipa ode.
Ounje Ogun niwonyii:
- Aja
- Iyan
- Emu
- Esun isu abbl
Eewo Ogun
Gbigbe ofifo agbe tabi akeregbe emu duro ni ojubo re.
3. Sango: Oba ni Sango je ni igba aye re ni ode aye, o si je alagbara pupo ti o fi je pe ko si ogun ti oba Sango ko le koju nigba aye re, agbara re po to bee ti ina fi maa n yo lenu re nigba ti a ba n binu, gbogbo awon eniyan si maa n beru re. Iyawo meta ni Sango ni, awon no Osun, Oba ati Oya si jee aya re.
Ilu dite mo Sango nitori asilo agbara re, o fi ilu sile, Oya nikan lo si tele. Oya wole ni IRA o si di odo ti a mo si odo Oya. Sango pokun so nidii igi AYAN ni koso.
Awon elegun Sango maa n di irun ori won bii ti obinrin, aworo Sango ni a n pen i Baba Mogba.
Ounje Sango niwonyii:
- Orogbo
- Agbo funfun abbl
4. ESU: Ilu ile – ife ni esu n gbe nigba aye re, o je oburewa, eniyan ESU fi igba kan koi se, ifa dida (awo) ni idi orunmila. O je eni to gbonu – gboya, ko si eni ti ko le ko loju, gbogbo ebo ti ESU bag be lo maa n fi (da). Orunmila maa n ran –an lo si odo Eledumare ni orun, idi niyi ti won fi n pe e ni “Agbayegborun”.
ESU maa n gba ija onija kann; a sit un maa n da ija sile laarin eniyan meji nigba aye re. igboju, akikanju ati ebo ti o n gbe to si n da, ni o je ki awon eniyan so di orisa leyin iku re.
Ounje Esu ni wonyii:
Gbogbo nkan tie nu n je ni ounje ESU
Eewo Esu
Tita adin si oju re
OWE ILE YORUBA
Owe ni akojopo oro ti o kun fun ogbon, imo yinle ati iriri awon agba. Owe yii ni awon agba maa n pa lati fi yanju oro to ba ta koko. Ni ile Yoruba, omode kii pa owe niwaju agbalagba lai ma toro iyonda lowo won, omode naa yoo so pe ” tooto o se bi owe”, awon agba ti o wan i ijokoo yoo si dahun pe “wa a ri omiran pa”.
Ona ti owe gba waye
1. Akiyesi sise: Awo agba maa n sakiyesi awon isele ti o n sele ni ayika won lati seda owe. Bi apeere: Bi a ba gba ile, gba ita, aatan la n da a si.
2. Esin: Opolopo awon owe ti awon baba n la wa maa n pa ni won waye nipase esin ibile won. Apeere: Aigbofa la n woke, ifa kan ko sin i para.
3. Asa: inu okan – o – jokan asa Yoruba ni awon agba ti seda opolopo awon owe. Bi apeere: Ile la n wo, ki a to so omo loruko.
ISORI OWE
Ona marun – un ni isori owe pin si, awon nii:
- Owe fun imoran
- Owe fun alaye
- Owe fun ibawi
- Owe fun ikilo
- Owo fun isiri
1. OWE FUN IMORAN: ti oro ba doju ru, awon agba n a maa n to lo fun imoran to ba ye. Ni opolopo igba, owe ni won maa n pa lati to eniyan sona. Bi apeere:
a. Ile ti ko toju eni su, okunkun re maa n soro o rin.
b. Alagemo ti bimo re tan, aimojo ku sowo omo alagemo
d.Igi ganganran ma gun ni loju, okeere lati n wo o
e. Oju mewaa ko ju oju eni
e. Falana gbo tire, tara eni la n gbo
2. OWE FUN ALAYE: Awon owe kan wa ti awon agba fi maa n salaye oro okan won fun eni ti won ba a ba soro. Apeere:
a. Ki ile to pa osika, ohun rere a ti baje
b. A ku to eni bog be ki a maa to oro ba nii so.
d. Agba to n sare ni aarin oja ni bi nkan ko le, a je pe o n le nkan
e. Agbatan ni a n gba ole, bi a ba da so fun ole a paa laro, bi a ba la ole nija, a sin-in dele.
e. Ara aimuole le n ko je ki a mop e ologbo n sode.
3. OWE FUN IBAWI: Bi enikan ba n huwa ti ko dara, owe awon agba fi ma n ba iru eni bee wi. Apeere:
a. Bi omode ba n se bi omode, agba o si se bi agba.
b. Aja kii roro ko so oju lo meji
d. Afase gbe ojo n tun ara re je
e. Adiye funfun ko mo ara re la gba
e. A kii roe ran enu lori, ki a tun maa fi ese wa ire nile
4. OWE FUN IKILO: Ti a ba se akiyesi pe enikan wa ninu ewu ti oun gan-an ko mo tabi fura, awon agba maa n pa owe lati kiilo fun pe ki osora. Apeere:
a. Bi eti ko ba gbo yinkin, inu kii baje
b. Ise ni oogun i se
d. Alaso ola kii ba elepo sere
e. Agboju logun fi ara re fun osi ta
e. Ese gin nile origafe, arijose ku, a ko ri enikan
5. OWE FUN ISIRI: A maa n lo awon owe yii lati tu eniyan ti o wa ninu ibanuje ninu tabi eni ti o ti so ireti nu oro aye re. Bi apeere:
a. Igbeyin ni alayo n ta
b. Kii buru titi ki o ma ku enikan mo ni, eni ti yoo kun i a komo
d. Ajeji owo kan ko gberu dele
e. Ise kii se ni, ki omo eni maa dagba
e. Pipe ni yoo ope, akololo a pe baba
Ise Asetilewa
Se alaaye ati itunmo owe yii “Adiye funfun ko mo ara re lagba”.
OSE KETA
AKORI EKO: EYAN
Eyan ni awon wunren (oro) ti a fi n yan oro – oruko (noun) tai apola oruko (Noun phrase) ninu gbolohun tabi ninu isori. Bi apeere:
Iwe tuntun ni a f era
Aso ala ni mo wo
‘Tuntun’ ati ‘ala’ ti a fa ila si ninu gbolohun oke yii ni oro eyon ti o n se afikun itumo fun oro oruko ti won n yan.
Orisii eyan
- Eyan asapejuwe
- Eyan ajoruko
- Eyan asafihan
- Eyan asonka
- Eyan alawe gbolohun asapejuwe
1. EYAN ASAPEJUWE: Ise eyan yii ni lati pon oro oruko lona ti yoo fi ye ni tekeyeke. Oro apejuwe pin si ona meji, awon ni:
a. Oro apejuwe ipile: iwonyi ni awon oro bii; pupa, rere, dudu, kekere, nla, funfun abbl.
Apeere lilo ni gbolohun
Nike je omo rere
Amala dudu ni mo feran
Ounje kekere ko le yo mi
2. EYAN AJORUKO: Eyi ni oro oruko tabi oro aropo oruko ti a lo lati yan oro – oruko miiran. Bi apeere: Dokita oyinbo ni mo fe ri
Abule odu ni Busola n gbe
Ewure Torera ni ole ji
Ile wa ni a n lo
3. EYAN ASOFIHAN: Eyi maa n toka si ohun ti a n soro nipa re. Weren tabi oro atoka re ni: wonyen, yii, yen, ati wonyi. Apeere:
Oro yen dun mo won ninu
Ile yii ga ju
Pasito gan-an ni mo fe ri
4. EYAN ASONKA: Irufe eyan yii nii se pelu onka, o maa n toka si iye nkan ninu gbolohun. Bi apeere:
Omode meta n sere
Oko kan ni oluwa yan fun obinrin
Akara mefa ni mo je
Ile marun-un ni baba – agba ko
5. EYAN ALAWE GBOLOHUN: ‘ti’ ni wunren atoka awe gbolohun asapejuwe. Ise re ni lati fi itunmo kun itumo oro – oruko ninu gbolohun. Bi apeere:
Gele ti a ran i ana wun mi
Ile ti mo ko ti kere ju
Baba ti o n soro re lo n bo yii
Ise Amutilewa
Toka orisii eyan ti o wa ninu gbolohun isale wonyii, ki o si fa ila si nidii.
1. Oko wonyen ni mo fe ta
2. Iyawo ti mo ni dara
3. Eran dindin wu mi je
4. Aso aran ni iya agba wo
5. Oke meje ni a gbodo gunde ibe
6. Iyana – Ipaja ti daru
7. Oke nlanla wan i Efon Alaye
ASA IGBEYAWO
Igbeyawo ni isopo okunrin ati obinrin lati di took-taya ni ibamu pelu asa ati ilana isedale ile Yoruba.
Koko mefa pataki ti o n gbe igbeyawo ni
- Ifesona (courtship)
- Ifayaran (perseverance)
- Suuru (patience)
- Ipamora (tolerance)
- Igbora-eni-ye (understanding)
- Ife aisetan (unconditional love)
IGBESE IGBEYAWO
- Ifojusode
- Iwaadi
- Alarina
- Isihun / ijohen
- Itoro
- Baba gbo, iya gbo
- Idana
- Ipalemo
- Ifa iyawo
- Ojo igbeyawo
- Ese iyawo wiwe
- Ibale
- Ikorun
- Ojo keje
IRO KONSONANTI
Iro konsonanti ni awon iro ti idiwo maa n wa fun jijade eemi ni kaa enu nigba ti a ba n pe won. Ona meta ni a le gba mo iru iro konsonanti ti an pe. Awon ona wonyii ni:
- Ibi isenupe
- Ona isenupe
- Abuda iro konsonanti
A. IBI ISENUPE: orisii mejo ni ibi isenupe iro konsonati ede Yoruba. Awon ibi isenupe wonyi bere lati ete lo si ibi otooto orule enu titi lo dopin. Awon naa ni:
(i) Afetepe
(ii) Afeyinfetepe
(iii) Aferigipe
(iv) Afajaferigipe
(v) Afajape
(vi) Afafasepe
(vii) Afafase fetepe
(viii) Afi-tan-an-na-pe
B. ONA ISENUPE: orisii meje ni awon ana isenupe iro konsonanti awon ni won wa lori bi afefe eemi ti maa n jade nigba ti a ba n pe iro tabi soro. Awon ni:
i. Asenupe
ii. Afunnupe
iii. Asesi
iv. Aranmupe
v. Arehon
vi. Afegbe enupe
vii. Aseesetan
D. ABUDA IRO KONSINANTI: ti a ba fe se apejuwe iro konsonanti ni ilana abuda, a ni lati wa awon ilana yii:
i. Orisun eemi (eemi amisinu tabi eemi amisode)
ii. Ipo ti alafo tan-an-na wa (ipo imi tabi ipo ikun)
iii. Ipo afase (boya afase wa sile tabi o gbera soke)
iv. Irufe afipe ti a lo (yala afipe asunsi tabi akanmole)
v. Irufe idiwo ti o wa fun eemi (boya ona se patapata tabi o si sile die)