OSE KEWAA
APOLA
AKOONU: –

  • Ki ni a n pe ni Apola.
  • Ki ni Apola oro Oruko
  • Ise ti Apola Oro Oruko n se ninu Gbolohun?
  • Ki ni a n pe ni Apola ise?
  • Ise ti Apola Ise n se ninu Gbolohun

 Apola ni akojopo oro ti o n di apa kan gbolohun. Apola le je eyo oro kan, o si le je meji tabi ju bee lo. Orisiri apola lo maa n di apa kan tabi odidi gbolohun.
Apola oro oruko ni eyo oro oruko kan tabi meji tabi ju bee lo ti o di apa kan odindi. O si le je apapo oro oruko ati oro oruko eyan ninu gbolohun Yoruba. Apola oro oruko le je oro oruko, oro aropo oruko, tabi aropo afara joruko.

Apeere apola to je eyo oro oruko kan

Iwe
Moto
Aso
Ileke
Apola le je eyo oro oruko meji tabi ju bee lo
Oju titi
Omi ojo
Baba agbe
Igi oko
Awa omo baba olowo ilu yii niyi.

Oko ayokele oloye ni mo ra
Apola oro oruko ati eyan
Ewu tuntun meji ni mo ra
Ile tI mo ko ga fiofio
Ise yi ma le o
Iwo gan-an lo mu owo mi

 ISE TI APOLA ORO ORUKO N SE
1.    Apola oruko maa n duro gege bii oluwa ninu gbolohun. Apeere:-
    Mo je eba
    Iwo ri olopaa
    Ade pa aja
2.    Apola oro oruko tun le duro ni ipo abo ninu gbolohun. Ohun ni ohun ti oro ise maa n fi abo le lori ninu gbolohun. Apeere:-
    Ife ra fila
Tisa na omo naa
Mo pe won
3.    Apola oro oruko le duro ni ipo eyan ninu gbolohun. Apeere:-
    Ise akowe dara
Ounje Jumoke ni mo fe je
    Ere ipa ko dara.

 APOLA ISE
    Oro ise ni opomulero ti o n toka si isele tabi koko
inu gbolohun. Oro ise maan ko ipa Pataki ninu gbolohun ede Yoruba. Apeere Oro ise:-
    Mo ta oja
Ade jeun
Omo naa n sunkun.
Apola oro ise le je eyo oro ise kan tabi oro ise meji tabi ju bee lo. Osi le je apapo oro ise pelu isori oro miiran ninu gbolohun Yoruba.
Apeere:-
apola eyo oro ise kan.
Anike sun
Sangba fo
Ile jo
Oko danu
Apeere Apola Oro Ise Meji Tabi Ju bee Lo.
    MO sare
lo sun
    Bola ti jise ti mo ran-an
    Tade je isu ti ko jina
    Apeere apola oro ise pelu isori oro miiran le je oro oruko, aponle, asapejuwe ati bee be lo.
    Omo pupa kekere kan n wa iya re
    Mo tete de si ipade lonii
    O sun fonfon leyin ounje ale

     ISE APOLA ORO ISE NINU GBOLOHUN
1.    Oro Ise Agbabo:- Awon oro ise kan wa ti won maa n ni oro oruko ti o tele won ninu gbolohun, iru awon oro ise bee ni a maa n pe ni oro ise agbabo. Iyen nipe won maa n ni abo ninu. Apeere:-
    Tafa ta ofa
    Jide ra keke kan
    Mo ja ijakadi
2.    Oro Ise Alaigbabo:- Eyi ni awon oro ise ti kii ni oro oruko kankan ninu to duro gege bi abo ninu gbolohun. Apeere:-
    Isu naa jina
    Agbado hu
    Tata n fo
Oro Ise Amugbalegbee:- Oun naa ni a mo si oro aponle. O maa n fun oro ise ni itumo kikun to si ja gaara. Apeere:-
    Mo tete de
Ade sise gidi
Alejo mi sese de

 IGBELEWON

  1. KI ni apola?
  2. Ki ni aplo oruko?
  3. Ki ni apola ise?
  4. Toka si apola oruko ni ipo oluwa nihihin

Ode pa eran
Sola ge igi
Baba wo oko ayokele

  1. Iru apola wo ni won fala si nidi yii

Tafa ta ofa
Agbado hu

 IWE AKATILEWA

  1. S.Y Adewoyin (2004) NEW SIMPLIFIED YORUBA L1 J.S.3 Copromutt (publishers) Nigeria Limited Oju Iwe 15-16.
  2. Egbe Akomolede ati Asa Yoruba Eko Ede ati Asa Yoruba Iwe Keji Oju Iwe 8-10 Longman Nigeria Plc.
  3. Oyebamiji Mustapha Eko Ede Yoruba Titun Iwe Keji Oju Iwe 17-18 University Press.
  4. Egbe Akomolede ati Asa Yoruba Eko Ede ati Asa Yoruba Iwe Keji Oju Iwe 20-22 Longman Nigeria Plc.
  5. Oyebamiji Mustapha Eko Ede Yoruba Tunutun Iwe Keji Oju Iwe 102-103 University Press Plc.

 IGBAGBO AWON YORUBA NIPA OLODUMARE
Akoonu: igbagbo awon Yoruba nipa Olodumare.
     Orisiirisii oruko Olodumare
     Ifihan ero Yoruba lori oruko Olodumare
     Ohun ti opolopo awon eniyan lero ni wi pe awon Yoruba ko mo Olorun tele afi igba ti awon elesin Kristi ati awon islam to de. Iro patapata ni eyi. Awon Yoruba ti n sin Olorun ki awon elesin ajeji to de. Lara awon ohun ti o je ki a mo ni oniruuru oruko ti a n pe Olorun. Oun ni a n pe ni Olodumare tabi Eledumare,Olu orun,Olorun, Eledaa, Adedaa, Obanjigi, Oba ogo abbl.
    Awon yoruba beru Olorun pupo bakan naa ni a si tun bowo fun. Idi niyi ti a ki I fi ku giri lo ba tabi ki a maa beere nnkan lowo re. Dipo bee a yan awon orisa kan gege bi asoju wa tabi alagbawi wa lodo re. Awon iru orisa bee ni Ogun, Sango, Orunmila, Obatala abbl. Awon wonyi ni awon Yoruba maa ran si Olorun nigba ti won ba fe gba nnkan lowo re.
    Die lara awon oruko ti o fi igbagbo awon Yoruba han nipa Olorun ni:

  • Olowogbooro
  • Eleti gbaroye
  • Atererekaye
  • Awimayehun
  • Olodumare
  • Obanjigi
  • Olorun
  • Olu Orun
  • Oba Ogo.
  • Kabiyesi
  • Jingbinikin
  • Arogunmatidi
  • Arabaribiti
  • Aribirabata.

     

IGBELEWON
Ko oruko Olodumare marun-un ti o fi igbagbo awon Yoruba han nipa Olodumare sile.

 IWE AKATILEWA
1 Egbe Akomolede ati Asa Yoruba (2002) Eko Ede ati Asa Yoruba iwe keji (J.S.S.2) Longman Nig Plc.oju iwe 95-97
2 Oyebamiji Mustapha (2009) Eko Ede Yoruba Titun iwe keji (J.S.S.3) university Press Plc.oju iwe 181-18

 APAPO IGBELEWON

  1. Ko oruko Olodumare marun-un ti o fi igbagbo awon Yoruba han nipa Olodumare sile.

ZT%NY@W) IX!

  1. Ki ni oro aropo afarajoruko?
  2. Ko apeere oro aropo afarajoruko sile.
  3. Ko iyato merin laarin oro aropo oruko ati oro aropo afarajoruko merin.

     

ISE ASETILEWA
1.    Apola oro oruko le wa ni ipo oluwa, abo ati _____(a) ise (b) eyan
(d) Apejuwe
2.    Oro wo ni o n sise oluwa ninu gbolohun yii “Ayo ba Tunde ja” (a) Tunde
(b) Ba (d) Ayo
3.    ______ ni opomulero gbolohun (a) Oro oruko (b) Oro ise (d) Oro aponle
4.    Isori oro wo ni a ko le ba pade ninu apola oro ise? (a) Ko si (b) Oro oruko (d) oro
aponle
5.    Oro ise alaigbabo ki i ni _______ ni ipo abo (a) ni oro ise (b) ni oro oruko
(d) Kii ni oro atokun.
APA KEJI

  1. ko oruko Olodumare mewaa sile.
  2. ki ni apola oruko?
  3. Ki ni apola ise?
  4. Ki apola apejuwe?

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *