ISE-:EDE YORUBA                 CLASS: SS1
ILANA ISE OSOOSE FUN SAA KETA
Ose:

  1. EDE:    Isori oro;Oro Oruko: Oriki, Orisii Oruko, Ise Oro-Oruko ninu Gbolohun

    ASA:    Asa- Asa Isomoloruko: Amutorunwa, abiso, inagije abbl.
    LIT:    Itupale ewi apileko. Amuye ewi, koko ewi abbl.

  2. EDE:    Oro Aropo-Oruko

    ASA:    Ipolowo Oja: iwulo ati pataki, orisii ona ti a n gba polowo oja.
    LIT:    Itupale iwe asayan ti ijoba yan. WAEC/NECO.

  3. EDE:    Oro-Ise: Agbabo, Alaigbabo, elela, Alailela.

    ASA:    Ere Idaraya: Ere Osupa, aojoojumo, Ita gbangba, abele.
    LIT:    Itupale iwe asayan ti ijoba yan. WAEC/NECO.

  4. EDE:    Onka; Egbaa titi de egbaa-run-un(2,000-10,000)-Ilana onkaye lati     

    egbaa-egbaa-run.
    ASA:    Ere Omode, Odo, Giripa ati agba. Ofin to de ere kookan, ohun elo
    ere kookan ati anfaani ere kookan
    LIT:     Itupale iwe asayan ti ijoba yan. WAEC/NECO.

  5. EDE:    Aroko Ajemo Isipaya

ASA:    Ere idaraya-;Ere igbalode. Ayipada ti o ti de ba ere idaraya abinibi
LIT:    Itupale iwe asayan ti ijoba yan. WAEC/NECO.

  1. EDE:    isori Oro: Oro-Aropo Afarajoruko, Oro Apejuwe. Lilo won ni

    gbolohun.
    ASA:    Owo Yiya: Ohun ti o le sun eniyan de ibi owo yia, ona ti a n gba ya
    owo,
    ipa ti onigbowo n ko ninu eto iyawo, anfaani ati aleebu owo yiya.
    LIT:    Ewi Alohun gege bi orison ironu Yoruba: Ese Ifa, Alo Apagbe.

  2. EDE:    Itupale gbolohun oniponna: oriki, Dida gbolohun oniponna mo,

    ASA:    Ona ti a n gba gba gbese – osomaalo,elemun-un. Ipa ti awon elesin
    ati ijoye n ko ninu gbigba gbese.
    LIT:    Ewi Alohun gege bi orison ironu Yoruba: Ofo, Ogede, Itan riro

  3. EDE:    Aroko asariyanjiyan: Ilana kiko aroko asariyanjiyan, Awon ori-oro ti

    o je mo aroko asariiyanjiyan, ijiroro lori ori-oro ti o je mo aroko asariiyanjiyan, kiko ilapa ero
    ASA:    Asa Isinku ni Ile Yoruba: Orisiirisii ona ti a n gba sin oku, oku omode, oku agba, itufo, itoju oku ati sisin oku agba sinu ile
    LIT:    Ewi Alohun alohun ti o je mo asa isinku, oku pipe, ijala, rara, Olele, Ege, Iremoje.

  4. EDE:    Akaye oloro geere –kika ayoka ni akaye, didahun ibeere ti o wa labe     ayoka. Awon oro ti o takoko ninu ayoka.

ASA:    Asa isinku ni ileYoruba: Isinku oba, isinku abami eniyan.
LIT:    Akojopo awon owe ti o jeyo lati inu iwe Asayan ewi ti ajo WAEC/NECO

  1. EDE:    Aroko; Leta kiko-Gbefe, ilana fun leta gbefe

    ASA:    Oku sise, sise oro oku.
    LIT:    Itupale iwe asayan ti ijoba yan. WAEC/NECO.

  2. EDE:    Atunyewo eko lori ise saa yii ninu ede, asa, ati litireso.
  3.     Atunyewo idanwo lori ise odun yii ninu ede, asa ati litirso.

     
     
     IWE ITOKASI

  4. Imo, Ede, Asa Ati Litireso. S.Y Adewoyin
  5. Eto Iro ati Girama fun Sekondiri Agba. Folarin Olatubosun.
  6. Akojopo Alo Apagbe: Amoo A. (WAEC).
  7. Oriki Orile Metadinlogbon: Babalola, A (WAEC).
  8. Iremoje Ere Isipa Ode: Ajuwon B. (WAEC).
  9. Igbeyin Lalayonta: Ajewole O. (WAEC).
  10. Iya Atata: Fadiya, O. (WAEC).
  11. Ore Mi: Aderibigbe, M. (WAEC).
  12. Egun Ori Ikunle: Lasunkanmi Tela. (NECO).
  13. Omo Ti A Fise Wo: Ojukorola Oluwadamilare. (NECO).
  14. Ewi Igbalode: Taiwo Olunlade. (NECO).

    

          
OSE KINNI
    
ORO- ORUKO
– oriki
– orisiirisii oro oruko.
– ise ti oro oruko n se ninu gbolohun.
– lilo oro oruko ninu gbolohun.
Oro –oruko ni awon oro ti won le da duro nipo oluwa, abo tabi eyan ninu gbolohun. AP.
    Baba ko ebe.
    Tolu fo aso.
    Mama se isu ewura.

 EYA ORO ORUKO.

  1. ORUKO ENIYAN : -Oro oruko le je oruko eniyan, eyi ni oruko ti o n toka si ohun ti o je eniyan. Ap

    -Rotimi
            – Dele
            -Ahmed
            – Dokita
            – Iyalaje…abbl
    2. ORO-ORUKO ALAISEEYAN:- Eyi ni oruko to n toka si awon nnkan ti kii se eniyan AP. okuta, iwe, ewure, omi, iyanrin, bata abbl.
    3.    Oro-oruko le je ohun elemi : – Eyi je oruko nnkan ti won ni emi bii eniyan tabi eranko.apaja,eniyan,esin,maalu,alangba,okunrin.abbl.
    4.     Oro-oruko le je ohun alailemii: – Eyi ni awon nkan ti ko ni emi. ap iwe, ile, bata, ewe, igi: abbl.
    5.     Oro-oruko le je ohun aridimu:- Eyi ni awon ohun ti a le fi oju ri tabi fi owo kan. apewa, eja,isu, tabili, sokoto, aga, ewedu, abbl.
    6.     Oro-oruko le je oruko ibikan :- Eyi ni awon oro oruko ti a le fi ibo se ibeere won. Ap ibo lo n lo? Osodi, Meka, Soosi.
    7.     Oro-oruko le je ohun afoyemo:- Eyi ni awon ohun ti a ko le fojuri sugbon ti a le mo nipa ero opolo. Ap ogbon, ilera, ero, ife, alaafia, igbadun, wahala, imo.
    8.     Oro-oruko le je aseeka : – Eyi ni o n toka si ohun ti a le ka Ap. Ile, ilu, eniyan, iwe, tatapupu.
    9.     Oro-oruko le je alaiseeka : – Eyi ni o n tokasi awon ohun ti koseeka Ap Iyanrin, epo, omi, afefe, gaari, irun.
    10.     Oro-oruko le je oruko igba:- Eyi ni oro ti a le lo lati toka si igba ti nnkan sele han. Ap Aaro, ana, odun, irole, oni, ola, ijeta

     ISE TI ORO-ORUKO N SE NINU GBOLOHUN.
    Ona meta pataki ni a le gba lo oro-oruko ninu gbolohun, o le sise:
    i.Oluwa,
    ii. abo
    iii. eyan.

     OLUWA: ni eni tabi ohun ti o se nnkan ninu gbolohun.
    Baba ko ebe.
         Bola fo aso.

     ABO:ni eni tabi ohun ti a se nnkan si, ap
    Mama se obe
         Bolu ko leta.

     EYAN; ni o maa n se afikun itunmo fun oro-oruko ap
         Mama se eja yiyan.
         Bola ka iwe mewaa.
        Daruko orisii ere idaraya merin ti o mo.

     IWE AKATILEWA
    Adewoyin S.Y (2014) Imo, Ede, Asa Ati Litireso fun ile Sekondiri Agba Corpromutt Publihers Nig Ltd Oju iwe 137-141.

     ASA
    ORISII ORUKO TI A LE SO OMO NILE YORUBA
    Akoonu
    Oruko se Pataki ni ile Yoruba, awon Yoruba kii sii deede fun omo ni oruko, awon oruko Yoruba maa n ni itumo. Idi niyi ti awon agba fi maa n se akiyesi ipo ti omo ba gba waye, Ipo ti ebi wa, esin idile baba ki won to fun omo ni oruko, Yoruba ni ile laawo ki a to so omo ni oruko.
    Eyi ni orisii oruko ti a ni ni ile Yoruba.
    Oruko amutorunwa
    ii. Oruko abiku
    iii. Oruko Inagije
    iv. Oruko abiso
    Oruko amutorunwa:- ni oruko ti a fun omo nipa sise akiyesi ona ara ti o gba wa si aye tabi isesi re nigba ti a bii. Apeere:

     Oruko amutorunwa:-
    Ige                Omo ti o mu ese waye
    Aina                Omobinrin ti o gbe ibi korun.
    Ojo                Omokunrin ti o gbe ibi korun.
    Oke                Omo ti o di ara re sinu apo ibi wa si aye epo tutu ni won maa
    n ta si ara apo naa, ki o to le tu.
    Oke                Omo ti o maa n daku ti won ba n fun ni ounje ni idubule.
    Dada                Omo ti irun ori re ta koko.
    Ilori                Omo ti iya re ko se nnkan osu ti o fi loyun
    Oni                Omo ti won bi sile to n kigbe laisinmi
    Babarinsa            Omo ti baba re ku ni kete ti won bii.
    Abiona                

     Oruko abiku: Oruko ti a fun omo ti o maa n ku, ti a sit un pada wa saye.
    Won maa n fun won ni oruko bii ebe tabi epe ki won le duro.ap
    Oruko                Itumo
    Durojaye    –    Ki o duro ni ile aye je igbadun
    Rotimi        –    Duro ti mi, ma se fi mi sile.
    Malomo    –    Duro si aye, ma pada si orun mo
    Kosoko    –    Ko si oko ti a o fi sin oku re mo
    Kasimaawoo    –    Ki a si maa wo boya yoo tun ku tabi ye.
    Bamitale    –    Duro ti mi di ojo ale
    Aja        –    Iwo ko ye ni eni ti a le fun ni oruko eniyan mo afi aja.

     Oruko Inagije:- oruko atowoda ti a fi eniyan tabi ti eeyan fun ara re lati fi se aponle tabi apejuwe irisi tabi iwa re ap.
    Eyinafe:     Eni tie yin re funfun ti o si gbafe.
    Ajisafe:     Eni to feran afe ni owuro ti gbogbo eeyan ba n sise
    Peleyeju:     Eni to ko ila pele, ti ila oju naa si ye e gan-an.
    Oginni:     Eni ti o maa n roar n tele ginniginni.

     Oruko abiso: eyi ni awon oruko ti o n tokasi ipo idile tabi obi omo saaju tabi asiko ti a bii.
    Apeere oruko to n tokasi ipo tabi esin idile.

     Ipo                    Oruko abiso
    Oba                     Adebisi, Adegorite, Adegoroye, Adesoji, Adegbite, Adeyefa.
    Eleegun                Ojewunmi, Ojeniyi, Eegunjo bi
    Jagunjagun                Akintola, Akinkunmi, Akindele
    Onisona                Onajide, Olonade
    Elesin Ifa                Fayemi, Faleye, Awobiyi, Awotunde
    Onisango                Sangobunmi, Sangodele
    Orisa Oko/Idobatala            Efunjoke, Opakunle, Soyinka.
    Orisa Ogun                Ogunyemi, Ogunbiyi, Odetola.

     Oruko to n toka si ipo obi saaju tabi ni akoko ti won bii.
    Oruko                        Itumo
    Ekundayo                    Ibanuje ati ekun ti o wa ninu ebi di ayo.

     Olabode                    Ola to ti lo ninu ebi tun ti pada de.

     Tokunbo            Omo ti won bi si Ilu oyinbo tabi ile
    okeere ti won gbe wa ile.

     IGBELEWON

    1. Daruko ohun marun-un ninu ohun elo isomoloruko ki o si salaye bi won se n lo won.
    2. Ko apeere oruko marun-un ninu oruko ile Yoruba pelu alaye.

     IWE AKATILEWA
    Adewoyin S.Y (2014) Imo, Ede, Asa Ati Litireso fun ile Sekondiri Agba Corpromutt Publihers Nig Ltd Oju iwe 101-119.

     ITUPALE EWI APILEKO
    Ewi je awon akojopo ijinle oro ti a ko sile tabi eyi ti a n ke pelu ohun didun. A maa n ko ni ila si ila ni. A ki i ko o bi aroko. ni abe ewi ni ati maa n se agbeyewo akanlo ede ayaworan akanlo ede ayaworan tumo si awon eroja ti o maa n mu ki ewi dun daadaa. Apeere won ni: awitunwi, asorege/ asodun, owe, akanlo ede, akude gbolohun, afiwe.
    AWITUNWI: ninu awitun ni a ti maa n tenumo oro ju eekan lo. A le pe oro bi eemeji tabi eemeta. Awiunwi eleyoro oro wa, akude gbolohun wa
    ASOREGE/ASODUN: eyi ni ki a maa pon nnkan ju bi o se ye lo. Won le wi pe, a se inawo ti aye gbo orun si mo. ounje po bi ile bi eni. Eniyan po nibe bi yanrin eti okun.
    OWE: Yoruba bo won ni owe lesin oro, oro lesin owe, bo oro ba sonu owe ni a fi maa n wa. owe je ona ti a fi maa n mo bi eniyan so gbo ede Yoruba to.
    AKANLO EDE: Yoruba ki i fi gbogbo enu soro. Won maa n pe oro so ni. Awon agba le wi pe o feraku. Itumo eyi ni wi pe onitohun ti loyun. Baba agba tit a teru nipa tumo si wi pe baba agba ti ku.
    IFORODARA: ninu iforodara ni won ti maa n fi oro da lorisiirisii. Fun apeere:
    Aso funfun ma funfun ni funfun
    O ti le funfun ni funfun ki funfun ju.

     Yaya ki ba ti je eran oya
    Bi ki i ba se iya Yaya ti n tae ran oya ni Moniya.

     IGBELEWON
    Se itupale asayan iwe ewi kin-in-ni ti ijoba yan.

      APAPO IGBELEWON.

    1. Ko apeere oro oruko mewaa sile
    2. Ko apeere oro-oruko marun fun oruko abiso, amutoruwa, inagije.
    3. Ko apeere akanlo ede ayaworan mefa.

     
     ISE AMURELE.

    1. Salako gbe igunnu. Ew ni oro oruko ti o n se ise oluwa?[a] Salako [b] Salako gbe [d] Igunnu.
    2. Oro-oruko a maa sise oluwa, ….. ati eyan [a] ise [b] aatokun [d] abo.
    3. Baba pe mi. Abo inu gbolohun yii ni ——- [a] baba [b] pe [d] mi.
    4. Ewo ni ki i se ara won? Taiwo, Kehinde, ige, Ojo ………[a] Olugbodi [b] Idoha [d] Salako.
    5. Oruko ti o je mo ise ilu ni ……. [a] Alayande [b] Oje kunle [d] Malamo.

            APA KEJI

    1. Ko apeere oruko amutorunwa marun-un sile.
    2. Ko apeere abuda oro oruko marun-n sile pelu apeere mejimeji.

            

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *