{"id":1681,"date":"2023-09-30T06:51:37","date_gmt":"2023-09-30T06:51:37","guid":{"rendered":"http:\/\/localhost\/ecole9ja\/?p=1681"},"modified":"2023-09-30T06:55:05","modified_gmt":"2023-09-30T06:55:05","slug":"all-weeks-jss-3-second-term-yoruba-notes","status":"publish","type":"post","link":"https:\/\/ecolebooks.com\/nigeria\/posts\/all-weeks-jss-3-second-term-yoruba-notes\/","title":{"rendered":"All Weeks &#8211; Jss 3 Second Term Yoruba Notes"},"content":{"rendered":"<p><strong> SIGMA TERM ILAANA ISE NI SAA KINNI FUN JSS3<\/strong><br \/>\n\t\t<strong>YORUBA LANGUAGE<br \/>\n<\/strong><\/p>\n<div>\n<table>\n<tbody>\n<tr>\n<td>OSE<\/td>\n<td>AKORI EKO<\/td>\n<\/tr>\n<tr>\n<td>1<\/td>\n<td>EDE \u2013 Ihun orisirisi awe gbolohun po lati di odidi gbolohun<br \/>\nASA \u2013 Awon asa to suyo lati inu awon ewi alohun<br \/>\nLITIRESO \u2013 Kika iwe literaso apileko ti ijoba yan<\/td>\n<\/tr>\n<tr>\n<td>2<\/td>\n<td>EDE \u2013 Atunyewo leta kiko (aigbefe)<br \/>\nASA \u2013 Awon oriisa ati eewo to suyo ninu litireso alohun ti a n fi oro inu won daa mo<br \/>\nLITIRESO \u2013 Ifaara lori litireso alohun<\/td>\n<\/tr>\n<tr>\n<td>3<\/td>\n<td>EDE \u2013 Iyato ti o wa laarin apola ati awe gbolohun Yoruba<br \/>\nASA \u2013 Itan isedale agbala aye<br \/>\nLITIRESO \u2013 Kika iwe litireso apileke ti ijoba yan<\/td>\n<\/tr>\n<tr>\n<td>4<\/td>\n<td>EDE \u2013 Aroka alalaye<br \/>\nASA \u2013 Owe ile Yoruba<br \/>\nLITIRESO \u2013 Oriki orile elerin, olokun, esin, onikoyi, olofa abbl.<\/td>\n<\/tr>\n<tr>\n<td>5<\/td>\n<td>EDE \u2013 Gbolohun Onibo<br \/>\nASA \u2013 Awon akanlo oro inu ede ati awujo Yoruba<br \/>\nLITIRESO \u2013 Kika iwe apileko ti ijoba yan<\/td>\n<\/tr>\n<tr>\n<td>6<\/td>\n<td>EDE \u2013 Akaye oloro wuuru \/ geere<br \/>\nASA \u2013 Awon orisa to suyo ninu litireso<br \/>\nLITIRESO \u2013 Kika iwe litireso ti ijoba yan<\/td>\n<\/tr>\n<tr>\n<td>7<\/td>\n<td>EDE \u2013 Akaye II (Ewi)<br \/>\nASA \u2013 Awon imole \/ orisa to suyo ninu litireso<br \/>\nLITIRESO \u2013 Kika iwe litireso ti ijoba yan<\/td>\n<\/tr>\n<tr>\n<td>8<\/td>\n<td>EDE \u2013 Atunyewo awon oro eyan<br \/>\nASA \u2013 Igbese igbeyawo ni ile Yoruba<br \/>\nLITIRESO \u2013 Kika iwe litireso ti ijoba yan<\/td>\n<\/tr>\n<tr>\n<td>9.<\/td>\n<td>EDE \u2013 Atunyewo awon oro aponle<br \/>\nASA \u2013 Ikomojade ni ile Yoruba<br \/>\nLITIRESO \u2013 Kika iwe apileko ti ijoba yan<\/td>\n<\/tr>\n<tr>\n<td>10<\/td>\n<td>Atunyewo ise lori ise saa yii lori ede, asa ati litireso<\/td>\n<\/tr>\n<tr>\n<td>11<\/td>\n<td>Idanwo ipari saa keji<\/td>\n<\/tr>\n<tr>\n<td>12<\/td>\n<td>Ifi \u2013 owo si iwe idanwo<\/td>\n<\/tr>\n<\/tbody>\n<\/table>\n<\/div>\n<p>\u00a0OSE KINNI<\/p>\n<h2>AKORI EKO: IHUN ORISIIRISII AWE GBOLOHUN PO DI ODIDI GBOLOHUN<br \/>\n<\/h2>\n<p>Kin \u2013 in \u2013 ni awe gbolohun?<br \/>\nAwe gbolohun ni ipede to ni oluwa ati ohun ti oluwa se<br \/>\nBi apeere:<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Ayinke mu omi<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Adepoju ti jeun<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Kasali je eba<br \/>\nAwe gbolohun le je ipede ti ko ni ju apola oro oruko ati apola kookoo lo. Apeere:<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Mo gba ebun naa<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Awon ni won wa<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Ade ti sun lanaa<br \/>\nMo \u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0gba \u00a0\u00a0\u00a0\u00a0ebun\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0naa<br \/>\napola \u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0apola \u00a0\u00a0\u00a0\u00a0oro \u2013 ise<br \/>\noro-oruko \u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0(verb phrase)<br \/>\n(Noun phrase)<\/p>\n<p>\u00a0Awe gbolohun le da duro ki o ni itumo. Apeere:<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Isola ati Ajani ra aso<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Omi ero naa mo<br \/>\nAwe gbolohun miiran le da duro ki maa ni itumo (awe gbolohun afarahe)<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Ti a ba ko ile<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Iba ke si mi<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Yala o wa tabi ko wa<br \/>\nAwe gbolohun le da duro bi odidi gbolohun, iru awe gbolohun bee ni a maa pe ni olori awe gbolohun. Apeere:<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Won gba<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Ade mo<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Iya omo ni <\/p>\n<p>\u00a0Itesiwaju ise lori awe gbolohun Abeke gbon<br \/>\nOpolopo awon gbolohun abode ni o le se ise awe gbolohun. Sugbon kii se gbogbo awe gbolohun lo le da duro bii gbolohun. Awon gbolohun isale wonyi le se ise awe gbolohun.<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Akanmu mu emu<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Apinke se iresi<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Ode pa igala<br \/>\nOrisii awe gbolohun (Types of clause)<br \/>\n1. Olori awe gbolohun (main clause): Eyi maa n da duro, o si maa n ni itumo ati paapaa o maa n sise odidi gbolohun. O ti ihun jo gbolohun abode tabi gbolohun eleyo oro-ise. Bi apeere:<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Awon omode feran iresi<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Aja Ogundeji ku\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Ise dara<br \/>\n2. Awe gbolohun afarahe (subordinate clause): Inu ihun gbolohun olopo oro-ise tabi gbolohun onibo ni a ti maa n ri awe gbolohun afarahe. Ninu gbolohun olopo oro \u2013 ise. Ipa kan yoo je gbolohun kikun nigba ti awon iyoku yoo je awe gbolohun afarahe ti ko ni itumo.<\/p>\n<p>\u00a0Orisii awe gbolohun afarahe<br \/>\ni. Awe gbolohun afarahe asapejuwe: ti ni atoka ibeere awe gbolohun yii. Awe gbolohun yii maa n tele oro oruko tabi apola oruko, o maa n je ki a mo nipa apejuwe nkan. Bi apeere<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Apinke ti o sun ti dide<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Aso Ankara ti mo ra dara<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Omoge ti mo n soro re niyi<br \/>\nii. Awe gbolohun afarahe asodoruko: &#8216;Pe&#8217; ni o maa n bere awe gbolohun yii, o le sise oluwa ati abo, o si maa n sise iso \u2013 doruko ninu ihun gbolohun. Apeere:<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Pe Olu ku ti mo gbo igbe ni mo fi ta<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Pe oju ka awon ole naa mo dun mo mi<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Oda mi loju pe omo naa ko le jale<br \/>\niii. Awe gbolohun afarahe asaponle: Awon oro atoka fun awe gbolohun yii n &#8216;nigba&#8217;, &#8216;ti&#8217;, &#8216;nitori ti&#8217; abbl. Awon oro \u2013 ise ti won maa n tele gbolohun ni won maa n pon. Bi apeere:<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Aja naa ku nigba ti oko ko lu u<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Emi yoo lo nisinsinyii ti mo gbo pe won de\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Ole naa ku nigba ti olopaa kolu won<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Obrinrin naa ku nitori ko ri owo le iwosan san<\/p>\n<p>\u00a0<br \/>\n\u00a0Iyato ti o wa laarin apola ati awe gbolohun (Differences between phrase and clause)<\/p>\n<div>\n<table>\n<tbody>\n<tr>\n<td>APOLA (PHRASE)<\/td>\n<td>AWE GBOLOHUN (CLAUSE)<\/td>\n<\/tr>\n<tr>\n<td>1. Apola kii ni oro \u2013 ise (ayafi ninu apola ise) Bi apeere:<br \/>\nIya Joke<br \/>\nAburo Badejo<br \/>\nNi Ibadan <\/td>\n<td>Awe gbolohun gbodo ni oro \u2013 ise ninu. Bi apeere:<br \/>\nKi o to sun<br \/>\nTi mo ra<br \/>\nMaa jo<\/td>\n<\/tr>\n<tr>\n<td>2. Apola ko le da duro ki o fun wan i itunmo kikun. Bi apeere:<br \/>\nNi abule odu<br \/>\nPapa asafa<br \/>\nAja ode<br \/>\nRin kemokemo<\/td>\n<td>Olori awe gbolohun le da duro ki o fun wan i itumo kikun. Bi apeere:<br \/>\nMo ti de<br \/>\nFijobi kan ilekun<br \/>\nAso Ankara dara<\/td>\n<\/tr>\n<tr>\n<td>3. Apola ko le daduro bi odidi gbolohun kikun. Bi apeere:<br \/>\nIwo ati emi<br \/>\nNi Osogbo<br \/>\nTi ile bo<\/td>\n<td>Olori awe gbolohun le da duro bii gbolohun kikun ti o ni itumo. Bi apeere:<br \/>\nObinrin yii burewa<br \/>\nEgungun ko korin<br \/>\nAdeojo kii ja<\/td>\n<\/tr>\n<\/tbody>\n<\/table>\n<\/div>\n<p>\u00a0<br \/>\n\u00a0<br \/>\n\u00a0<br \/>\n\u00a0<br \/>\n\u00a0<br \/>\n\u00a0OSE KEJI<\/p>\n<h2>AKORI EKO: ATUNYENWO LETA AIGBEFE (INFORMAL LETTER)<br \/>\n<\/h2>\n<p>IGBESE LETA AIGBEFE<br \/>\ni. Adiresi: \u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Adiresi akoleta (The writer&#8217;s address)<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Adiresi agbaleta (Receiver&#8217;s address)<br \/>\nii. Deeti (the day&#8217;s date)<br \/>\niii. Ikini ibeere (salutation)<br \/>\niv. Akole leta (the tittle \/ heading)<br \/>\nv. Koko leta (main content)<br \/>\nvi. Ikadii \/ ipari leta (conclusion)<\/p>\n<p>\u00a0Leta aigbagbefe \/ aigbefe (Formal letter)<br \/>\nEyi ni leta ti a maa n ko si awon eniyan ti won wa ni ipo kan ni ibi ise adani tabi si ajo ilu. Leta bayii kii se enikan pato, eni ti o je oga ni akoko naa ni yoo kaa. Idi niyi ti a kii fi ko oruko eniyan Kankan sii.<br \/>\nNinu leta aigbagbefe, ko si aaye fun iroyin tabi efe rara. Apeere iru leta yii ni a n ko si Ajele, Olofuu iwe iroyin, enwa ile \u2013 ise, oba, Alaga igbimo, Alaga ijoba ibile, oga ile \u2013 iwe ati akowe agba ibi ise ijoba apapo bii: oga agba ajo idanwo WAEC, NECO ati JAMB.<\/p>\n<p>\u00a0Igbese Leta aigbagbefe<br \/>\na. Adiresi: Adiresi meji nil eta aigbafe maa n ni<br \/>\ni. Adiresi akoleta: eyi yoo wa ni owo otun oke iwe, deeti ojo ti a koi we yoo tele ni isale.<br \/>\nii. Adiresi agbaleta: Eyi yoo wan i owo osi ni ila ti o tele deeti. Apeere:<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Federal Government College,<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Ilorin,<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Kwara State.<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a02<sup>nd<\/sup> February, 2015.<br \/>\nOlotuu,<br \/>\nIwe Iroyin Alaroye<br \/>\n34, Agbabiaka Street,<br \/>\nLagos.<\/p>\n<p>\u00a0<br \/>\n\u00a0<br \/>\n\u00a0b. Ikini Ibeere: Apa osi ni ila ta tele adiresi agbaleta ni akoleta yoo ko ikini akoko si leta n la ni o gbodo fi bere yoo si fi ami koma kadii re. apeere:<\/p>\n<p>\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Olotuu,<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Oga ile \u2013 iwe,<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Akowe agba, abbl<br \/>\nd. Akole leta aigbefe: Ila ti o tele ila ikini ni akoleta yoo ko akole leta re si ni aarin iwe yoo si fara sidii re ti o ba ti leta kekere ko o tabi ki o ko o nil eta nla lai fala si nidii. Apeere:<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Ayeye Ojo Omiran Orile \u2013 Ede Naijiria.<br \/>\ne. Ara leta: Aaye ko si fun iforo jewoo tabi awada ninu leta yii, ohun ti a ba fe so ni pato ni a gbodo gbe kale. Ti o ba si je esi iwe ti akoleta ko gba tele tabi ko ni a gbodo fihan.<br \/>\ne. Ikadii\/ipari: owo otun ni isale iwe ni akoleta yoo ko igunle leta re si, oruko meji (iyen ni oruko akoleta ati obi re) ni o gbodo ko pelu ami idanuduro ni ipari. Apeere:<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Emi ni,<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Biodun Agbabiaka.<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0(signature) <\/p>\n<p>\u00a0Ise Asetilewa<br \/>\nKo leta si oluko agba ni ile \u2013 iwe re lati gba aaye fun ose kan nitori ailera re. <\/p>\n<p>\u00a0<\/p>\n<h2>AWON ORISA ILE YORUBA ATI AWON EEWO WON<br \/>\n<\/h2>\n<p>Eniyan ni awon orisa wonyii ni igba aye won (ifa, ogun, esu, sango, oya, osun abbl). Sugbon nitori akitiyan ati ise akoni won nigba ti won wa laye ni awon Yoruba se so won di orisa akunlebo. Paapaa julo, iru iku ti won ku ati ise won leyin iku won so won di eniyan oto laarin awon omo adari ti n irun.<br \/>\n1. Ifa tabi Orunmila: Orunmila ni awon Yoruba pe ni Agbonmiregun, ayanmo tabi kadara eniyan ko seyin re, ko si ohunkohun ti eniyan le se laye ti ko ni mo nipa re. orisa yii je okan gboogi ninu awon ibe ti awon Yoruba ka si lopolopo, ifa dide (pelu ikin tabi opole) ni o maa n so ayanmo tabi ese \u2013 n \u2013 taye omo. Litireso atenudenu ti a maa n lo ti a ba n da ifa tabi se odun ifa ni a n pe ni iyere ifa, amaa n sun uyere ifa lati fi yin tabi ki ifa ni.<br \/>\nOunje Ifa niwonyii:<\/p>\n<ol>\n<li>\n<div>Adie\n<\/div>\n<\/li>\n<li>\n<div>Ewure\n<\/div>\n<\/li>\n<li>\n<div>Eyele\n<\/div>\n<\/li>\n<li>\n<div>Igbin\n<\/div>\n<\/li>\n<li>\n<div>Eja\n<\/div>\n<\/li>\n<li>\n<div>Epo pupa abbl.\n<\/div>\n<\/li>\n<\/ol>\n<p>Eewo Ifa<br \/>\nAwon olusin re ko gbogbo je iu titun saaju odun ijesu.<br \/>\n2. Ogun:Agbe ni ogun nigba aye re, o si je akikanju nigba ti o wa laye. Ni aye ode \u2013 oni gbogbo awon ohun elo tabi irinse ti o ba je mo irin ni won maa n boo gun. Ijala ni ewi ti ab maa ri sun nibi odun ogun tabi ni ibi isipa ode.<br \/>\nOunje Ogun niwonyii:<\/p>\n<ol>\n<li>\n<div>Aja\n<\/div>\n<\/li>\n<li>\n<div>Iyan\n<\/div>\n<\/li>\n<li>\n<div>Emu\n<\/div>\n<\/li>\n<li>\n<div>Esun isu abbl\n<\/div>\n<\/li>\n<\/ol>\n<p>Eewo Ogun<br \/>\nGbigbe ofifo agbe tabi akeregbe emu duro ni ojubo re.<br \/>\n3. Sango: Oba ni Sango je ni igba aye re ni ode aye, o si je alagbara pupo ti o fi je pe ko si ogun ti oba Sango ko le koju nigba aye re, agbara re po to bee ti ina fi maa n yo lenu re nigba ti a ba n binu, gbogbo awon eniyan si maa n beru re. Iyawo meta ni Sango ni, awon no Osun, Oba ati Oya si jee aya re.<br \/>\nIlu dite mo Sango nitori asilo agbara re, o fi ilu sile, Oya nikan lo si tele. Oya wole ni IRA o si di odo ti a mo si odo Oya. Sango pokun so nidii igi AYAN ni koso.<br \/>\nAwon elegun Sango maa n di irun ori won bii ti obinrin, aworo Sango ni a n pen i Baba Mogba.<br \/>\nOunje Sango niwonyii:<\/p>\n<ol>\n<li>\n<div>Orogbo\n<\/div>\n<\/li>\n<li>\n<div>Agbo funfun abbl\n<\/div>\n<\/li>\n<\/ol>\n<p>\u00a0<br \/>\n\u00a04. ESU: Ilu ile \u2013 ife ni esu n gbe nigba aye re, o je oburewa, eniyan ESU fi igba kan koi se, ifa dida (awo) ni idi orunmila. O je eni to gbonu \u2013 gboya, ko si eni ti ko le ko loju, gbogbo ebo ti ESU bag be lo maa n fi (da). Orunmila maa n ran \u2013an lo si odo Eledumare ni orun, idi niyi ti won fi n pe e ni &#8220;Agbayegborun&#8221;.<br \/>\nESU maa n gba ija onija kann; a sit un maa n da ija sile laarin eniyan meji nigba aye re. igboju, akikanju ati ebo ti o n gbe to si n da, ni o je ki awon eniyan so di orisa leyin iku re.<br \/>\nOunje Esu ni wonyii:<br \/>\nGbogbo nkan tie nu n je ni ounje ESU<br \/>\nEewo Esu<br \/>\nTita adin si oju re<br \/>\nOWE ILE YORUBA<br \/>\nOwe ni akojopo oro ti o kun fun ogbon, imo yinle ati iriri awon agba. Owe yii ni awon agba maa n pa lati fi yanju oro to ba ta koko. Ni ile Yoruba, omode kii pa owe niwaju agbalagba lai ma toro iyonda lowo won, omode naa yoo so pe &#8221; tooto o se bi owe&#8221;, awon agba ti o wan i ijokoo yoo si dahun pe &#8220;wa a ri omiran pa&#8221;.<br \/>\nOna ti owe gba waye<br \/>\n1. Akiyesi sise: Awo agba maa n sakiyesi awon isele ti o n sele ni ayika won lati seda owe. Bi apeere: Bi a ba gba ile, gba ita, aatan la n da a si.<\/p>\n<p>\u00a02. Esin: Opolopo awon owe ti awon baba n la wa maa n pa ni won waye nipase esin ibile won. Apeere: Aigbofa la n woke, ifa kan ko sin i para.<\/p>\n<p>\u00a03. Asa: inu okan \u2013 o \u2013 jokan asa Yoruba ni awon agba ti seda opolopo awon owe. Bi apeere: Ile la n wo, ki a to so omo loruko.<\/p>\n<p>\u00a0ISORI OWE<br \/>\nOna marun \u2013 un ni isori owe pin si, awon nii:<\/p>\n<ol>\n<li>\n<div>Owe fun imoran\n<\/div>\n<\/li>\n<li>\n<div>Owe fun alaye\n<\/div>\n<\/li>\n<li>\n<div>Owe fun ibawi\n<\/div>\n<\/li>\n<li>\n<div>Owe fun ikilo\n<\/div>\n<\/li>\n<li>\n<div>Owo fun isiri\n<\/div>\n<\/li>\n<\/ol>\n<p>1. OWE FUN IMORAN: ti oro ba doju ru, awon agba n a maa n to lo fun imoran to ba ye. Ni opolopo igba, owe ni won maa n pa lati to eniyan sona. Bi apeere:<br \/>\na. Ile ti ko toju eni su, okunkun re maa n soro o rin.<br \/>\nb. Alagemo ti bimo re tan, aimojo ku sowo omo alagemo<br \/>\nd.Igi ganganran ma gun ni loju, okeere lati n wo o<br \/>\ne. Oju mewaa ko ju oju eni<br \/>\ne. Falana gbo tire, tara eni la n gbo<\/p>\n<p>\u00a02. OWE FUN ALAYE: Awon owe kan wa ti awon agba fi maa n salaye oro okan won fun eni ti won ba a ba soro. Apeere:<br \/>\na. Ki ile to pa osika, ohun rere a ti baje<br \/>\nb. A ku to eni bog be ki a maa to oro ba nii so.<br \/>\nd. Agba to n sare ni aarin oja ni bi nkan ko le, a je pe o n le nkan<br \/>\ne. Agbatan ni a n gba ole, bi a ba da so fun ole a paa laro, bi a ba la ole nija, a sin-in dele.<br \/>\ne. Ara aimuole le n ko je ki a mop e ologbo n sode.<br \/>\n3. OWE FUN IBAWI: Bi enikan ba n huwa ti ko dara, owe awon agba fi ma n ba iru eni bee wi. Apeere:<br \/>\na. Bi omode ba n se bi omode, agba o si se bi agba.<br \/>\nb. Aja kii roro ko so oju lo meji<br \/>\nd. Afase gbe ojo n tun ara re je<br \/>\ne. Adiye funfun ko mo ara re la gba<br \/>\ne. A kii roe ran enu lori, ki a tun maa fi ese wa ire nile<\/p>\n<p>\u00a04. OWE FUN IKILO: Ti a ba se akiyesi pe enikan wa ninu ewu ti oun gan-an ko mo tabi fura, awon agba maa n pa owe lati kiilo fun pe ki osora. Apeere:<br \/>\na. Bi eti ko ba gbo yinkin, inu kii baje<br \/>\nb. Ise ni oogun i se<br \/>\nd. Alaso ola kii ba elepo sere<br \/>\ne. Agboju logun fi ara re fun osi ta<br \/>\ne. Ese gin nile origafe, arijose ku, a ko ri enikan<\/p>\n<p>\u00a05. OWE FUN ISIRI: A maa n lo awon owe yii lati tu eniyan ti o wa ninu ibanuje ninu tabi eni ti o ti so ireti nu oro aye re. Bi apeere:<br \/>\na. Igbeyin ni alayo n ta<br \/>\nb. Kii buru titi ki o ma ku enikan mo ni, eni ti yoo kun i a komo<br \/>\nd. Ajeji owo kan ko gberu dele<br \/>\ne. Ise kii se ni, ki omo eni maa dagba<br \/>\ne. Pipe ni yoo ope, akololo a pe baba<\/p>\n<p>\u00a0Ise Asetilewa<br \/>\nSe alaaye ati itunmo owe yii &#8220;Adiye funfun ko mo ara re lagba&#8221;.<\/p>\n<p>\u00a0OSE KETA<\/p>\n<h2>AKORI EKO: EYAN<br \/>\n<\/h2>\n<p>Eyan ni awon wunren (oro) ti a fi n yan oro \u2013 oruko (noun) tai apola oruko (Noun phrase) ninu gbolohun tabi ninu isori. Bi apeere:<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Iwe tuntun ni a f era<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Aso ala ni mo wo<br \/>\n&#8216;Tuntun&#8217; ati &#8216;ala&#8217; ti a fa ila si ninu gbolohun oke yii ni oro eyon ti o n se afikun itumo fun oro oruko ti won n yan.<br \/>\nOrisii eyan<\/p>\n<ol>\n<li>\n<div>Eyan asapejuwe\n<\/div>\n<\/li>\n<li>\n<div>Eyan ajoruko\n<\/div>\n<\/li>\n<li>\n<div>Eyan asafihan\n<\/div>\n<\/li>\n<li>\n<div>Eyan asonka\n<\/div>\n<\/li>\n<li>\n<div>Eyan alawe gbolohun asapejuwe\n<\/div>\n<\/li>\n<\/ol>\n<p>1. EYAN ASAPEJUWE: Ise eyan yii ni lati pon oro oruko lona ti yoo fi ye ni tekeyeke. Oro apejuwe pin si ona meji, awon ni:<br \/>\na. Oro apejuwe ipile: iwonyi ni awon oro bii; pupa, rere, dudu, kekere, nla, funfun abbl.<br \/>\nApeere lilo ni gbolohun<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Nike je omo rere<br \/>\n\t\t\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Amala dudu ni mo feran<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Ounje kekere ko le yo mi<\/p>\n<p>\u00a02. EYAN AJORUKO: Eyi ni oro oruko tabi oro aropo oruko ti a lo lati yan oro \u2013 oruko miiran. Bi apeere:\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Dokita oyinbo ni mo fe ri<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Abule odu ni Busola n gbe<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Ewure Torera ni ole ji<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Ile wa ni a n lo<\/p>\n<p>\u00a03. EYAN ASOFIHAN: Eyi maa n toka si ohun ti a n soro nipa re. Weren tabi oro atoka re ni: wonyen, yii, yen, ati wonyi. Apeere:<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Oro yen dun mo won ninu<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Ile yii ga ju<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Pasito gan-an ni mo fe ri <\/p>\n<p>\u00a0<br \/>\n\u00a04. EYAN ASONKA: Irufe eyan yii nii se pelu onka, o maa n toka si iye nkan ninu gbolohun. Bi apeere:<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Omode meta n sere<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Oko kan ni oluwa yan fun obinrin<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Akara mefa ni mo je<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Ile marun-un ni baba \u2013 agba ko\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0<\/p>\n<p>\u00a05. EYAN ALAWE GBOLOHUN: &#8216;ti&#8217; ni wunren atoka awe gbolohun asapejuwe. Ise re ni lati fi itunmo kun itumo oro \u2013 oruko ninu gbolohun. Bi apeere:<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Gele ti a ran i ana wun mi<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Ile ti mo ko ti kere ju<br \/>\n\u00a0\u00a0\u00a0\u00a0Baba ti o n soro re lo n bo yii<\/p>\n<p>\u00a0Ise Amutilewa<br \/>\nToka orisii eyan ti o wa ninu gbolohun isale wonyii, ki o si fa ila si nidii.<br \/>\n1. Oko wonyen ni mo fe ta<br \/>\n2. Iyawo ti mo ni dara<br \/>\n3. Eran dindin wu mi je<br \/>\n4. Aso aran ni iya agba wo<br \/>\n5. Oke meje ni a gbodo gunde ibe<br \/>\n6. Iyana \u2013 Ipaja ti daru<br \/>\n7. Oke nlanla wan i Efon Alaye<\/p>\n<p>\u00a0<\/p>\n<h3>ASA IGBEYAWO<br \/>\n<\/h3>\n<p>Igbeyawo ni isopo okunrin ati obinrin lati di took-taya ni ibamu pelu asa ati ilana isedale ile Yoruba.<br \/>\nKoko mefa pataki ti o n gbe igbeyawo ni<\/p>\n<ol>\n<li>\n<div>Ifesona (courtship)\n<\/div>\n<\/li>\n<li>\n<div>Ifayaran (perseverance)\n<\/div>\n<\/li>\n<li>\n<div>Suuru (patience)\n<\/div>\n<\/li>\n<li>\n<div>Ipamora (tolerance)\n<\/div>\n<\/li>\n<li>\n<div>Igbora-eni-ye (understanding)\n<\/div>\n<\/li>\n<li>\n<div>Ife aisetan (unconditional love)\n<\/div>\n<\/li>\n<\/ol>\n<p>\u00a0<\/p>\n<h3>IGBESE IGBEYAWO<br \/>\n<\/h3>\n<ol>\n<li>\n<div>Ifojusode\n<\/div>\n<\/li>\n<li>\n<div>Iwaadi\n<\/div>\n<\/li>\n<li>\n<div>Alarina\n<\/div>\n<\/li>\n<li>\n<div>Isihun \/ ijohen\n<\/div>\n<\/li>\n<li>\n<div>Itoro\n<\/div>\n<\/li>\n<li>\n<div>Baba gbo, iya gbo\n<\/div>\n<\/li>\n<li>\n<div>Idana\n<\/div>\n<\/li>\n<li>\n<div>Ipalemo\n<\/div>\n<\/li>\n<li>\n<div>Ifa iyawo\n<\/div>\n<\/li>\n<li>\n<div>Ojo igbeyawo\n<\/div>\n<\/li>\n<li>\n<div>Ese iyawo wiwe\n<\/div>\n<\/li>\n<li>\n<div>Ibale\n<\/div>\n<\/li>\n<li>\n<div>Ikorun\n<\/div>\n<\/li>\n<li>\n<div>Ojo keje\n<\/div>\n<\/li>\n<\/ol>\n<h3>IRO KONSONANTI<br \/>\n<\/h3>\n<p>Iro konsonanti ni awon iro ti idiwo maa n wa fun jijade eemi ni kaa enu nigba ti a ba n pe won. Ona meta ni a le gba mo iru iro konsonanti ti an pe. Awon ona wonyii ni:<\/p>\n<ol>\n<li>\n<div>Ibi isenupe\n<\/div>\n<\/li>\n<li>\n<div>Ona isenupe\n<\/div>\n<\/li>\n<li>\n<div>Abuda iro konsonanti\n<\/div>\n<\/li>\n<\/ol>\n<p>A. IBI ISENUPE: orisii mejo ni ibi isenupe iro konsonati ede Yoruba. Awon ibi isenupe wonyi bere lati ete lo si ibi otooto orule enu titi lo dopin. Awon naa ni:<br \/>\n(i) Afetepe<br \/>\n(ii) Afeyinfetepe<br \/>\n(iii) Aferigipe<br \/>\n(iv) Afajaferigipe<br \/>\n(v) Afajape<br \/>\n(vi) Afafasepe<br \/>\n(vii) Afafase fetepe<br \/>\n(viii) Afi-tan-an-na-pe<\/p>\n<p>\u00a0B. ONA ISENUPE: orisii meje ni awon ana isenupe iro konsonanti awon ni won wa lori bi afefe eemi ti maa n jade nigba ti a ba n pe iro tabi soro. Awon ni:<br \/>\ni. Asenupe<br \/>\nii. Afunnupe<br \/>\niii. Asesi<br \/>\niv. Aranmupe<br \/>\nv. Arehon<br \/>\nvi. Afegbe enupe<br \/>\nvii. Aseesetan<\/p>\n<p>\u00a0D. ABUDA IRO KONSINANTI: ti a ba fe se apejuwe iro konsonanti ni ilana abuda, a ni lati wa awon ilana yii:<br \/>\ni. Orisun eemi (eemi amisinu tabi eemi amisode)<br \/>\nii. Ipo ti alafo tan-an-na wa (ipo imi tabi ipo ikun)<br \/>\niii. Ipo afase (boya afase wa sile tabi o gbera soke)<br \/>\niv. Irufe afipe ti a lo (yala afipe asunsi tabi akanmole)<br \/>\nv. Irufe idiwo ti o wa fun eemi (boya ona se patapata tabi o si sile die)<\/p>\n<p>\t\t\u00a0<\/p>\n","protected":false},"excerpt":{"rendered":"<p>SIGMA TERM ILAANA ISE NI SAA KINNI FUN JSS3 YORUBA LANGUAGE OSE AKORI EKO 1&#8230;<\/p>\n","protected":false},"author":1,"featured_media":0,"comment_status":"open","ping_status":"open","sticky":false,"template":"","format":"standard","meta":{"footnotes":""},"categories":[1,154],"tags":[],"class_list":["post-1681","post","type-post","status-publish","format-standard","hentry","category-posts","category-second-term-jss3-yoruba"],"aioseo_notices":[],"_links":{"self":[{"href":"https:\/\/ecolebooks.com\/nigeria\/wp-json\/wp\/v2\/posts\/1681","targetHints":{"allow":["GET"]}}],"collection":[{"href":"https:\/\/ecolebooks.com\/nigeria\/wp-json\/wp\/v2\/posts"}],"about":[{"href":"https:\/\/ecolebooks.com\/nigeria\/wp-json\/wp\/v2\/types\/post"}],"author":[{"embeddable":true,"href":"https:\/\/ecolebooks.com\/nigeria\/wp-json\/wp\/v2\/users\/1"}],"replies":[{"embeddable":true,"href":"https:\/\/ecolebooks.com\/nigeria\/wp-json\/wp\/v2\/comments?post=1681"}],"version-history":[{"count":1,"href":"https:\/\/ecolebooks.com\/nigeria\/wp-json\/wp\/v2\/posts\/1681\/revisions"}],"predecessor-version":[{"id":1682,"href":"https:\/\/ecolebooks.com\/nigeria\/wp-json\/wp\/v2\/posts\/1681\/revisions\/1682"}],"wp:attachment":[{"href":"https:\/\/ecolebooks.com\/nigeria\/wp-json\/wp\/v2\/media?parent=1681"}],"wp:term":[{"taxonomy":"category","embeddable":true,"href":"https:\/\/ecolebooks.com\/nigeria\/wp-json\/wp\/v2\/categories?post=1681"},{"taxonomy":"post_tag","embeddable":true,"href":"https:\/\/ecolebooks.com\/nigeria\/wp-json\/wp\/v2\/tags?post=1681"}],"curies":[{"name":"wp","href":"https:\/\/api.w.org\/{rel}","templated":true}]}}