Share this:

ISE EDE YORUBA KILAASI:JSS2

ILANA ISE OSOOSE FUN SAA KEJI

1  EDE:  Atunyewo ise saa kin-in-ni

 ASA:  Atunyewo ise saa kin-in-ni

 LIT:  Atunyewo ise saa kin-in-ni

2  EDE:  Aroso Alapejuwe (ilana bi a se le ko aroko Yoruba )

 ASA:  Asa Iranra Eni lowo- Ajo, Esusu, Egbe Alafowosowopo

 LIT:  Litireso Alohun to je mo Esin Ibile- Iyere Ifa, Iwi, Ijala Iremoje.

3  EDE:  Aroko Asapejuwe ( kiko aroko alapejuwe).

 ASA:  Asa Iranra eni lowo (owe, aaro, arokodoko, ebese )

 LIT:  Kika Iwe Apileko: ere onise ti ijoba yan

4  EDE:  Aroso Oniroyin/Asotan ( ilana)

ASA:  Ogun Jija (awon ohun ti o n fa ogun jija ati ohun ti ko ye ko fa ogun jija, awon oloye ogun).

 LIT:  kika iwe ere onise.

5  EDE:  Aroko Asotan/Oniroyin ( kiko aroko).

ecolebooks.com

 ASA:  Eto Isigun, Ipalemo ogun jija, awon ohun elo ogun jija ati ete

ogun jija.

LIT:  Litireso Alohun to je mo esin ibile- orin oro, sango pipe, esu pipe, oya pipe. Abbl.

6  EDE:  Akaye Oloro Geere/Wuuru.

ASA:  (a) Ipari ogun . (b) Ona ti a le gba dena ogun (d) anfaani ati aleebu.

 LIT:  Kika iwe Apileko ti ijoba yan.

7  EDE:  Akaye Oloro Geere.

 ASA:  Atunyewo Asa Iranra-eni-lowo.

 LIT:  Kika iwe apileko ti ijoba yan.

8  EDE:  Akaye ( ilana kika akaye Onisorogbesi).

 ASA:  Ikini

 LIT:  Kika iwe apikeko ti ijoba yan

9  EDE:  Akaye Onisorogbesi.

ASA:  Iwa Omoluwabi. Kin ni omoluwabi, ojuse omoluwabi ni awujo: (otito siso,iwa pele ati ibowo fun agba)

 LIT:  Kika Iwe Apileko ti ijoba yan.

10  EDE:  Atunyewo orisii gbolohun ede Yoruba

 ASA:  Iwa omoluwabi ati ojuse omoluwabi si obi

11&12

 

 

IWE ITOKASI

1 S. Y Adewoyin (2004) New simplified L1Yoruba iwe keji [J. s. s .2] Copromutt (publishers) Nigeria Limited

2 Egbe akomolede ati asa Yoruba (2002) Eko ede ati asa Yoruba iwe keji (J.S.S.2) Longman Nig Plc.

3 Oyebamiji Mustapha (2009) Eko ede Yoruba titun iwe keji (J.S.S.3) university Press Plc.

4 Ayo Bamgbose Fonoloji ati Girama Yoruba (1990)

 

OSE KIN-IN-NI

 

ONKA YORUBA (301- 500) DEETI……………………

Gege bi a ti a so seyin pe iyato diedie yoo ba onka 20, 40, 60, ati 80 ni kete ti a kuro lori igba (200). Fun apeere:

20 okoo

40 oji

60 ota

80 orin

300 ni a n pe ni oodunrun.400 je irinwo ti 500 maa je eedegbeta (600-100)=500. 600 ni a pe ni egbeta (200 x 3).

 300 oodunrun

 320 okooleloodunrun

 340 ojileloodunrun

 360 otaleloodunrun

 380 orinleloodunrun

 400 irinwo

 420 okoolerinwo

 440 ojilerinwo

 460 otalerinwo

 480 orinlerinwo

 500 eedegbeta

 

IGBELEWON

1 Ko awon onka wonyi sile 320, 340, 460, 480, 490

2 ko awon onka wonyi sile 330, 350, 370 430, 470.

 

IWE AKATILEWA

1 Egbe Akomolede ati Asa (2002) Yoruba Eko Ede ati Asa Yoruba iwe keji (J S S2 ) Longman Nig Ltd oju iwe 24-28

 

 

ASA ISOMOLORUKO

AKOONU

  • OHUN ELO ISOMOLORUKO
  • ETO ISOMOLURUKO
  • EWI ATENUDENU TO JE MO IKOMOJADE

Ebun nla gbaa ni Yoruba ka omo si, won si gba wi pe ko si iru dukia ti Olodumare le fun eniyan ti o bori omo. Nitori idi eyi inu won maa n dun pupo nigba ti Oluwa ba yonu si awon idile kan to fi omo titun ta won loore.

Orisirisi ona ni awon Yoruba n gba so omo loruko. Awon miiran a maa wo sababi, asiko ati igba ti won loyun omo naa titi won fibi sile, boya won wa ninu idunnu tabi isoro nigba ti won loyun re ti o wa se pe nigba ti won bii gbogbo oke isoro won di petele, iru ipo bee a maa han ninu oruko omo bee. Oruko Yoruba a tun maa fi iru esin ti idile tabi ebi kan n sin han. Omiran yoo maa fi ise owo ti won se han.

Ni aye atijo, awon obi mejeeji, iya ati baba ni o ni ase lati so omo won loruko ni ojo kejo ti won ba bi omo naa, sugbon oruko ti baba tabi ebi baba ba fun omo ni won maa n te mo o lara ju. Aro kutukutu ni won maa n so omo loruko tori pe owo ero ni asiko owuro je gege bi asa. Baale ile tabi iyaale ile lo maa n dari eto yii, awon obi omo a file ponti, won a fona roka fun awon alejo won.

Leyin pe won a file ponti, won gbodo to ju awon nnkan apeere kan fun eto isomoloruko gan-an. Awon nnka bii oti, orogbo, obi, aadun, omi, iyo, suga, ireke, ataare, oyin, epo pupa ati awon nnkan miran. Awon ohun elo ni a n pe ni eroja isomoloruko. Won a maa fi oruko ti a n pe eroja kookan ati bi eledaa se seda won se adura fun omo naa. Bi apeere, won le fi aadun se adura fun omo naa gege bi oruko re pe aye omo naa yoo dun kale.

Oniruuru orin ni won maa n ko nibi ayeye isomoloruko ti won yoo si maa ke ewi lorisirisi. Ko si ewi kan pato ti a ko le lo ni iru ayeye yii, to ba sa ti ba inu didun lo, yato si awon bii meloo kan bii oku pipe, iremoje, ekun-iyawo.

Apeere orin to je mo ikomojade

A.  Iya abiye o ku ewu o

 Ewu ina kii pawodi

 Awodi o ku ewu

B.  Edumare fun wa lolu omo

 Edumare fun wa lolu omo

 Olu omo maa n da wa lorun o

 Edumare fun wa lolu omo  

 

OHUN ELO ISOMOLORUKO IWURE/ADURA

Odidi ataare lagbaja, wa a dirun, wa a digba

Obi (abata) obi ni biku, obi ni bi arun ki iku maa pa o.

Eja aaro Eja re o, ori leja fi n labu ori re o ni buru

Orogbo orogbo re o, wa gbo wa to

Oti oti ki i ti, oti ki I te omo yii o ni ko ni ti/te

Omi tutu omi re o, ko ni gbodi lara re

Owo ki omo ma rahun owo

 

 

IGBELEWON

1 Ko ohun elo ismoloruko marun sile

2 Bawo ni won se n lo won nibi isomoloruko.

3.  Awon ewi atenudenu wo ni a le lo nibi ayeye ikomojade

 

ORISIRISI ORUKO

AKOONU: Oruko amutorunwa

  Oruko abiso

Oruko abiku

Oruko oriko

Oruko amutorunwa ni oruko eyi ti a n pe omo gege bi ona tabi ipo ti omo gba waye nigba ti won bi.

ORUKO ITUMO

Tiawo/Kehinde akobi ninu awon ibeji(aburo)

Kehinde omo ti a bi tele Taiwo

Idowu omo ti a bi tele awon ibeji

Ige omo ti o ba ese waye

Dada omo ti irun ori re ta koko

Ajayi omo ti o da oju bole nigba ti a bi

Oke omo ti o di ara re sinu apo felefele waye

Olugbodi omo ti ika owo re tabi ika ese re pe mefa

ORIKI ABISO: Awon oruko ti o n toka si ipo tabi aaye ti awon obi omo wa nigba ti won bi omo naa.

 

ORUKO ITUMO

Abiodun/Adebodun omo ti a bi ni akoko odun Pataki kan

Babawale/Babatunde omobinrin ti a bi leyin iku baba re agba

Iyabo/Yetunde/Yewande omombinrin ti a bi leyin iku iya re agba

Abiona omobinrin ti iya re bi si oju ona

Abiose/Abosede omo ti a bi ni ojo ose (aiku)

Abiara omo ti oyun re ko ti I han ti baba re fi ku.

 

ORUKO ABIKU: Abiku ni omo ti a bi ti n ku lemlemo. Apeere oruko won ni Enilolobo, Kukoyi, Malomo, Kosoko, Durojaye.

 

ORUKO IDILE: Awon oruko wonyi ni se pelu, esin tabi ipo ebi ni awujo

ESIN ORUKO

Ifa Awoseeka, Fabunmi, Faleti, Dopemu.

Ogun Ogunbiyi, Ogunleye, ogundiran

Sanponna Babayemi, Obafemi, Anibaba

 

ORUKO ORIKI: Awon oruko yii je oruko ti a fi n pon eeyan le.

 

 

 

ORUKO OKUNRIN ORUKO OBINRIN

Alani, Ajani, Alabi, Adio, Alao Amoke Ajike, Ayinke, Ajihun, Akanke

Asamu, Ayinla, Ajagbe Adunni, Alake Asake, Ajoke.

 

IGBELEWON

  1. Ko ohun elo isomoloruko meje sile ki o si salaye bi a se n lo won.
  2. Ko onka lati 400-500.

     

IWE AKATILEWA

S.Y Adewoyin (2003) New Simplified Yoruba L1 Book Two Copromutt Publisher oju iwe 87-88

 

EWI ALOHUN AJEMAYEYE

Orisirisii ewi atenudenu ni a ni ni ile Yoruba ti a maa lo nibi ayeye, awon ewi atenudenu yii ko lo n ka. Lara iru awon ewi bayii ni a ti ri Rara, Olele, Oku-pipe, Alamo, Ege, Ekun-Iyawo, Efe, Dadakuada, Etiyeri ati bee bee lo.  

Bi orisirisii ayeye se wa bii ayeye igbeyawo, isinku agba, ikomojade, isile, oye jije ati bee bee lo, bee naa ni awon Yoruba ni oniruru ewi ti o ba okookan mu sugbon awon ewi alohun ti a le lo nibi igbeyawo ni a fe gbe yewo.

Bi o tile je pe ekun iyawo gan ni ewi atenudenu ti a ya soto fun aseye igbeyawo, ti o si gbe oruko iyawo lori, awon ewi atenudenu kan wa to je pe ojo ni won, sasa ni ibi ayeye ti won kii ti lo won. Iru awon ewi atenudenu bee ma n waye nibi ayeye igbeyawo bakan naa. Die ninu awon ewi naa ni rara, ege, olele, apepe, obitun, dadakuada ati bolojo.

 

LITIRESO ATENUDENU EYA/AGBEGBE

Rara Oyo

Olele Ijesa

Biripo Ikale/Ilaje

Ekun iyawo  Oyo

Bolojo Ye wa(Egbado)

Alamo Ekiti

Adamo  Ife

Igbala Egba

Dadakuada  igbomina

Orin etiyeri  Oyo

Ege/Ariwo  Egba

Orin Edi  Ile-ife

Obitun  Ondo

Apepe Ijebu

IWE AKATILEWA

1 Egbe Akomolede ati Asa (2002) Eko Ede ati Asa Yoruba iwe keji (J S S2 ) Longan Nig Ltd oju iwe123-127.

 

 

APAPO IGBELEWON

  1. Ko ohun elo isomoloruko meje sile ki o si salaye bi a se n lo won.
  2. Ko onka lati 400-500.
  3. Ko ohun elo ismoloruko marun sile
  4. Bawo ni won se n lo won nibi isomoloruko.
  5. Awon ewi atenudenu wo ni a le lo nibi ayeye ikomojade

 

ZT%NY@W) IX!

  1. Ko aroko lori bi o se lo isinmi keresimesi.

 

ISE ASETILEWA

  1. 500 ni A. irinwo B. igba D. oodunrun E. eedegbeta.
  2. Marundinleedegbeta ni A. 95 B. 295 D. 495 E. 395.
  3. Ewi alohun ti o wopo ni Ijebu ni A. Apepe B. Obitun D. ekun iyawo E. rara.
  4. Ewi alohun ti o wopo ni dadakuada ni A. apepe B. Obitun D. Dadakuada E. rara.
  5. Omo ti o doju bole nigba ti a bi ni A. Ajayi B. Dada D. Idowu E. Taye.

     

    APA KEJI

    1. Ko onka lati 400-500.
    2. Ko oruko amutorunwa marun pelu alaye.

 

OSE KJI

 

AROSO ALAPEJUWE

AKOONU:  Deeti………………..

  • Itumo.
  • Apeere.

Aroso ni ohun ti a ro lati inu arojinle wa ti a fe ko sile. Orisiirisii aroso lo wa, a ni aroko oniroyin, onileta, alalaye, onisorogbesi, alapejuwe, alariyanjiyan.


AROSO ALAPEJUWE

Eyi je mo sise apejuwe eniyan, ibikan tabi ohun kan lona ti o se pekipeki nnkan naa. Tori a le so wi pe aroso alapejuwe ni aroso ti a fi n se apejuwe eniyan tabi ibi kan(Descriptive essay). Apejuwe wa gbodo fi han pe a mo ohun ti a n soro nipa re. Apeere ori oro aroko alapejuwe ni:-

  • Ile baba mi
  • Oja ilu mi
  • Ore mi ti mo feran ju
  • Ile iwe mi

     

ILANA AROKO (ILE BABA MI)

 Ilu wo ni ile naa wa

 Adireesi ibi ti ile naa wa

 Bawo ni ile naa se ri ( ile ile/alaja)

 Oda wo ni ile naa ni?

 Ki ni a koko maa ri ni ile naa

 Ojule melo ni ile naa

 Nje iyato wa laarin ile yii si omiiran bi?

 Ko boya o feran ile naa tabi o ko feran re, salaye

 

IGBELEWON

1 Ki ni a n pe ni aroko?

2  Orisii aroko melo lo wa?

  1. Salaye aroko alapejuwe
  2. Ko ilana lori aroko “ore mi ti mo feran ju”

 

ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ

Egbe akomolede ati asa Yoruba (2002) Eko ede ati asa Yoruba iwe keji ( J.s.s.2) oju iwe 49-53 Longman Nig Plc.

 

ASA

AKORI ISE:   ASA IRANRA – ENI – LOWO.
Deeti………………..

 Gege bi a ti so saaju tele pe orisiirisii ona ni awon Yoruba maa n gba ran arawon lowo. E je ki a tun gbe awon wonyi wo ninu ona ti awon Yorba maa n gba ran arawon lowo.

Owe: Ise ti o po pupo ti eniyan kan ko le da se funra re bi o ti wu ki o lagbara to ni won n fi owe se, Tokunrin, tobinrin, tomode, tagba ni a n be lowe tori gbogbo won ni o ni ipa ti won o n ko nibe. Iru ise ile kiko ni a maa n be eniyan lowe si. ki i se dandan ki a san owe pada bi aaro ti o je adire irana.

Arokodoko: Eniyan meji, meta lo maa n se iru ise yii, won a sise ninu oko enikan ni oni bi o ba di ojo keji oko enikeji ni won o lo. Bi o ba di ojo keta, won o gba oko eniketa lo lati sise. Bayi ni won o se maa se titi won o fi pari ise.

Ebese: ona iranra eni lowo miiran ti awon Yoruba n gba ran arawon lowo ni ebese. Oun ni ona iranra eni lowo fun inawo ti o n bo lona. Fun apeere ti inawo kan ba ku si dede bi igbeyawo, isomoloruko. Enikan ko le se gbogbo imurasile iru inawo yii. Awon to maa lo ra orisiirisii ounje, awon to maa lo ge igi ni oko bakan naa ni awon ti won yoo se eto omi yoo wa. Gbogbo ona won yii ti a n gba lati ran eniyan lowo fun iru inawo yii ni a n pe ni ebese.

Aaro: Awon ti ojo ori won ko ju ara won lo ni won maa n se aaro. O maa n wopo laarin awon agbe.Won le to mefa, mejo tabi ju bee lo.

 

IGBELEWON

Ko
ona marun-un ti a n gba ra ara wa lowo ki o si salaye won lokookan.

 

ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ

1 Oyebamji Mustapha (2009) Eko ede Yoruba titun iwe kin-in-ni (J S S2 ) oju iwe University Press Nig

2  Oyebamji Mustapha (2009) Eko ede Yoruba titun iwe kin-in-ni (J S S2 ) oju iwe 136-146 University Press Nig

 

AWON EWI ALOHUN AJEMESIN ABALAYE

– Iyere Ifa

– Esa Egungun / Iwi

Ijala

 

Ni aye atijo ki awon alawo funfun to mu awon esin igbalode wa saarin awon Yoruba, orisirisi esin ni awon baba nla wa n sin ti awa si jogun ba lowo won. Bi orisii awon esin yii se wa naa ni a ni awon ewi alohun tabi ewi atenudenu ti a n lo fun okookan won. Iyen ni pe oni irufe ewi ti a fi maa n ki awon orisa kookan ti a n sin ni ile Yoruba.

 Iyere Ifa: ni orin awon babalawo ti won saba maa n ko ni asiko ti won ba n se odun ifa, sugbon iyere sisun le waye nigba ti babalawo ba n ki ifa lowo tabi ti won ba n se ayeye kan bii etutu ati igba ti won ba fe bo ifa.

 Esa Egungun/Iwi: ni ewi alohun ti awon olusin egungun maa n lo nigba ti won ba n se odun egungun. Awon lo maa n je oruko mo oje, awon oruko bii Ojekunle Ojeniyi Ojedele ati bee bee lo. Tako-tabo idile oloje lo le pe esa.

 Ijala: awon ode ati awon alagbede ni won n sun ijala ni akoko odunlati fi yin ogun ati lati fi wa oju rere Ogun. Oloye: Oluode, jagun Ode, Abogun, Eleede.

Ounje Ode: aja, iyan, obi, emu, esun isun, akukodie.

Ohun Elo Orin: fere ekutu, ilu dundun, ati agree.

Apeere Ijala ni:

Ogun lakaaye Osinmole

Onile kangun kangun orun

O lomi nile feje we

O laso nile fimokimo bora

Ogun alada meji o fi okan sanko

O fi okan yena ……….

 

IWE AKATILEWA

S.Y Adewoyin (2003) NEW SIMPLIFIED YORUBA L1 Corpromutt Publishers Oju iwe 12-13.

Egbe Akomolede ati Asa Yoruba Eko Ede ati Asa Yoruba Iwe Keta Oju Iwe 14 – 16.

 

 

IGBELEWON

  1. Daruko ewi atenudenu merin to je mo esin abalaye pelu awon orisa ti won n fi awon ewi naa bo.
  2. Salaye lori Oro

 

APAPO IGBELEWON

  1. Iroyin ti a n so fun eiyan ti a ko t ii so ni?
  2. Ko ewi alohun esin abalaye marun-un sile.
  3. Salaye awon oro yii: owe, ebese, aaro, arokodoko.

 

ZT%NY@W) IX!

  1. Salaye irinajo Oduduwa lati ilu Meka si Ile-Ife.
  2. Ki ni gbolohun? ko apeere merin.

     

ISE ASETILEWA

  1. ….. je ohun ti a ro ti a ko ti ko sile ni . A. akaye B. gbolohun D. aroko E. aroso.
  2. Iyato laarin aroso ati aroko ni pe a kii ti ….. aroso sile. A. ko B. ro D. wi E. ri
  3. Aroko wa gbodo ……. A. koni logbon B. panilerin D. mu eniyan sun E. je iro pipa
  4. Ewo ninu awon wonyi ni o ni eto ijoba ninu? A. egbe alafowosowopo B. ajo D. esusu E. aaro
  5. Iru eniyan wo lo le se olori elesusu. Eni ti o ba je ….. A. olowo B.ologbon D. olooto E. osise ile ifowopamosi

APA KEJI

1 Salaye esusu

ajo

  1. Awon nnkan wo ni a gbodo koko mo bi a ba fe ko aroko?

 

OSE KETA.

AROKO ALAPEJUWE

AKOONU:  Deeti………………..

  • Itumo.
  • Apeere.

Aroko ni ohun ti a ko sile lati inu arojinle wa fun elomiran lati ka a. Orisiirisii aroko lo wa, a ni aroko oniroyin, onileta, alalaye, onisorogbesi, alapejuwe, alariyanjiyan.

 

AROKO ALAPEJUWE

Eyi je mo sise apejuwe eniyan, ibikan tabi ohun kan lona ti o se pekipeki nnkan naa. Tori a le so wi pe aroko alapejuwe ni aroko ti a fi n se apejuwe eniyan tabi ibi kan(Descriptive essay). Apejuwe wa gbodo fi han pe a mo ohun ti a n soro nipa re. Apeere ori oro aroko alapejuwe ni:-

  • Ile baba mi
  • Oja ilu mi
  • Ore mi ti bimo feran ju
  • Ile iwe mi

 

ILANA AROKO (ILE BABA MI)

 Ilu wo ni ile naa wa

 Adireesi ibi ti ile naa wa

 Bawo ni ile naa se ri ( ile ile/alaja)

 Oda wo ni ile naa ni?

 Ki ni a koko maa ri ni ile naa

 Ojule melo ni ile naa

 Nje iyato wa laarin ile yii si omiiran bi?

 Ko boya o feran ile naa tabi o ko feran re, salaye

 

IGBELEWON

1 Ki ni a n pe ni aroko?

2  Orisii aroko melo lo wa?

  1. Salaye aroko alapejuwe
  2. Ko ilana lori aroko “ore mi ti mo feran ju”

 

ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ

Egbe akomolede ati asa Yoruba (2002) Eko ede ati asa Yoruba iwe keji ( J.s.s.2) oju iwe 49-53 Longman Nig Plc.

 

 

 AKORI ISE:   ASA IRANRA – ENI – LOWO.

Asa iranra – eni – lowo ni ona ti awon Yoruba maa n gba ran ara won lowo tabi ki a so pe asa iranra eni – lowo ni ona ti awon Yoruba maa n gba soore fun arawon. Orisiirisii ona ni awon Yoruba maa n gba ran ara won lowo. Die lara won ni: (i) Aaro (ii) Ebese (iii) Esusu abbbl  

Esusu:-Eleyii ni i se pelu owo. Won maa n da owo yii ni. Won maa n ni eni ti yoo maa gba owo yii laarin arawon. Eni ti o n gba owo yii maa gba owo naa kaakiri lodo awon eniyan (omo egbe). Bi won ba ti n da owo yii ni won maa ko si ara iganna/ogiri (wall) won o maa fa igi kookan si ara iganna, igi yii ni iye ti o duro fun.

Ajo:- Ajo naa dabi esusu ni, won maa n da owo fun olori alajo. O ni iye owo ti eniyan yoo maa da bi agbara eeyan ba se to. Iyato to wa laarin esusu ati ajo ni wi pe gbogbo iye ti eniyan ba da ni eeyan yoo ko nibi esusu sugbon nibi ajo eeyan yoo ko ida kan sile fun olori alajo.

Egbe alafowosowopo: egbe alafowosowopo naa ni won n pe ni egbe alajeseku. Egbe yii wopo wa laarin iyaloja,osise ijoba abbl. Won maa n ni oloye laarin won bi akowe, akapo, ayewe owo wo.ki a ranti wi pe awon egbe yii maa n ni eto ati ofin lati odo ijoba. Eyikeyi ninu omo egbe ni o ni anfaani lati ya owo nibe.

 

IGBELEWON

  1. Ko ona meta ti awon Yoruba maa n gba ran ara won lowo.
  2. iyato wo lo wa laarin esusu ati ajo?.

 

ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ

1 Oyebamji Mustapha (2009) Eko ede Yoruba titun iwe kin-in-ni (J S S2 ) oju iwe University Press Nig

2  Oyebamji Mustapha (2009) Eko ede Yoruba titun iwe kin-in-ni (J S S2 ) oju iwe 136-146 University Press Nig

 

 

LITIRESO

Kika iwe apileko ti ijoba yan.

 

APAPO IGBELEWON

  1. Ko ona meta ti awon Yoruba maa n gba ran ara won lowo.
  2. Iyato wo lo wa laarin esusu ati ajo?
  3. Salaye kekere lori iwe itan aroso ti o n ka.

 

ZT%NY@W) IX!

  1. Ko onka lati 1-100.

     

ISE AMURELE

  1. ….. je ohun ti a ko sile lati inu arojinle wa fun elomiran lati ka a. A. akaye B. gbolohun D. aroko E. aroso
  2. Ti a ba fe ko aroko, a gbodo koko yan ….. A. ikadi B. ifaara D. ori oro E. ikadii
  3. Aroko wa gbodo ……. A. koni logbon B. panilerin D. mu eniyan sun je oni-isipaya
  4. Ewo ninu awon wonyi ni o ni eto ijoba ninu? A. egbe alafowosowopo B. ajo D. esusu E. ebese.
  5. Iru eniyan wo lo le se olori elesusu. Eni ti o ba je ….. A. olowo B.ologbon D. olooto. E. osise ile ifowopamosi.

APA KEJI

  1. Ki ni aroko alapejuwe?
  2. Iyato wo lo wa laarin arokodoko ati aaro?

 

 

 

 

OSE KERIN

 

AROSO ASOTAN/ONIROYIN Deeti………………..

AKOONU:

  • Itumo
  • Apeere.
  • Igbese.

Aroso ni aroso iroyin ohun ti o sele ni oju wa tabi ti won so wa fun ti a n so iroyin naa fun elo miiran laisi si ayokuro tabi afikun. O ye ki eni ti yoo royin nnkan le royin finnifinni lona ti ko si nibe nigba ti isele naa sele yoo fi le fi oju inu wo nnkan naa bi igba ti oun gan alara fi oju se konge ohun naa ni.

 



Die ninu awon ori oro ti a le ko aroso oniroyin le lori ni wonyi:-

  1. Ija igboro kan to soju mi
  2. Ijamba moto kan ti mo wa ninu re
  3. Ojo kan ti a ko le gbagbe
  4. Ayeye ojo ibi kan ti mo lo

 

Awon igbese ti a gbodo gbe bi a ba fe ko aroko asotan ni:-

  1. A gbodo yan ori oro ti a fe so itan le lori
  2. A gbodo so ilu tabi ibi ti isele naa ti se
  3. Agbodo so ohun to gbe ni de ibi isile naa tabi nnkan to fa sababi isele naa
  4. A gbodo so itan naa lekun rere bo se waye gan-an
  5. A gbodo kadi itan wa pelu eko mani-gbagbe kan tabi imoran.

IGBELEWON

  1. Ki ni aroko oniroyin/asotan?
  2. Ko aroko lori ojo ibi re ti o koja
  3. Ko ilapa ero lori “Ojo kan ti nko le gbagbe”

 

ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ

Egbe akomolede ati asa Yoruba (2002) Eko ede ati asa Yoruba iwe keji (J.S.S.2) 49-51 Longman Nig Plc.

 

AWON OHUN TO N FA OGUN

Ti a ba n soro ogun, a n soro lori ede aiyede laarin ilu meji tabi ju bee lo. Iru nnkan bayii ni o maa n fa itajesile, ipaniyan, wahala igbenilokan soke, iberu, iku. Nitori idi eyi gbogbo eniyan ni yoo ba ese re soro ti won yoo salo. Apeere awon nnkan ti o maa n fa ogun ni:

  • Ile ati ohun ini
  • Oro aala ile
  • Isakole
  • Ife lati gba eru (sunmomi)
  • Ede aiyede.

 

IGBELEWON

  1. Ki ni ohun ti o n se okunfa ogun?

 

 

 

ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ

1  Oyebamiji Mustapha (2009) Eko ede Yoruba titun iwe keji (J.S.S.2) oju iwe 75-86 university Press Plc.

2  Oyebamiji Mustapha (2009) Eko ede Yoruba titun iwe keji (J.S.S.2) oju iwe 1-5 University Press Plc.

 

LITIRESO

Kika iwe apileko ti ijoba yan.

 

APAPO IGBELEWON

  1. Ki ni aroko oniroyin/asotan?
  2. Ko aroko lori ojo ibi re ti o koja
  3. Ko ilapa ero lori “Ojo kan ti nko le gbagbe”
  4. Ko asa marun-un ninu iwe apileko ti o ka.

 

ZT%NY@W) IX!

  1. Ko asa marun-un ninu iwe litireso apileko ti o ka seyin.

 

ISE ASETILEWA

  1. Iroyin ti a n so fun eniyan ni aroso A. onisorogbesi B. oniroyin/asotan D. alapejuwe.
  2. Ewo ni ki i se aroso oniroyin? A. baba mi B. odun keresimesi ti o koja D. ounje ile wa.
  3. “ojo kan ti n ko le gbagbe je aroso …… A. alapejuwe B. oniroyin D. alariyanjiyan.
  4. Awon ilu maa n gbe ogun ti ara won nitori …….. A. ounje B. oro ile D. orin kiko
  5. Lara ohun ti o le fa ogun ni? A. oro siso B. aala ile D. ounje.

 

APA KEJI

  1. Fun aroso oniroyin ni oriki
  2. Ko nnkan merin ti o le se okunfa ogun
  3. salaye perete lori iwi/esa.

 

 

OSE KARUN-UN

 

AROKO ASOTAN/ONIROYIN Deeti………………..

AKOONU:

  • Itumo
  • Apeere.
  • Igbese.

Aroko ni ohun ti a ko sile lati inu arojinle wa fun elomiran lati ka a. Orisiirisii aroko lo wa, a ni aroko oniroyin, onileta, alalaye, onisorogbesi, alapejuwe, alariyanjiyan.


Aroko oniroyin: ni a n pe ni aroko asotan. Iru aroko yii ni a ti maa n so itan isele ti a fi oju ri tabi eyi ti a kopa ninu re, tabi ti a gbo lati enu enikan. Aroko yii maa n so nipa ohun to ti sele seyin ni. Die ninu awon ori oro ti a le ko aroko oniroyin le lori ni wonyi:-

  1. Ija igboro kan to soju mi
  2. Ijamba moto kan ti mo wa ninu re
  3. Ojo kan ti a ko le gbagbe
  4. Ayeye ojo ibi kan ti mo lo

 

Awon igbese ti a gbodo gbe bi a ba fe ko aroko asotan ni:-

  1. A gbodo yan ori oro ti a fe so itan le lori
  2. A gbodo so ilu tabi ibi ti isele naa ti se
  3. Agbodo so ohun to gbe ni de ibi isile naa tabi nnkan to fa sababi isele naa
  4. A gbodo so itan naa lekun rere bo se waye gan-an
  5. A gbodo kadi itan wa pelu eko mani-gbagbe kan tabi imoran.

IGBELEWON

  1. Ki ni aroko oniroyin/asotan?
  2. Ko aroko lori ojo ibi re ti o koja
  3. Ko ilapa ero lori “Ojo kan ti nko le gbagbe”

ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ

Egbe akomolede ati asa Yoruba (2002) Eko ede ati asa Yoruba iwe keji (J.S.S.2) 49-51 Longman Nig Plc.

 

AWON OHUN ELO OGUN JIJA Deeti………………..

Ki ilu kan to ja ilu miiran. A je wi pe ede aiyede ti wa laarin won. Leyin eyi ni won o ta arawon lolobo pe ki won o mura ogun jija (ipeninija ) sile . Awon ode ilu ni won saba maa n lo ja ogun. Eleyi wopo laarin awon iran eso ikoyi. Won o paroko ranse. Ose, osun, kaninkanin ninu igba kan. Etu, ota ibon, ado ati awon nnkan ijanba ninu igba miiran. Won a ni ki oba ilu keji o yan okan ninu aroko yii. Ota, ibon, ahaya yii tumo si ogun nigba ti osun, ose tumo si alaafia pe awon fara mo ohun ti awon ilu keji yii so. Awon ohun eelo ogun jija ni ibon, ofa, ada, obe, ahaya, etu, kumo, kannakanna, esin, oogun lorisiirisii.

 Ipalemo Ogun Jija: ki won to ja ogun nile Yoruba, ilu yoo lo beere lowo ifa bi ohun yoo ti ri, ohun ti won gbodo koko se ki won to ja ogun. Won yoo bo ifa. Won yoo rubo Ogun ki Ogun ma fi eje won we. Ki ohun ija won bi ida, ibon ma koju ija si won. Won o tun rubo si Esu laalu ogiri oko ki Esu ma ba a se won, ki Esu se awon ota won.Leyin eyi ni won yoo ko awon odo kunrin jo pelu awon omo ode fun imura sile de ogun.

 Eto Isigun: awon omo ogun ni won koko maa n siwaju ogun nigba ti awon oloye ogun yoo tele won gege bi ipo won ba se ga to. Balogun ati awon isongbe re ni o maa n keyin ogun.

 

IGBELEWON

  1. KI ni awon nnkan ti won fi maa n paroko ogun jija?
  2. Ko awon ohun elo ogun jija mewaa sile.
  3. Salaye lori ipalemo ogun.

 

ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ

1  Oyebamiji Mustapha (2009) Eko ede Yoruba titun iwe keji (J.S.S.3) oju iwe 75-86 university Press Plc.

 

2  Oyebamiji Mustapha (2009) Eko ede Yoruba titun iwe keji (J.S.S.3) oju iwe 1-15 University Press Plc.

 

LITIRESO

AWON EWI ALOHUN AJEMESIN ABALAYE

 

– Iyere Ifa

– Esa Egungun / Iwi

– Sango Pipe

Ni aye atijo ki awon alawo funfun to mu awon esin igbalode wa saarin awon Yoruba, orisirisi esin ni awon baba nla wa n sin ti awa si jogun ba lowo won. Bi orisii awon esin yii se wa naa ni a ni awon ewi alohun tabi ewi atenudenu ti a n lo fun okookan won. Iyen ni pe oni irufe ewi ti a fi maa n ki awon orisa kookan ti a n sin ni ile Yoruba.

 Iyere Ifa: ni orin awon babalawo ti won saba maa n ko ni asiko ti won ba n se odun ifa, sugbon iyere sisun le waye nigba ti babalawo ba n ki ifa lowo tabi ti won ba n se ayeye kan bii etutu ati igba ti won ba fe bo ifa.

 Esa Egungun/Iwi: ni ewi alohun ti awon olusin egungun maa n lo nigba ti won ba n se odun egungun. Awon lo maa n je oruko mo oje, awon oruko bii Ojekunle Ojeniyi Ojedele ati bee bee lo. Tako-tabo idile oloje lo le pe esa.

 Sango Pipe: ni ewi awon Adosu Sango awon ni olusin Sango, o le je okunrin tabi obinrin, ko si eni ti ko le ki oriki Sango. Asiko ti won ba n bo Sango tabi se odun Sango ni Sango pipe ti maa n waye ju.

Oya Pipe:
Oya pipe je ewi alohun esin abalaye esin Oya. Won maa n pe e ni akoko odun oya. Awon olubo re ni a n pe ni Iya Oya. Oro inu re maa n da lori ife oko, eewo Oya agbo tabi irun re (agbo) ko gbodo de ojubo oya. Ounje fun irubo amala ati obe ilasa ati ewure. Apeere Oya Pipe:

A-a-seeperi arewa obinrin

Oya oriri, nle oloro Sango

Afinju irunmole ti n be lodo Sango

Afinju iyawo ti n ba oko re rode ……..

 

Orin Oro/Arungbe: awon oloro ni won n ko orin ni akoko odun re (odun oro) won n fi orin yiibi oniwabaje lati le dekun iwa ibaje tabi lati fit un asiri ohun ikoko ti won ro pe eni Kankan ko mo. Awon oloye oro Ajana, Lala, Eleeti Oro. Ounje Oro: efo ekuya, asaro, obuko, adiye, iyan ati obe egusi. Eewo: obinrin ko gbodo ri Oro. A ki i ajeku Oro. Apeere orin Oro ni:

Ta n pe Tisa nibi Oro? (2ce)

Abi sokoto tofetofe

Ta n pe Tisa nidi Oro?

 

Oro ma soko

Ile ni e wa to

Obinrin wo o, o ku pi……

 

Esu-Pipe: Awon Olubo re ni won n pe e ni akoko odun won. Esu je iranse/olopaa Olodumare. Obinrin ni o wopo laaarin awon Aworo Esu, awon okunrin maa n da ere si ori.

Ounje Esu: epo,ebo.

Eewo Esu: adi ati obi.

Apeere Ewi Alohun Esu Pipe:

Esu laalu ogiri oko,laaroye afada toro-epo

Okunrin kukuru,okunrin gogoro laalu

Abani woran ba o rid a

Elekun n sunkun, Laaroye n s’eje.

 

Ijala Ere Ode: Awon Ode ati alagbede ni won n sun ijala ni akoko odun lati fi yin Ogun ati lati fi wa oju rere re tabi lati fi ki agba ode.

Oloye: Oluode, Jagun, Ode abogun,

Ounje Ogun: aja, iya, obi, emu, esun isu, akukodie.

Ohun Elo Orin Ijala: fere ekutu, ilu dundun, ati ilu agree.

Apeere Ijala Ode ni:

Ogun lakaaye osinmole,

Onile kangunkangun oke orun,

O lomi nile feje we,

O laso nile fi morimo bora.

Ogun aladaa meji,

O fikan sanko, o fikan yena…

 

IGBELEWON

Salaye ewi alohun ajemesin marun-un.

 

IWE AKATILEWA

S.Y Adewoyin (2003) YORUBA LI BOOK 2 Corpromutt Publishers Oju Iwe 16-17.

 

ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ

Egbe akomolede ati asa Yoruba (2002) Eko ede ati asa Yoruba iwe keji (J.S.S.2) Longman Nig Plc Oju Iwe 14-16.

 

APAPO IGBELEWON

  1. Ki ni aroko oniroyin/asotan?
  2. Ko aroko lori ojo ibi re ti o koja
  3. Ko ilapa ero lori “Ojo kan ti nko le gbagbe”
  4. Salaye ewi alohun ajemesin marun-un.

 

ZT%NY@W) @K_

  1. Ko aroko lori ‘ile iwe mi’

     

     

ISE ASETILEWA

  1. Ti won ba fun wa ni akaye ohun ti won fe ki a se ni ki a ……A. ronu B. sa ere kiri D. fa ogbon inu re yo
  2. Ota ibon, etu je aroko ….. A. alaafia B. ipalemo ise ode D. ogun jija.
  3. Awon ti ogun ba ko lati ilu kan si omiran ni a n pe ni ….. A. jagunjagun B. iwofa D. eru
  4. Awon ……. ni olusin ogun A. olounje B. ode D. onirara.
  5. …….. ni won n fi ijala bo A. ogun B. ifa D. sango.

APA KEJI

  1. Ko ohun elo ogun jija meji sile
  2. Ko merin sile ninu ewi atenudenu to je mo esin abalaye

 

OSE KEFA

AKAYE

akaye ni ohun ti a ka ti o si ye wa yekeyeke. Ti a ba fe dahun ibeere ti o tele akaye, a gbodo fi ara bale daadaa ka akaye, a gbodo ka akaye ni eemeji. Leyin eyi ni o wo awon ibi ti ibeere ti jeyo ninu akaye. Leyi ni yoo dahun ibeere. Ti o ba ti dahun ibeere tan ni yoo tun wo boya idahun ba ibeere mu.

 

Ka ayoka isale yii ki o si dahun ibeere ti o tele e.

Owo se pataki, o se koko. Bi o tile je pe owo ko fe ki enikeni damoran kanakan leyin

ohun, sibe a gbodo mo pe iranse lo je. Ko ye ki o di oga fun enikeni, ti Oba oke ba fi se buruji fun. Laye atijo, bi enikan ba sise to lowo laarin ebi, gbogbo ebi ni yoo janfaani re. Imo won ni pe owo ko niran, ko je ki won di agberaga. Bi awon baba wa se ni itara ise aje to, won ki i saba gbona alumokoro wa owo. Lode oni awon eniyan n digunjale, won n sese, won n gbe kokeeni nitori owo.

 

  1. Ayoka yii fi ye wa pe owo je ……………………. A. agberaga B. oga D. iranse E. onitara.
  2. Ona wo lo daraju lati lowo? A. oso sise B. omo gbigbe D. ise sise E. gbigbo tebi
  3. Akole to ba ayoka yii mu ju ni…………. A. awon adigunjale B. owo nini D. anfaani olowo E. gbigbe kokeeni
  4. Itara ki ni awon Yoruba ni? A. igberaga B. ise aje D. buruji E. owo nini
  5. Pari oro yii ‘Imo won ni pe ……………. A. owo ko niran B. owo ni koko D. owo dara E. owo je ajemonu.

 

 

AWON OLOYE OGUN Deeti………………..

Ni ilu Oyo, awon ode ati awon akoni ni awon oloye ti o maa n dajo lati lo jagun. Pupo lati iran onikoyi, iremogun ati oluoje ni o maa n jagun ju nile Yoruba. Awon iran onikoyi ko ni ise meji ju ogun lo. Aadorin ni awon oloye ogun laarin awon eso ikoyi ni o n so ilu Oyo. Laarin won ni a ti yan Aare onakakanfo Eleyi ni olori ogun gbogbo ile Yoruba.

Oloye ogun ti ipo re ga ju ni ilu kookan ni ile Yoruba ni Balogun. Balogun ni isomogbe re . Awon ni otun balogun ti o gbodo maaa ja ni egbe otun re ni oju ogun. Osi Balogun naa je okan lara oloye Balogun. Ohun ni o maa n ja ni egbe osi Balogun ni oju ogun. Leyin eyi ni a ni ekerin, ekarun ati ekefa Balogun. Awon oloye mefeefa yii ni ipo won ga ju ni ninu oye ogun.

Seriki ni oye ogun ti o pawo le Balogun. Sarumi ni oloye ogun to kan, oun naa ni isomogbe bi ti Balogun ati Seriki.

ETO OGUN: Gege bi ipo awon oloye ogun ba se ri ni won se n to ja ogun. Oloye asiwaju ni o maa saaju pelu awon isomogbe re. Leyin won ni Bada pelu awon isomogb re leyin re ni asipa. Leyin patapata ni Balogun pelu awon isomogbe re yoo wa ni oju ogun.

 

BI A SE LE DENA OGUN JIJA

Orisiirisii ona ni awon Yoruba maa n gba dena ogun paapaa julo won maa n mo odi yi ilu ka lati soro fun ota lati koja si ilu won.

Wiwa Yara: Yara yii ni won maa n gbele/koto lati soro fun awon ota lati koja nibe

Tituba: Ni iwon igba ti owo ilu kin-in-ni ba te ekeji awon ara ilu yii le bebe ki won ni awon o se ohun ti won ni ki awon o se, awon ti fara mo ohun ti won ba ti so. Iru igbese bayi ni a n pe ni tituuba

Lilo Alami: Alami/Aloore ni eni ti o n so enu ibode kookan. Awon ni won maa tete ri ti ogun ba ti n bo. Laifotape won ti fi to eni ti o ye leti pe ogun ti de.

 

IGBELEWON

  1. Ko orisi ona meta ti a n gba dena ogun sile
  2. Salaye wiwa/Yara ninu eto ogun jija
  3. Ko oruko oloye ogun marun-un sile
  4. Awon iran wo ni won maa n jagun nile Yoruba.

 

 

ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ

1  Eko ede ati asa Yoruba titun iwe kin-in-ni ( S S S ) Oju iwe 75-86 lati owo Oyebamji Mustaph.

2  Oyebamiji Mustapha (2009) Eko ede Yoruba titun iwe keji (J.S.S.3) oju iwe 1-15 university Press Plc.

 

 

LITIRESO

Kika iwe apileko ti ijoba yan.

 

 

APAPO IGBELEWON

  1. Ko orisi ona meta ti a n gba dena ogun sile
  2. Salaye wiwa/Yara ninu eto ogun jija
  3. Ko oruko oloye ogun marun-un sile
  4. Awon iran wo ni won maa n jagun nile Yoruba.

 

ZT%NY@W) @K_

  1. Ya ate faweli aranmupe.

 

ISE ASETILEWA

  1. Ohun ti a ka ti o ye wa ni A. oniroyin B. akaye D. alalaye
  2. Ewo ni o tona? A. a gbodo fi ara bale ka akaye B. a ko gbodo ka akaye ti a ko mo eni ti o ko o D. akaye gbodo gun.
  3. Ewo ni ko tona? A. a gbodo fi ara bale ka akaye B. a ko gbodo ka akaye ti a ko mo eni ti o ko o D. idahun gbodo ba ibeere mu
  4. Oloye ogun ti o ga ju ni …… A. Balogun B. Aare Onakakanfo D. bada D. Seriki
  5. Ni aarin ilu kookan eni ti oye ogun re ga ju ni ……A. Balogun B. Aare Onakakanfo D. seriki

APA KEEJI

  1. Ona wo ni won n gba dena ogun? Salaye.
  2. Ko anfaani ogun jija meta sile.
  3. Salaye ona meta ti a n gba dena ogun jija.

 

 

 

 

 

OSE KEJE

AKAYE 1

(Ka akaye yii ki o si dahun ibeere ti o tele)

 Ojo ko ti awon eegun yoo pidan ni ita Oba. Oba ati awon ijoye ati gbogbo awon ero ti pese wamuwamu si aaye won. Bee ni olukuluku awon eegun nla n ta okiti, won le awon eegun keekeeeke lese wa si ojude Oba. Ariwo n ta gee bee ni kaluku ti n lo juba niwaju Oba ki won to lo jokoo laaye won. Eyi ti o ba de keyin a si juba awon ti o ba niwaju ki o to jokoo. Sugbon okan ganta bayi de, se ni o lo jokoo ni tire leyin ti o ti ki Oba tan, ko tile naani awon ti o ba niwaju rara. Awon naa si kan oro re sinu. Won ni awon yoo maa wo ibi ti yoo ruu wo.

 Bi ilu ti n dahun kikankikan ni awon eegun n bo sijo nikookan ti won si n jo bi arira. Eegun oyaju yii kan n yan finafina kiri ni lai beru ohun ti awon yooku le fi oun se.

  1. Kin ni o mu Oba ati awon ijoye ti won fi pese wamuwamu ni ita Oba? A. Oba fe fi eniyan joye B. awon ode fe sun ijala fun Oba. D. awon eegun fe pidan fun Oba E. oba fe se Igbeyawo fun omo re.
  2. Iru iwa wo ni eegun ti o de gbeyin hu si awon elegbe re? A. iwa aladaje B. iwa ika D. iwa odaju E. iwa igberaga
  3. Ki ni awon eegun so nipa eegun ti o de gbeyin? A. won ni awon yoo wo ibi ti yoo ru wo B. won ni awon yoo le kuro laarin won D. won ni awon yoo rojo re fun Alagbaa E. won ni awon yoo rojo re fun Oba
  4. Ohun ti awon eegun koko n se nigba ti won de ita Oba ni pe won ……. A. n pesa fun Oba B. juba fun Oba D. juba fun arawon E. n juba fun awon obi won.
  5. Itumo ‘naani’ gege bi a ti loo ninu ayoka yii ni ……. A. ibinu B. aibikita D. ainilaari E. idunnu

 

AKAYE 2

Ka ayoka yii ki o si ahun ibeere ti o tele e.

Eniitan je omobibi ilu Oloruntowoju ni ipinle Ogun. Ibanuje to subu lu ayo lo fa sababi oruko ti iya baba re so o yii. Sebi Yoruba bo, won ni: “bi ko ba ni idi, obinrin kii je Kumolu”. Ojo keta ti Ayoke ti i se iya re bi i ni o ki aye pe “O digba o se”.

Bi o tile je pe baba re Alabi se alaisi ninu ijanba oko nigba ti oyun re wa ni osu marun-un. Abeni to je iya baba Eniitan ti le ni aadorin odun ni akoko ti awon obi re fi jade laye sugbon O gbagbo wi pe oju Olorun lo n banii woo mo gege bi oruko ilu won.

Abeni sa gbogbo ipa re pelu iranlowo Olorun lati ri i pe Eniitan kawe lati alakoobere titi de Ifafiti. Ni ikeyin, Eniitan di Oloselu ati onisowo pataki ni iseju aye re.

IBEERE:

  1. Eniitan je omo ipinle —— A. Oyo B.Ogun C. Osun D.Kwara E. Ondo
  2. “O digba o se” ninu ayoka yii tumo si ki eniyan —– A. sun B.yari C. ku D. ja E.juwo
  3. Bba Eniitan ku ninu ijanba—— A.oko B.omi C. ina D.ile E. okada
  4. —— lo gba pe oju Olorun lo n bani wo mo. A. Abeni B. Ayoke C. Alabi D. Ajiun E. Alani
  5. Eniitan di —– ni isoju aye Abeni. A. Dokita B. Agbejoro C. Oluko D. Awako E.Oloselu

 

IGBELEWON

  1. Ki ni aroko?
  2. Ki ni aroko onioroyin?
  3. Ko aroko lori ijamba moto ti o se oju re.

 

AKORI ISE:   ASA IRANRA – ENI – LOWO.

Asa iranra – eni – lowo ni ona ti awon Yoruba maa n gba ran ara won lowo tabi ki a so pe asa iranra eni – lowo ni ona ti awon Yoruba maa n gba soore fun arawon. Orisiirisii ona ni awon Yoruba maa n gba ran ara won lowo. Die lara won ni: (i) Aaro (ii) Ebese (iii) Esusu abbbl  

Esusu:-Eleyii ni i se pelu owo. Won maa n da owo yii ni. Won maa n ni eni ti yoo maa gba owo yii laarin arawon. Eni ti o n gba owo yii maa gba owo naa kaakiri lodo awon eniyan (omo egbe). Bi won ba ti n da owo yii ni won maa ko si ara iganna/ogiri (wall) won o maa fa igi kookan si ara iganna, igi yii ni iye ti o duro fun.

Ajo:- Ajo naa dabi esusu ni, won maa n da owo fun olori alajo. O ni iye owo ti eniyan yoo maa da bi agbara eeyan ba se to. Iyato to wa laarin esusu ati ajo ni wi pe gbogbo iye ti eniyan ba da ni eeyan yoo ko nibi esusu sugbon nibi ajo eeyan yoo ko ida kan sile fun olori alajo.

Egbe alafowosowopo: egbe alafowosowopo naa ni won n pe ni egbe alajeseku. Egbe yii wopo wa laarin iyaloja,osise ijoba abbl. Won maa n ni oloye laarin won bi akowe, akapo, ayewe owo wo.ki a ranti wi pe awon egbe yii maa n ni eto ati ofin lati odo ijoba. Eyikeyi ninu omo egbe ni o ni anfaani lati ya owo nibe.

 

IGBELEWON

  1. Ko ona meta ti awon Yoruba maa n gba ran ara won lowo.
  2. iyato wo lo wa laarin esusu ati ajo?.

 

ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ

1 Oyebamji Mustapha (2009) Eko ede Yoruba titun iwe kin-in-ni (J S S2 ) oju iwe University Press Nig

2  Oyebamji Mustapha (2009) Eko ede Yoruba titun iwe kin-in-ni (J S S2 ) oju iwe 136-146 University Press Nig.

 

LITIRESO

 

Kika iwe apileko ti ijoba yan.

 

 

APAPO IGBELEWON

  1. Ki ni aroko?
  2. Ki ni aroko onioroyin?
  3. Ko aroko lori ijamba moto ti o se oju re.
  4. Ko ona meta ti awon Yoruba maa n gba ran ara won lowo.
  5. iyato wo lo wa laarin esusu ati ajo?.

 

ZT%NY@W) @K_

  1. ya ate faweli airanmupe.

     

ISE ASETILEWA

  1. Wiwa koto si eyin odi lati dena ogun jija ni …… A. lilo alami B. wiwa yara D. tituuba
  2. Ewo ni ki I se ona ti a n gba dena ogun A. wiwa yara B. tituuba D. idobale
  3. Alore ni …………. Ilu. A. ami B. oluso D. eso
  4. Ori oro wo lo je mo aroko asotan ju nihin-in? A. eto ikaniyan B. bi mo se lo isinmi ti o koja D. olowo lagba.
  5. …………. le je oro fun aroko asotan tabi oniroyin. A. omokunrin wulo ju omobinrin lo B. ile eko mi D. asiko ijoba iselu awarawa E. ojo ibi mi ti o koja

APA KEJI

  1. Ko apeere ori oro aroko oniroyin
  2. Ko ona ti a n gba ogun sile

 

OSE KEJO

AKAYE ONISOROGBESI Deeti………………..

( Olu ati Aina pade arawon ni ile itura piremia ni Ilu Ibadan. Won ti ri arawon tipe die. Bayi ni won bere oro won.)

Aina  Olu, iwo niyen, e ma ku ojo meta.

0lu  Emi niyen o, lowo oko aaro.

Aina  Se ko si nnkan Olu? O da bi igba wi pe ara re fa die.

Olu  Ara mi da ko si nnkan to n se omo olorun. Bi ode ti ri naa ku ni.

Aina  Iyen o maa to o ro. Arun gbogbo aye niyen ( Leyin igba ti won joko ).

Olu  Aina, Iyawo ati awon omo nko?

Aina  Gbogbo won wa daadaa. Igba ti mo tile n bo ni oko mi n mura lati mu awon omo jade

Olu  Abi ohun naa wa ninu awon igbimo idagbasoke?

Aina  O wa nibe, sugbon emi ko ri si idagbasoke ilu Ibadan.

Olu  Nnkan to da ni eto idagbasoke ilu. Looto wahala wa nibe sugbon ojuse gbogbo wa ni.

Aina  Bee ni o o paro.

 

IGBELEWON

  1. Awon wo ni won n soro ninu akaye yii?
  2. Ilu ibo ni won ti n soro?
  3. Ki ni koko oro won?

ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ

Oyebamiji Mustapha (2009) Eko ede Yoruba titun iwe keji (J.S.S.3) oju iwe 102- 225 231 university Press Plc.

 

IKINI (GREETINGS)

AKOKO IKINI IDAHUN

Aaro/owuro Ekaaro o o o, a dupe

E e jiire bi o

Osan E kaasan o o o.

Irole E kuurole o o o

Ale E kale o o o

BI A SE N KI IKINI IDAHUN

Aboyun Asokale anfaani o e se o

Nibi isomoloruko E ku ijade oni adun a kari o

Nibi oku E ku aseyinde o eyin naa a gbeyin arugbo yin o

Onidiri Eku ewa/oju gbooro o o

Agbe Aroko bodun de o ase o

Osise ijoba oko oba o ni sayin lese o ami o

Ijoye kara o le wa a gbo.

Oba Kabiyesi o oba n ki o

Eni to n jeun lowo E bamiire o omo rere a ba o je

Nibi oku agba E ku aseyinde o e se o, eyin naa a gbeyin arugbo yin o

 

ÌGBÉLÉWÒN

1 Bawo ni won se n ki awon wonyi?

  • Onidiri
  • Agbe
  • Nibi oku agba
  1. Bawo ni won se n ki eniyan ni
  • Aaro
  • Osan

 

 

LITIRESO

Kikai we apileko ti ijoba yan.

IGBELEWON

  1. Awon wo ni won n soro ninu akaye yii?
  2. Ilu ibo ni won ti n soro?
  3. Ki ni koko oro won?
  4. Bawo ni won se n ki awon wonyi?
  • Onidiri
  • Agbe
  • Nibi oku agba
  1. Bawo ni won se n ki eniyan ni
  • Aaro
  • Osan

 

ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ

S Y Adewoyin (2003) New simplified Yoruba L1 iwe kin-in-ni [J s s1] oju we 5-7.

 

 

ISE ASETILEWA

1.  Aroko ti o maa ni asogba ni aroko …. A. asotan B. oniroyin D. onisorogbesi.

2.  Aroko onisorogbesi maa n ni eniyan … A. meji si meta B. eni kan soso D.

3  asa iranra-eni-lowo ti o dabi adiye irana ni A. aaro B. ebese D. ajo.

4   … won maa n da owo ninu re sugbon iye ti o ba wu eni kookan ni won maa n da. A. esusu B. ebese D. ajo.

5  Aroko wa gbodo …… A. pani lerin B. kun eeyan loorun D. ba ori oro mu.

 

APA KEJI

  1. Bawo ni won se n ki n ni: aaro, osan, ale, igba otutu?
  2. Salaye: ikini.
  3. Salaye eda itan merin ninu iwe apileko ti o ka.

 

OSE KESAN-AN.

 

 

IWA OMOLUWABI Deeti………………..

Iwa omoluabi ni iwa ti o to ti o si ye ki eniyan ma hu. Iwa rere ti o ye ti o si to ki eniyan maa hu ninu ile, ninu ijo, ninu egbe ati laarin ilu ni a pe ni iwa omoluabi. Iru iwa bayi maa wopo laarin awon omo ile iwe. Ibowofagba, iwa iteriba, ikini, otito siso. Iranra eni lowo. Iru iwa bayi maa n mu ibasepo wa laarin ebi ara ore ni. Nitori naa iwa omoluabi ni iwa ti o to ti o si ye ki eniyan ma hu. Apeere iwa omoluabi ni awujo ni:

  • Ikini
  • Otito siso
  • Iteriba
  • Igboran
  • Iwa iforiti
  • Asa iranra eni lowo
  • Iwa pele
  • Ibowo fagba
  • Ise sise.

IGBELEWON

  1. Ki ni iwa omoluabi
  2. Ko iwa omoluabi merin sile
  3.  

 

ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ

1  Eko ede Yoruba titun iwe keta ( S S S ) Oju iwe 105- 118 lati owo Oyebamji Mustaph

2  Oyebamji Mustaph (2002) Eko ede Yoruba titun iwe keji ( JS S ) Oju iwe 164-173/1-15 university Press Plc.

 

LITIRESO

Kika iwe apileko ti ijoba yan.

 

APAPO IGBELEWON

  1. Ki ni iwa omoluabi
  2. Ko iwa omoluabi merin sile

 

ZT%NY@W) @K_

  1. Ki ni ami ohun?
  2. Se alaye lekun-un rere lori orisii ami ohun.

     

ISE ASETILEWA

  1. Eni ti o ni iwa gidi ni a mo si …….. A. oni ipata B. onijagidijagan D. omoluabi
  2. Ohun akoko ti a gbodo se ti a ba ji laaro ni ……. A. ki a rin erin B. ki a jeun D. ki a ki awon obi wa.
  3. Aroko wa gbodo …….. A. pani lerin B. mu ki eniyan sun D. koni logbon
  4. Orisii aroko to tun wa ni …… A. aroso B. agbaso D. alalaye
  5. Ti a ba fe ko aroko, a gbodo yan …..A. ikadi B. ifaara D. ori oro

APA KEJI

  1. ko iwa omoluabi mewaa sile

 

OSE KEWAA

GBOLOHUN EDE YORUBA

gbolohun ni ipede ti o kun pelu itumo kikun. Orisii eya gbolohun meji ni o wa. Awon eya naa ni: (i) gbolohun ni ilana ihun ati

  (ii) gbolohun ni ilana ise tabi ise ti o n je.

  1. Gbolohun ni Ilana Ihun ni: gbolohun eleyo oro ise (abode), olopo oro ise (onibo) ati alakanpo.
  • Gbolohun eleyo oro ise o maa n ni eyo oro ise kan. Apeere: ade pa eku.
  • Gbolohun olopo oro ise: o maa n ni ju eyo oro ise kan lo. Apeere: Kunle sare tete lo pon omi
  • Gbolohun alakanpo: o maa n gbolohun meji ninu. O si maa ni oro asopo ninu pelu. Apeere: Apeere: Olu je buredi ati eyin.

     

  1. Gbolohun ni Ilana Ise/ise ti o n je: apeere gbolohun alalaye, ase, ibeere, kani, ayisodi,
  • Gbolohun Alalaye: a maa n fi se alaye. Apeere: ojo ro ni ana.
  • Gbolohun Ase: a maa n fi ase. Apeere: jokoo si ibe yen, pa enu re de.
  • Gbolohun Ibeere: a maa n fi se iwadii a si maa n lo wuren/atoka ibeere awon bi: nko, nda, se, tani, ki ni, bawo, nibo. Apeere: Se o ti jeun?
  • Gbolohun Kani/Iba: Apeere: n ba wa kani mo gbo.
  • Gbolohun Ayisodi: a maa n se amulo ko, o, ki i, i. Apeere: Gbade ko ka iwe.

     

 

IGBELEWON

  1. Ko apeere marun-un marun-un fun awon gbolohun yii:

    Gbolohun ase, olopo oro ise, abode, alakanpo, ibeere, ayisodi,alalaye.

 

IWE AKATILEWA:

  1. Oyebamji Mustapha (2009) Eko Ede Yoruba titun iwe kin-in-ni (J S S1 ) University Press oju iwe 219-222 & 227-230

 

IWA OMOLUWABI

 

Awon Yoruba bo won ni iwa rere ni eso eniyan bee si ni oruko rere san ju wura ohun fadaka lo. Gege bi omoluabi, orisiirisii ojuse ati eto ni o se pataki ti a gbodo mojuto tabi fi si okan ni eyi yoo mu ki awon eniyan maa wo eniyan bi omo ti o ni eko. lara awon ojuse naa ni wony:

Ojuse si Obi: Gege bi omoluabi ti a ko ti o si gba eko, o ni awon ojuse ti a gbodo maa se fun awon obi wa tori Yoruba bo won ni ile lati ko eso rode. Omoluwabi gbodo:

Gboran si obi lenu

gboro si obi re lenu.

Jise fun awon obi

Bowo fun awon obi re

Tun oruko obi re se.

Je asoju rere fun obi re nibi gbogbo.

Se ise ile fun obi re

 

Ijoba: omoluwabi gbodo:

San owo ori

Bowo fun ofin ilu

Da si ise idagbasoke ilu

Je asoju rere fun orile-ede re.

Gbodo kopa ninu idagbasoke oro aje ilu re.

Maa bowo fun Asia orile-ede re.

 

LITIRESO

Kika iwe apileko ti ijoba yan.

 

ISE AMURELE

1.  “Nje” je atona/wuren gbolohun ____ A. Ibeere B. alalaye D. Ase.

2.  “E dake” je apeere gbolohun ______ A. Alaye B. Ase D. Ibeere E. Alakanpo

3.  ______ ni gbolohun ti a ti maa se amulo oro asopo A. Eleyo oro ise B. Olopo oro ise D. Alakanpo

4.  Ewo ni ki i se wunren gbolohun ibeere ninu awon wonyi A. awaB. Meloo D. Bawo.

5  Eni ti o ni iwa gidi ni a mo si …….. A. oni ipata B. onijagidijagan D. omoluabi

APA KEJI

  1. salaye awon gbolohun won yii gbolohun olopo oro ise,gbolohun eleyo oro ise ati gbolohunibeere
  2. ko iwa omoluabi sile


     




Share this:


subscriber

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Accept Our Privacy Terms.*